Wo ohun márùn-ún tó ń fa kí nǹkan ọkùnrin má le

  • Adline Okere
  • Editor, BBC Igbo

Ọkunrin to n tu sokoto

Ọpọ ọkunrin lo saaba maa n dakẹ ti nnkan ọmọkunrin wọn ba ti dẹnukọlẹ, ti ko si gberi mọ.

Wọn yoo wa fi ọrọ naa se iso inu ẹku, arunmọra, mọ sinu, awo mọ sikun.

Iwadii si ti fihan pe awọn ọkunrin ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejidinlogun si marundinlogoji lo ko ida mẹẹdogun ninu ida ọgọrun awọn eeyan ti nnkan ọkunrin wọn ko le daadaa.

Bẹẹ ni awọn ọkunrin ti ọjọ ori wọn ti le ni ogoji ọdun ko ida ogoji ninu ọgọrun awọn ọkunrin ti nnkan ọkunrin wọn ko sisẹ, ti oloyinbo n pe ni Erectile dysfunction (ED).

Eyi ko si sẹyin ẹlẹya to seese ki wọn fi se ni awujọ tabi asa idẹyẹsi to maa n saba wọpọ si iru ẹni bẹẹ.

Bakan naa ni wọn tun le maa yaju si iru ọkunrin bẹẹ, tabi ki iyawo rẹ maa ri fin, ti wọn ba fi tu asiri yii sita ninu ile tabi pẹlu ẹnikẹni

Nitori idi eyi, awọn ọkunrin ti nnkan wọn ko sisẹ mọ maa n da gbe agbelebu wọn lori ọrọ yii ni to si le fa ironu ati irẹwẹsi ọkan si wọn lara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bi eyi ba si waye, ọpọ aisan miran tun le gba ibẹ wọle si wọn lara, ti wọn si maa n bẹru lati sun mọ aya wọn ninu ile.

Bi ọkunrin ko si le se ojuse rẹ si iyawo rẹ bo se yẹ ninu ile, o maa n mu ki opo to gbe ile naa ro maa yẹ diẹdiẹ, ti ija yoo si maa waye lemọlemọ laisi idi kan pato.

Dokita Rasheed Adedapo Abassi, jẹ akẹkọjade nibudo ẹkọsẹ isegun fasiti Yale nilẹ Amẹrika, to si ni iriri ọdun mọkandinlogun lẹnu isẹ nipa ilera awọn ọkunrin.

O wa salaye nipa ohun to n sokunfa ki nnkan ọkunrin ma sisẹ mọ, iwosan rẹ ati awọn ọna ta fi le dena isẹlẹ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki ni itumọ ki nnkan ọkunrin ma sisẹ?

Erectile dysfunction (ED) eyiun ti nnkan ọkunrin ko ba sisẹ mọ ni asiko ti oko rẹ ko ba le fun odidi isẹju mẹẹdogun gbako.

Iwadii ti fihan pe ọkunrin to ba dape lara, ni nnkan ọkunrin rẹ gbọdọ le gbanko ni owurọ to ba ji.

Amọ dokita Abass ni to ba jẹ pe fun akoko ranpẹ ni oko ọkunrin kan fi n le, tabi ko le gbe nnkan ọkunrin to le naa wọ inu oju ara obinrin ti yoo fi rọ pẹsẹ, a jẹ pe onitọun ti ni aisan ti wọn n pe ni Erectile dysfunction (ED) ni.

Ọpọlọpọ nnkan lo n faa ti iru isẹlẹ yii fi maa n waye amọ marun pere ninu awọn ohun to n sokunfa ki nnkan ọkunrin ma sisẹ mọ ree:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Aidape eroja òmóònù (Hormone) kan lara ọkunrin ti wọn n pe ni testosterone:

Eroja òmóòònù Testosterone yii lo maa n mu ki ọkunrin dape lara nigba ti eroja omoonu ti wọn n pe ni Estrogene to wa lara obinrin lo maa n mu ki obinrin le loyun lati bimọ.

Yatọ si bo se n waye lara awọn ọkunrin, eroja omoonu Estrogene to n da loju ara obinrin lo maa n dinku ti obinrin ba ti pe ẹni aadọta ọdun.

Amọ ni ti awọn ọkunrin, eroja omoonu Testosterone ko le dinku laelae amọ awọn ipenija kan maa n ba finra.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Irẹwẹsi ọkan tabi ironu (Stress):

Irẹwẹsi ọkan jẹ ohun kan gboogi to maa n se okunfa ki nnkan ọkunrin ma le bo se yẹ. Irẹwẹsi ọkan le waye ti isẹ ba bọ lọwọ ọkunrin, ti owo ba safẹrẹ lọwọ rẹ tabi ti ipenija ba wa ninu igbeyawo rẹ tabi lati ibikibi.

Awọn ohun to n mu irẹwẹsi ọkan wa yii yatọ si eyi ti sise ere idaraya n mu wa nitori ere idaraya maa n mu ki ọkan pọn ẹjẹ lọ si awọn isan to yẹ ni.

Amọ irẹwẹsi ọkan maa n pọn ẹjẹ yika gbogbo ara ni laibikita.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Aimaa se ere idaraya deedee (Ibalopọ):

O yẹ ka maa tẹnu mọ eleyi daadaa lati dena ki nnkan ọkunrin ma gberi. Ọkunrin gbọdọ kọ asa sise ere idaraya fun ọgbọ isẹju lojoojumọ.

“N jẹ o mọ ere idaraya ti mo maa n daba rẹ fun awọn alaisan ti mo n tọju? Ibalopọ oorekoore ni.

Mo si ni awọn abọ iwadii kan to fidi eyi mulẹ, ti mo le tọka si bii ẹri to daju.” Dokita Abass lo sọ bẹẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ibalopọ oore koore:

Dokita Abass wa daba fun awọn ọkunrin pe ki wọn maa da oje ara wọn ta n ms si Sperm ni igba mọkanlelogun losoosu.

O ni ibalopọ gbogbo igba maa n se iranwọ lati mu dena arun jẹjẹrẹ ile itọ ọkunrin, eyi to le se akoba lọjọ iwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Aisi omi to mọ fun mimu fawọn araalu:

Eleyi le jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan amọ gẹgẹ bi Dokita Abass se wi, ni ọdun diẹ sẹyin ka to wọnu ọdun 2000, ọpọ eeyan lo ni anfaani si omi ẹrọ to mọ, eyi ti wọn ti fi oogun apakokoro si.

Amọ o salaye pe aisi omi ẹrọ to mọ fun araalu lati mu, eyi to ni eroja asaloore ke ke ke ti wsn n pe ni macronutrients, n mu ki ọpọ nnkan ọkunrin ma gberi mọ.

O wa sisọ loju rẹ pe, wọn ti pọn ni dandan fun ijọba lati setọju omi ẹrọ to n pese fawọn araalu lati pọn mu pẹlu awọn eroja to n pa kokoro bii fluoride, calcium, selenite.

O ni gbogbo awọn eroja inu omi yii lo ni ojuse tiwọn lati se, ki awọn ọkunrin le ni oje to dara lara.