Tinubu polongo Nàìjíríà fáwọn olùdókoòwò àgbáyé ní Paris, ọ̀rọ̀ tó sọ rèé

Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/Facebook

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti fi ogun orilẹede Naijira gbari ni Paris, orilẹede France to lọ fun ipade pataki pẹlu awọn oludokoowo lagbaye ti wọn jọ pe nibẹ.

Bola Tinubu rọ awọn oludokoowo ti wọn jọ wa nibi ipade naa wipe orilẹede Naijiria ti ṣetan lati ba wọn da owo pọ.

O jẹ ko di mimọ fun wọn pe yiyọ ti wọn yọ owo iranwọ epo kuro ni Naijiria ati apapọ iye owo ṣiṣe pasiparọ owo ilẹ okere.

Aarẹ Tinubu ni France

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/Facebook

“A ti ṣetan fun ṣiṣe owo, a ti gbaradi lati ki awọn oludokoowo ku abọ,” o sọ eyi nigba to n gbalejo Aarẹ ati alaga igbimọ awọn adari Banki Afrexim, Ọjọgbọn Benedict Oramah; ati Aarẹ Banki fun idagbasoke ilẹ Yuroopu naaOdile Renaud-Basso.

Ninu ọrọ kan ti olugbaninimọran pataki fun aarẹ Tinubu lori ibaraẹnisọrọ ati akanṣe iṣẹ iyẹn Dele Alake fi sita, tinubu fi da awọn oludokoowo naa loju wipe ijọba apapọ yoo tẹsiwaju lati mu igbelarugẹ ba ọrọ aje plu awọn aato ti yoo ti idokoowo lẹyin lawọn apaa ibi ti Naijiria ti lee figagbagba to si ni anfani ju awọn to ku lọ paapaa julọ lẹka eto ọgbin.

Aarẹ Tinubu ni France

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/Facebook

“A nilo atunto fun ilọsiwaju orilẹede,” tinubu tun fi kun un wipe yoo gba igboya ati mimu ọkan le lati ṣe atunto eto ọrọ aje, o si n pe fun ajọṣepọ lọpọ yanturu lati fi ẹsẹ eto ọrọ aje rinlẹ daadaa.

Aarẹ ni atunto to n lọ lọwọ ni orilẹede Naijiria yoo di eyi ti yoo lalopẹ nitori ifigagbaga eto ọrọ aje ti yoo fa oju awọn oludokoowo ilẹ okere mọra.

Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/Facebook