Wo ìyá Ọgọ́rin ọdún tó ń ṣe ìdánwò kíláàsì Kejìlá

Arabirin Ratna Kumari Sunuwar, ẹni ọgọrin ọdun ni o ya ọpọlọpọ lẹnu bi o ṣe kundun lati maa ka iwe pẹlu bi o se dagba to lọjọ ori.

Ratna, ẹni ti wọn bi ni Ramechhap niluu Kathmandu lorilẹede Napel ṣalaye pe oun ko ni anafani lati lọ si ile ẹkọ nigba to wa ni ọmọde

O ni isẹ oko ati isẹ alabaru ni oun n ṣe lati ri ọwọ mu lọ sẹnu sṣugbọn nnkan yii pada nigba ti awọn mọlẹbi rẹ ra ile, ti wọn si ko lọ si Kathmandu.

“Bi a se ko lọ ni mi ko ba ni nnkan kan lati sẹ mọ, irẹwẹsi ọkan ba mi pe nise ni mo n fi asiko mi ṣofo.

“Bi mo ṣe ni kilode ti mi o bẹrẹ lati maa lọ si ile ẹkọ niyẹn. ti mo si darapọ mọ kilaasi awọn agbalagba .”

Aworan

“Mo gbagbọ pe ọjọ ori ko kọ iwe kika”

Ratna ni lasiko ti aarun korona n ba agbaye finra ni oun ṣe idanwo ipele kẹwa ati ikọkanla, ti oun si ti mura fun idanwo ipele kejila bayii.

“Mo gbagbọ pe ọjọ ori ko kọ iwe kika rara.

“Nigba ti mo bẹrẹ, awọn eeyan kan ko fẹran nnkan ti mo ṣe, wọn ni kilode ti mo fi lọ si ile ẹkọ.

“Kilode ti n ko duro nile, ki n ma gbadun oorun. Iwe kika jẹ ki mọ iyatọ ninu ọtun ati osi, nnkan to da ati eyi to ku diẹ kato.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí