Ìjì ńlá sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di aláìnílélórí ní Kwara

Aworan

O to bii Ile igbe marundilogoji ti ojo nla kan to rọ ni, ọjọ kọkanla osu kẹrin ọdun 2024 bajẹ ni iluu Igbonna, ni ijọba ibilẹ Oyun, nipinlẹ Kwara.

Awọn olugbe ilu naa ni wọn ti wa ni inu ifoya bayii latari bi ojo alagbara naa to mu atẹgun nla dani se sọsẹ ni ilu ọhun, eyi to ba dukia ẹgbẹlẹgbẹ milionu jẹ.

Ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn ti di alainile lori latari iji nla naa.

Awọn ile, ṣọọbu, to wa ni ilu ọhun ni wọn fara gba ninu iṣẹlẹ naa. Ṣe lo ka awọn orule ile atawọn ṣọọbu kan lọ patapata, nigba to fi awọn mi-in silẹ laabọ.

Yatọ si ilu Igbonna, ilu kan ti wọn n pe ni Ẹlẹẹku, ti ohun naa wa ni agbegbe Igbonna naa fara kaasa ninu iṣẹlẹ laabi naa.

Ọpọlọpọ opo ina to wa lawọn agbegbe wọnyi lo wo lulẹ, ti awọn waya ori wọn si fọn kaakiri oju ọna.

Aarẹ ẹgbẹ ọmọ bibi idagbasoke Igbonna, Igbonna Descendants Development Union, (IDPU), Lọya AS Salami, to ba awọn oniroyin sọrọ ni ni nnkan bii aago meje alẹ ana lojo ọhun bẹrẹ.

Ọgbẹni Salami salaye pe bi ojo naa ṣe n rọ ni iji nla n fẹ.

Aarẹ ọhun ni iji jija lo ṣaaju, ki ojo too bẹrẹ si i rọ. O ni gbogbo ile to wa ni ilu Igbonna, ni iji naa fẹ fọwọ ba tan, to si gbe odidi ile, tabi ko ba a jẹ.

Salami, ni iji nla naa ti mu adanu nla ba ọpọ araalu to ṣoro fun wọn lati ribi sun si bayii.

O ni lọwọ lọwọ bayi, ọrọ aje ati igbaye gbadun ilu naa lo ti fori san pan, ti awọn tọrọkan o si mọ ibi ti wọn yoo fori ka si.

O bẹ ijọba atawọn tori ṣẹgi ọla fun lati dide iranlọwọ fawọn to fara kaasa, nitori ọpọ dukia olowo iyebiye lo ṣegbe latari ojo nla to rọ lẹyin iji naa, ti ọpọ si ti di alainilelori lasiko ti gbogbo nnkan di ọwọngogo yii.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ajọ panapana ni Kwara, Hakeem Hassan Adekunle, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ loni lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin yii.

O ni iṣẹlẹ naa ba ni lọkan jẹ pupọ, ati pe awọn to fara kaasa ti n beere fun iranlọwọ ijọba.

Alukoro naa ni ko din ni aarundinlogoji ile igbe ti iṣẹlẹ naa fọwọ ba.