Trinity Guy yóò fojú ba ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ Ajé – Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Agbẹnusọ Ileesẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Olumuyiwa Adejobi ti ni adẹrinposonu, Abdullahi Adisa, ti ọpọ mọ si Trinity Guy, yoo foju ba ileẹjọ lọjọ Aje lori fọnran kan to fi sori ayelujara ninu eyi to ti n ni ki ọmọdebinrin kan maa ṣe apejuwe nnkan ọmọkunrin rẹ to ni o ri.

Adejobi, ninu ọrọ to fi fesi si ọrọ kan lori ayelujara to ni ki ileẹsẹ ọlọpaa rii pe wọn fi isẹlẹ yii fa Trinity Guy leti, ki wọn si tu silẹ.

O tẹsiwaju pe: “Daju daju yoo foju ba ile ẹjọ lọjọ Aje. Ọpọ igba ni awọn eeyan ti wa fi ẹjọ Trinity Guy sun, ti ọpọlọpọ awọn ajafẹtọ ọmọniyan si ti da si ọrọ naa sugbọn ki awọn yooku fi ti Trinity Guy se arikọgbọn”.

“Yoo foju ba ileẹjọ lọjọ Aje. A ti gba ipe lọwọ ọpọlọpọ eeyan lori rẹ, ti awọn ileesẹ NGO si nifẹ si ọrọ to wa nilẹ yii.

“Ko si mọdaru ninu ofin gẹgẹ bi mo ṣe ma n sọ. Ki awọn yooku fi eyi k’ọgbọn.”

Ṣaaju eyi gan ni alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti kọkọ ke si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ pe ki wọn ti ọwọ Trinity guy bọ’ṣọ pẹlu ọkan o jọkan fidio alawada, skit to n ṣe nipa ko maa tan awọn eeyan jẹ (pranks) eyi to sọ pe o lodi si ẹtọ ọmọniyan ati alafia ilu.

Nítorí ìjíròrò wa pẹ̀lú Trinity Guy, àwọn òbí ọmọ tó fi ṣe skit ti wà lọ́dọ̀ wa – Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo

Aworan Trinity guy

Oríṣun àwòrán, nigeria police/ trinity guy

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe gbajumọ alawada ori ayelujara, Abdullahi Maruf Adisa ti ọpọ mọ si ‘Trinity guy’ ti farahanwa lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ pẹlu agbẹjọro rẹ lati dahun ipe ti wọn pe e lọjọbọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ranṣẹ pe Trinity guy ko wa wi tẹnu rẹ lori fọnran kan to fi sori ayelujara ninu eyi to ti n ni ki ọmọdebinrin kan maa ṣe apejuwe nnkan ọmọkunrin rẹ to ni o ri.

Ṣaaju eyi gan ni alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, ọga ọlọpaa Olumuyiwa Adejọbi ti kọkọ ke si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ pe ki wọn ti ọwọ Trinity guy bọṣọ pẹlu ọkan o jọkan fidio alawada, skit to n ṣe eyi to sọ pe o lodi si ẹtọ ọmọniyan ati alafia ilu.

Trinity guy sọ fun ọlọpaa pe awọn obi ọmọ naa mọ si bi oun ṣe fi ọmọdebinrin naa ṣe fidio naa

Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Oṣifẹsọ ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti pe lẹyin ijiroro ọlọpaa ati Trinity guy, awọn ti lọ fi ṣinkun ofin mu baba ati iya ọmọ naa, Isiaka Ahmed ati aya rẹ Rofiat.

Gẹgẹbi o ṣe sọ, trinity guy ṣalaye fun awọn ọlọpaa to fi ọrọ waa lẹnu wo pe, oun gba aṣẹ lọwọ awọn obi ọmọdebinrin naa ki oun to lo o fun fidio naa, ati ki oun to gbe e si ori ayelujara.

Trinity guy ninu fidio rẹ kan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ ni idi niyi ti awọn ọlọpaa ẹka to n gbogun ti awọn iwa ọdaran to niiṣe pẹlu awọn majesin Gender/Juvenile related offences desk ṣe pe awọn obi ọmọ naa lati wa wi tẹnu wọn.

‘Ọdun 2022 ni fidio Skit naa jade, kii ṣe aṣẹṣẹ ṣe’

Ninu ifọrọwerọ to wa ṣe pẹlu BBC News Yoruba, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ naa sọ pe gbajumọ alawada oriayelujara naa, sọ pe oṣu kọkanla ọdun 2022 ni oun fi fido naa sita.

O ni ko pẹ pupọ ti oun gbe fidio naa sita ti oun tun yọọ kuro nigba ti ariwo dide tako o paapaa lori aitọ rẹ pẹlu ọrọ ọmọde.

O fi kun un pe bi o tilẹ jẹ wi pe trinity funra rẹ ti gbe e kuro lori ayelujara, ṣugbọn awọn kan ti ka a silẹ lati ori ayelujara.

SP Oṣifẹsọ ni ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa n ja a fun bayii ni ọtọ ọmọdebinrin yii.