Àwọn orílẹ̀èdè Áfíríkà bẹ̀rẹ̀ ìpàdé àpérò láti ṣẹ́ eegun ẹ̀yìn àwọn agbésùnmọ̀mí

Aworan awọn olori orilẹede Africa

Ipade ọlọjọ meji kan ti n waye lọwọ nilu Abuja eyi ti aarẹ Bola Ahmed Tinubu ba wọn si.

Ipada naa lo wa lati gbogun ti iwa igbesunmọmi ati ikunkookomọni lawọn orilẹede to wa nilẹ Afirika.

Ọjọ Aje oni ati ọjọ isẹgun ọla ni ipade naa yoo fi waye eyi ti awọn olori orilẹede nilẹ adulawọ yoo peju si.

Akori ipade apero naa, ti aarẹ Bola Tinubu bawọn side rẹ ni “Riro okun ajọsepọ laarin awọn orilẹede lagbara si ati sise agbega awọn ileesẹ ti yoo tẹ ori iwa igbesunmọmi ba”.

Ọọfisi oludaninimọran fun aarẹ Naijiria lẹka eto aabo lo se agbekalẹ ipade apero naa.

Afojusun ipade apero naa si ni lati mu ki igbesẹ gbigbogun ti iwa igbesunmọmi le koko si laarin awọn orilẹede Afirika lati ipasẹ ajọsepọ ileesẹ ologun, ki wọn si dẹkun bi ohun ija oloro ati owo se n kọja lati orilẹede kan si omiran lati se atilẹyin fawọn ọdaran.

Ipade apero yii si lo n waye lasiko yii ti ọpọ orilẹede nilẹ Afirika n koju iwa idunkookomọni lẹka eto aabo lati ọwọ awọn ajijagbara ẹsin Islam ati agbebọn, paapaa lawọn agbegbe asalẹ Sahara.

Orilẹede Nigeria to n gbalejo ọọfisi ajọ isọkan agbaye to n gbogun ti iwa titako igbesunmọmi, lo n dari ipade naa.

Ileesẹ ologun Naijiria si lo ti leri leka lati gbẹsan bi wọn se sẹburu awọn ọmọogun rẹ mẹfa to n lọ pẹtu si aawọ nipinlẹ Niger, ti wọn si pa wọn ni ipakupa.

Aworan awọn olori orilẹede Africa
Aworan awọn olori orilẹede Africa

Ileesẹ ologun fikun pe awọn agbebọn lo lọwọ ninu ikọlu sawọn ologun naa lalẹ ọjọ Ẹti.

Lara awọn eeyan ti yoo sọrọ nibi ipade apero naa ni aarẹ ajọ isọkan ilẹ Adulawọ, t Moussa Faki Mahamat ati aarẹ ajọ ECOWAS, Omar Touray pẹlu aarẹ Bola Tinubu ti ijọba rẹ n koju isoro eto aabo to mẹhẹ.

Awọn asaaju lawọn orilẹede Ghana ati Togo naa yoo dara pọ akẹẹgbẹ wọn lati orilẹede Naijiria, Bola Tinubu lati peju sibi ipade apero naa.

Bakan ni awọn onimọ nipa eto aabo latinu ajọ isọkan orilẹede ilẹ Yuropu atawọn orilẹede miran nilẹ Afirika yoo peju sibi ipade naa.