Kí ló fa wàhálà láàrín àwọn olùgbé agbègbè Bodija àtàwọn onílé ijó ‘Night club’ nílùú Ibadan?

Aworan ilu Ibadan ni alẹ

Oríṣun àwòrán, other

Nnkan ko dan mọran laarin awọn olugbe agbegbe Bodija nilu Ibadan tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ọyọ atawọn onile ijo ati ile igbafẹ alẹ lagbegbe naa.

Gẹgẹbi iroyin ti o tẹ wa lọwọ ṣe sọ, ariwo to n jade latawọn ile ijo yii kii jẹ ki awọn eeyan to n gbe agbegbe naa o ni isinmi ni wakati tabi asiko yoowu yika ojumọ.

Bakan naa lawọn ara adugbo naa tun sọ wi pe awọn ile ijo ati igbafẹ alẹ wọnyi ti n di ibuba fun awọn oniṣẹ ibi eyi to n mu ki iṣẹlẹ ibi o di eyi to wọpọ nibẹ bayii.

Ki lawọn iṣẹlẹ laabi to n waye lagbegbe naa?

Yatọ si ariwo ti ko jẹ ki awọn eeyan agbegbe naa ri imu mi, lara ẹsun ti wọn tun fi kan awọn onile ijo naa ni bi awọn onibara wọn ṣe n fi ọkọ di oju ọna, bi wọn ṣe n fa awọn to n lo ogun oloro wa si agbegbe naa ati bi wọn ṣe n fi aye gba awọn iwa ọdaran mii.

Laipẹ yii naa si tun ni iroyin jade pe ọdọbinrin kan to ṣẹṣẹ kẹkọgboye imọ ijinlẹ nọọsi, Boluwatifẹ Ọmọniyi di ologbe lẹyin to tẹlẹ ọrẹkunrin rẹ lọ si ile ijo kan lagbegbe Bodija yii kan naaa.

Oniruru iwa idigunjale lo ti n waye lagbegbe paapaajulọ eyi ti awọn eeyan agbegbe naa si ti n pariwo le lori pe o n mu igbe aye le koko fun awọn lagbegbe Bodija.

Ki ni igbesẹ ti awọn eeyan agbegbe naa gbe bayii?

Nigba ti ọrọ naa ṣe bi eyi to de gongo ẹmi awọn olugbe agbegbe Bodija, paapaa awọn onile lagbegbe naa ni wọn fi eni ko eji ti wọn gba ọdọ gomina ipinlẹ naa lọ ni sẹkitariati ijọba to wa nilu Ibadan.

Wọn ni ki ijọba o gba awọn lọwọ gbọnmọgbọnmọ awọn onile ijo naa.

Igba akọkọ kọ niyi ti awọn eeyan agbegbe Bodija yoo ke gbajare tọ ijọba lọ lori ọrọ yii.

Loṣu kejila Ọdun 2021, awọn olugbe agbegbe yii gbe igbesẹ kan naa ṣugbọn ti ọrọ naa ko yi pada rara.

Ki ni ijọba ipinlẹ Ọyọ n sọ bayi lori ọrọ yii?

Awọn olugbe agbegbe naa lẹyin ipade ọhun

Oríṣun àwòrán, other

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti pinnu lati fi iya ti o tọ jẹ awọn oludasilẹ ile ijo to n fi ariwo faaji alẹ ṣe idiwọ fun awọn olugbe agbegbe Bodija nilu Ibadan.

Ninu ọrọ ti o sọ nibi ipade naa, igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ, Amofin Adebayo Lawal ṣe alaye wi pe ohun ti awọn onile ijo n ṣe ni agbegbe naa ko jẹ itẹwọgba si ijọba ipinlẹ Ọyọ, nitori naa si ni o fi pe fun igbesẹ lori awọn ofin ati ilana antẹle ti ẹka ileeṣẹ ijọba to n mojuto ileigbe gbe kalẹ.

Lawal gboriyin fun awọn olugbe agbegbe naa fun suuru wọn titi di asiko yii koro oju si aitẹle ofin ati ilana ileigbe lati ọwọ awọn onile ijo naa.

Igbakeji Gomina ṣe alaye wi pe saaju asiko yii ni awon onile ijo naa ti tọwọ bọ iwe adehun lati mu adinku ba ariwo ti wọn n pa ati awọn idiwọ mii ti wọn n ṣe ni agbegbe naa, ṣugbọn wọn kọ eti ọgbọin si adehun naa. O ni ijọba ko ni fi aye gba aigbọran wọn mọ lati asiko yii lọ.

O fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ko ni yi ipinnu rẹ pada lori ọrọ naa bikoṣe ki wọn fi iya jẹ ile ijo ti o ba tapa si ofin ileigbe ti ijọba la kalẹ.