Wo bí gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun àti àwọn gomina míràn tó ṣèlérí láti tí banki tó bá kọ owó àtijọ́ ṣe fẹ́ ṣeé

Gomina Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, Dapo Abiodun/Twitter

Ijọba ipinlẹ Ogun ti kede pe banki to ba kọ owo naira atijọ lọwọ arailu yoo rugi oyin

Gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiodun lo kede bẹẹ loju opo ikansiraẹni Twitter rẹ

Eyi ko ṣẹyin bi iroyin ṣe gbode pe awọn banki kaakiri Naijiria ti n kọ owo naira atijọ naa, ti wọn ko si gba a lọwọ awọn araalu.

Dapo Abiodun lasiko to n ba awọn ara ọja sọrọ ni agbegbe ọja Itoku Kampala ni Abeokuta ni gomina naa sọ bẹẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina naa koju oro si awọn banki naa, to si kilọ fun wọn pe nitori ko si owo naira tuntun ni ilu ko yẹ ki wọn fi iya jẹ aẉọn ara ilu.

Gomina ipinlẹ Ogun naa wa kesi awọn araalu lati gba alaafia laaye, nitori awọn ṣetan lati fopin si inira to ba awọn araalu.

‘’Kọ owo atijo ni Kano , ki o rugi oyin’’ – Gomina Ganduje

Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ti kilọ fun awọn banki ati awọn ileeṣẹ nipinlẹ naa lati ṣọra ṣe lori ọrọ owo naira atijọ nibẹ.

Ganduje ni banki to ba dan wo lati kọ owo atijọ lọwọ awọn araalu yoo di titi pa, ti wọn ko si ni lee ṣiṣẹ nipinlẹ ọhun.

Bakan naa ni o ni awọn ileeṣẹ to ba kọ owo naira naa ni awọn yoo gba iwe aṣẹ ti wọn fi n ṣiṣẹ nibẹ, ti wọn yoo si ti ileeṣẹ naa pa.

‘’ O ti wa si akiyesi ijọba pe awọn ile itaja kan, banki, ile ounjẹ ati awọn ọlọja ni ọja, to fi mọ awọn ile epo ti bẹrẹ si ni kọ owo atijọ naa.’’

‘’Eleyii ti fa ifaṣẹyin ba ọrọ aje nipinlẹ naa, ti ọwọngogo si gbode kan nitori awọn eniyan ko ri owo tuntun na lasiko yii.’’

Gandujẹ ni aigba owo atijọ lọwọ awọn eniyan naa ti fa iya ati iṣẹ fun awọn araalu, ti ohun si ti lera fun awọn eniyan.

‘’Ẹ maa na owo atijọ yin lọ, ti Tinubu ba wọle yoo yi ofin ọhun pada’’- Gomina El-rufai

Saaju ni gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ti kede fun awọn araalu lati maa na owo naira wọn lọ ki wọn ma fi ti ijọba ṣe.

El-rufai sọ bẹẹ lasiko to n bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ ijọba lori owo naira tuntun ni Naijiria.

Gomina ipinlẹ Kaduna naa ni ki awọn araalu mu owo wọn pamọ , ati pe o da awọn loju pe oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oselu APC, Bola Tinubu yoo yi ofin naa pada ti o ba ti di aarẹ.

Bakan naa ni ipinlẹ Ondo, Zamfara darapọ mọ awọn ipinlẹ to ku lati pe ileeṣẹ banki apapọ Naijiria ni ẹjọ.

Ṣé lóòtọ́ làwọn bánkì ń kọ Náírà àtijọ́?

Owo Naira tuntun ati ti atijọ

Oríṣun àwòrán, CBN

Ọpọ awọn araalu ti mu igbe bọ ẹnu bayi lẹyin ti awọn banki, olokoowo kan ni awọn ipìnlẹ kan lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ si ni maa kọ owo beba N200, N500 ati N1000 silẹ lati gba a lọwọ awọn onibara wọn.

Eyi ko sẹyin ilana ati asẹ ti apapọ banki orilẹede Naijiria CBN pa, to ni ki awọn araalu da awọn owo atijọ pada, ki wọn si gba tuntun.

Ọjọ kẹwaa, oṣu keji ọdun 2023 ni gbedeke ti banki apapọ fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati da owo naa pada.

Sugbọn ọpọ eeyan ni asẹ naa nira fun lati tẹle nitori wọn ko ri owo tuntun gba jade.

Iwadii ileeṣẹ BBC fihan pe pupọ awọn banki ni agbegbe Abeokuta ati Eko ni wọn ti kọ jalẹ, ti wọn ko si gba Naira atijọ mọ lọwọ awọn onibara wọn.

“Banki kọ lati gba N200,000 Naira atijọ lọwọ mi”

Ọkan lara awọn onibara Ile ifowopamọ to ba wa sọrọ ni awọn osisẹ banki ni wọn ko gba owo to to ẹgbẹrun lọna igba naira lọwọ oun nitori pe o jẹ naira atijọ́.

Nibayi, ọpọ awọn eeyan lo ti n kan si awọn ontaja tabi olokoowo lati maṣe gba beba Naira atijọ lọwọ awọn onibara wọn.

Iwadii fihan pe pupọ awọn ọlọja ati araalu lo ṣi ni Naira atijọ lọwọ, ti wọn si ti rawọ ẹbẹ si banki apapọ lati fun wọn ni anfani lati paarọ owo naa.

Iléẹjọ́ tó ga jùlọ pàṣẹ pé kí CBN àti ìjọba àpapọ̀ wọgile gbedeke pipaarọ ati amulo Naira atijọ si tuntun.

saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa ti pasẹ fun ijọba apapọ lati wọgile gbedeke pipaarọ ati amulo Naira atijọ si tuntun

Bẹẹ ba gbagbe, awọn gomina mẹta to wa latinu ẹgbẹ oselu APC ti gomina Mallam El-Rufai ko sodi lo gbe ẹjọ naa lọ siwaju ile ẹjọ lọjọ kẹta osu keji ọdun yii.

Awọn gomina ọhun ni gomina ipinlẹ Kaduna, Kogi ati Zamfara, ti wọn si tọ ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa lọ pe ko pasẹ pe ki banki apapọ ilẹ CBN jawọ ninu atunse owo naira.

Igbimọ adajọ ẹlẹnimeje nile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa, eyi ti adajọ John Okoro ko sodi lo panupọ pasẹ bẹẹ.

Awọn adajọ naa lo si sọ fun ijọba apapọ ilẹ wa, CBN atawọn banki olookoowo lati wọgile gbedeke ọjọ kẹwa osu Keji ọdun yii ti wọn pasẹ pe owo Naira atijọ ko ni jẹ itẹwọgba mọ.

Ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa naa ni asẹ ọhun gbọdọ fidi mulẹ titi ti oun yoo fi pari igbẹjọ lori ẹjọ ti awọn gomina naa gbe wa siwaju rẹ.