Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà míì ti jáde láyé

Afolashade Oluweri

Oríṣun àwòrán, Queen Folashade Oluweri/Facebook

Igi nla tun ti wo, araba nla miran lagbo tiata tun ti dara ilẹ, ajanaku miran tun ti sun bi oke, ti opo ile miran si ti yẹ lagbo tiata.

Ọkan lara gbajumọ osere kan, to fi oke okun se ibujoko, Olori Afolasade ti jade laye.

Afolashade ti ọpọ mọ si Afolashde Oluweri nitori ere Oluweri Magbojo to gbe jade, ni awọn akẹẹgbẹ rẹ lagbo tiata ti n daro iku rẹ.

Gbajumọ osere tiata miran, Saidi Balogun, lo fi ikede iku obinrin naa sita ni aarọ ọjọ isẹgun loju opo Instagram rẹ.

Balogun ni owurọ ọjọ Aje ni agba ọjẹ osere tiata naa jade laye gẹgẹ bi Saidi Balogun ti kede rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa lo salaye pe Afolashade Oluweri ti ba oun kopa ri ninu gbajugbaja sinima kan ti oun gbe jade, eyi to pe ni Ọmọ Alhaja.

Nibayii na, wọn ko tii kede ẹkunrẹrẹ iroyin nipa isisnku oloogbe naa.

Bi o ba si se n jade, ni BBC Yoruba yoo maa mu wa si etigbọ yin.

Ikede iku Afolashde Oluweri ti Saidi Balogun se loju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, saidibalogun/Instagram