Wo ìdí mẹ́ta tí Buhari fi ń rìnrìnàjò lónìí yàtọ́ sí pé ó ń lọ fún ìtọ́jú ara rẹ̀ ní London

Buhari

Oríṣun àwòrán, @Presidency

Aare Muhammadu Buhari to n tukọ́ Naijiria gbera irinajo lonii

Ero awon omo Naijiria sotooto bi Aare Buhari se tun kede irinajo lo sile okeere lasiko yii.

Gbogbo eto lo ti pari bayii, fun Aarẹ Muhammadu Buhari ti orileede Naijiria lati lọ ṣe ayẹwo, ko si gba itọju nile iwosan rẹ to wa ni London..

Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina to jẹ oludamọran pataki fun aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin ati ipolongo lo gbe iroyin naa sita fawọn akọroyin laaarọ oni, ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọjọ kin-in-ni, ọsu kẹta, ọdun 2022.

Idi meta wo lo n gbe Aare Buhari lo silẹ̀ okeere?

Femi Adesina jẹ ko di mimọ pe ọsẹ meji gbako ni Aarẹ yoo lo nibẹ, nitori pe ilera lọ̀rọ̀.

O ni o se pataki ki Aare Buhari gba itọ̀jú lasiko irinajo naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ati pe lẹyin ti Aarẹ Buhari ba gba itọju ọlọsẹ meji rẹ tan, ni yoo tun fi ẹsẹ kan ya nilu Nairobi, lorileede Kẹnya.

Ọgbẹni Adeṣina ṣe ṣalaye ninu atẹjade to gbe sita pe irinajo lo si Kenya yii yoo bi eso to dara fun orile-ede Naijiria.

Adẹsina fi kun ọrọ rẹ pe ibi ayẹyẹ aadọta ọdun ti ajọ ayika agbaye, iyẹn United Nations Environmental Programme (UNEP@50), ti yoo waye lọjọ kẹta si ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ọdun 2022 ti a wa yii ni Aarẹ Buhari a tun ti kopa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki tun ni Adesina so?

Bakan naa lo tun sọ pe Aare Buhari yoo lo latari iwe ipe ti akẹgbẹ rẹ, lati Kenya, Uhuru Kenyatta, fi ranṣẹ si i.

Bee, Onpeni nii sọla ni awọn agba n wi nilẹ̀ Oodua.

Ati pe Aare Buhari yoo ri aaye sinmi diẹ̀ sii laarin isẹ́ ilu wonyii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ero awon omo Naijiria sotooto lori irinajo Aare Buhari lasiko yii:

Buhari

Bi awon kan se n gboriyin fun un pe ara kii se okuta ati pe ara n fe isinmi naa ni awon mii n so pe kii se pelu ohun to n sele laarin Ukraine ati Russia yii lo ye ki aare tun maa rinrin ajo bẹ́ẹ̀.

Buhari
Buhari