“Ẹ̀ṣẹ̀ Lekan, awakọ̀ Fatinoye ju tí Judasi lọ, gbogbo ẹbí ló dá lóró”

awọn eeyan to n se isin imọyi fun ẹbi Fatinoye

Bi eeyan ba jẹ ori ahun, to ba wa nibi ti wọn ti ṣe isin alẹ abẹla ati ẹyẹ ikẹyin fun tọkọtaya Fatinoye ati ọmọ, onitọhun yoo bu sẹkun.

Awọn ẹbi Fatinoye yii lawọn afurasi agbebọn tọwọ ọlọpaa ti tẹ sun mọle wọn niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ aisun ọsun tuntun 2023.

Bakan naa, lawọn agbebọn yii tun ju ọmọ kan soso ti wọn bi sinu odo pẹlu ọmọ ti wọn gba tọ.

Lọjọ Isẹgun ni awọn ololufẹ ẹbi Fatinoye ṣeto eto isin ẹyẹ ikẹyin f’awọn oloogbe naa, nibi ti wọn ti sọ oriṣiriṣi ọrọ iwuri nipa wọn.

Iwaju ita ile awọn oloogbe naa to wa ni adugbo Ọba Karunwi, Ibara GRA niluu Abẹokuta ni eto ọhun si ti waye.

Lara awọn eekanlu to peju sibi eto naa ni Ọmọwe Ambrose Olutayọ Ṣomide to jẹ ẹgbọn oloogbe ati Olu-ọmọ fun Ẹgba Oke-Ona, Oloye Akinkunmi Jiboku, to fi mọ gbogbo awọn mọlẹbi, ọrẹ ati alabaṣiṣẹ pọ wọn.

Ọpọ akẹ́kọ̀ọ́ lawọn Fatinoye n ran lọ sile ẹkọ, wọn jẹ alatilẹyin fun ọpọ eeyan – Ọrẹ Fatinoye

Nigba to n sọrọ, Oloye Jiboku to ṣagbatẹru eto naa sọ pe ẹdun ọkan ni iku awọn idile naa jẹ fun oun nitori kekere lawọn ti bẹrẹ ajọṣepọ.

“Ọrẹ pataki ni mo jẹ si Oloogbe Kẹhinde ati iyawo rẹ, Olubọla Fatinoye, ti a si wọnu ara wa gidi.

Tọkọtaya naa jẹ ẹni ta le fi yangan, lai sọ asọdun. Wọn jẹ atilẹyin fun ọpọ eeyan.

Mo ṣi le sọ diẹ lara awọn akẹkọọ ti wọn n ran lọ sileewe. Yoruba bọ wọn ni ‘igi to ba tọ, kii pẹ n’igbo’, Ka nigbagbọ pe a ti fi gbogbo ẹ si ọwọ Ọlọrun. Ki Oluwa ba wa dawọ iṣẹlẹ buruku yii duro.”

Awọn eeyan to wa nibi isin imọyi fun ẹbi Fatinoye

“Ko si ohun ti wọn n se ninu ile Fatinoye, ti Lekan, awakọ wọn ko mọ tori bii ọmọ ni wọn mu”

Oloye Jiboku tẹsiwaju pe “Ọjọ ti Lekan ti de, ni mo ti mọ ọn mọ iyawo, ni bii ọdun 2018.

Iyawo yii ko fi han si awa ọrẹ ati ojulumọ wi pe boya awakọ ni. Niṣe ni wọn mu Lekan gẹgẹ bi ọmọ.

Lekan jẹ ẹni ti a ko tete mọ wi pe oṣiṣẹ ni, nitori ohun ti ọmọ wọn ba jẹ lo maa jẹ. Gbogbo ohun ti a wa n gbọ lasiko yii lo n jẹ kayeefi fun mi.

“Ni nnkan bi ọjọ marun si asiko ti wọn maa ku, ibi ti a ti n sọrọ yii la wa, ti iyawo si pe Lekan wi pe ko tete lọ bu ounjẹ, ko to di pe Oreoluwa, to jẹ ọmọ wọn de.

Mo wa nibẹ ni, wọn ko sọ fun mi. Wọn gbe gbogbo ara le.

Ko si ohun ti wọn n ṣe ninu ile, ti ko han si Lekan, ti emi si mọ si, sugbọn ile aye la ri yẹn, bi iku ile ko ba pa ni, t’ode ko le pa ni.”

Ẹbi Fatinoye

“Mo ri Lekan gẹgẹ bii oniwa irẹlẹ, sugbọn ta lo mọ pe iranṣẹ eṣu ni”

Bakan naa ni Jiboku fikun pe “Emi gẹgẹ bi eeyan kan, mi o mọ iru epe tabi ọrọ teeyan le sọ si Lekan, ju ko dakẹ, ko maa wo lọ.

Ti wọn ba lọ si ode ayẹyẹ, ti Lekan ba da joko sinu mọto, iyawo maa pariwo le e lori ni pe ko maa bọ wa jokoo lẹgbẹ oun.

Kii ṣe ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọn ti ṣe e loju mi. Eyi lo fa a to fi jẹ pe gbogbo awa ti a sunmọ wọn, ko si nnkan ti a le ṣe fun Lekan ju ka ba wọn tọju ẹ lọ.

Ṣugbọn ta lo mọ pe iranṣẹ eṣu ni.

Mo ri Lekan gẹgẹ bi ẹni to ni iwa irẹlẹ, tori pe kii sọrọ, o jẹ ki n tun wa ni oye wi pe, kii ṣe gbogbo eeyan la n gbe ara le.

Ẹni to jẹ ọmọ Ọlọrun gan-an lasiko yii, mo maa sa fun un, ko si ẹni to le mọ pe Lekan le ṣe ijamba, kii ṣe ẹni ti eeyan le ri, to le na ika aburu si.

Ikede alẹ imọyi fun ẹbi Fatinoye

Oríṣun àwòrán, Fatinoye‘s Family

Ọdun meji lo ku ki Kẹhinde fẹyin ti, ipa to ko ninu aye mi, ko kere rara. – alabaṣiṣẹpọ oloogbe ni CBN

Nigba ti oun naa n sọrọ lori iku ẹbi Fatinoye, ọkan gboogi lara awọn alabasisẹpọ Kehinde, tii se ọkọ, Rasheed Fajimi naa gbarata lori bi wn se da ẹmi rẹ legbodo.

Fajimi ni “Ọrẹ mi ni Oloogbe Kẹhinde Fatinoye jẹ. O ti to ọgbọn ọdun ti emi pẹlu Kẹhinde ti mọ ara wa.

A jọ bẹrẹ iṣẹ ni banki CBN to wa ni Abẹokuta ni, ko to di pe a lọ si Eko. Latigba naa la ti jọ wa, ko to di pe nnkan to ṣẹlẹ yii ṣẹlẹ lọjọ akọkọ ninu ọdun.

Lotitọ, onikaluku lo maa sọ ohun ti wọn ba ri, otitọ ibẹ ni pe, Kẹhinde ṣi n ṣiṣẹ lọwọ, ko tii fẹyinti.

Ọdun 2025 lo ṣẹṣẹ maa fẹyinti. Kẹhinde jẹ ẹnikan to jẹ pe ti ẹ ba ba nnkan to n dun yin lọ s’ọdọ rẹ, ẹrin lẹ maa ba kuro.

“Ipa to ko ninu igbesi aye mi, gẹgẹ bi ọrẹ, ko kere rara, o mu ile aye gẹgẹ bii pe ko jẹ nnkan teeyan le wa mọ aya.

A ti di ọrẹ bi ọmọ iya, eeyan ko le rin, ki ori ma mi, ṣugbọn kii ṣe bi ki ẹ ba iranlọwọ lọ sọdọ, ko sọ pe ko si.”

Ile Fatinoye ti wọn sọ ina si

Nnkan ti Lekan awakọ se fun wa kọja ohun ti Judasi ṣe, gbogbo ẹbi lo da loro”- Ẹgbọn ati aburo Oloogbe

Ẹgbọn Kehinde Fatinoye ti oun naa sọrọ nibi isin imọyi naa kede pe oloogbe gbiyanju fun gbogbo ẹbi rẹ, ki wọn to da ẹmi rẹ legbodo laipe ọjọ.

O gbiyanju fun awa mọlẹbi ati ọrẹ. Ko si ẹni to maa sunkun de ọdọ ẹ, ti ko ni ba ẹrin pada. Igbakeji alakoso ni Kẹhinde ni ẹka to wa.

Kẹhinde lo ran akọbi mi lọ si fasiti ipinlẹ Delta jade. Ọmọ mi keji naa, Kehinde lo n ran an lọ si ile ẹkọ gbogboniṣe t’ipinlẹ Eko.”

Bakan naa ni Zaccheus Fatinoye tii se abiro oloogbe salaye pe o ku ọsẹ keji ki wọn pa ẹgbọn oun, lo ra foonu tuntun fun mi

O ni awọn marun-un lawọn obi wọn bi, akọbi wa ti ku, ẹni to ṣikẹta ni Kẹhinde ti wọn pa yii.

O ni ibanujẹ nla ni iku Kehinde jẹ fun oun,nitori ẹni to n ran awọn lọwọ ninu mọlẹbi niyẹn.

“Kii ṣe pe mi o ṣiṣẹ, ṣugbọn bi mo ba ni iṣoro to fẹ ga ju ẹmi mi lọ, ẹnikan ti mo n sare lọ ba niyẹn.

Inu oṣu kọkanla ni ẹgbọn mi gbọ pe mo ra ilẹ si agbegbe Ilogbo, wọn si pe ẹni to ta ilẹ fun mi, wọn si fun ẹni naa ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira gẹgẹ bi owo bulọọku lati fi kọ ile naa.

Ka ni mo tete sọ ni, maa ti pari ile naa. Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun 2022 ni ẹgbọn mi tun ra foonu fun mi.

Titi aye ni ma maa fi ranti ẹgbọn mi. Awọn ni wọn ran ọmọ mi lọ si ileewe giga, bẹẹ ni wọn tun n fun ọmọ naa ni ẹgbẹrun mẹwaa naira loṣooṣu.

Nnkan ti Lekan ṣe yii, kọja ohun ti Judasi ṣe fun Jesu. Gbogbo ẹbi lo da loro”

Ẹbi Fatinoye

Ọjọ mẹta lo ku ka bẹrẹ iṣẹ akanṣe ni ṣọọṣi, ni wọn pa Fatinoye – Ọmọ ijọ ti oloogbe n lọ

Ẹgbẹ African Christian Fellowship ti oloogbe Kehinde Fatinoye wa ninu rẹ naa sọrọ nibi isin imọyi rẹ.

Ọgbẹni Sanmi Ogundele to jẹ ọmọ ẹgbẹ naa ni Oloogbe ni aarẹ ẹgbẹ lati bii ọdun mẹfa, tawọn si ti setan lati bẹrẹ akanse isẹ ti wọn n se lọwọ pada ninu ijọ naa, ki iku to mu lọ.

“Ẹni ti kii ta ẹnikẹni nu lawọn oloogbe yii jẹ. Iwa ọmọluabi si wa lara awọn mejeeji. Ko sẹni to le dahun bi ile naa ṣe jona.

Emi ni mo pe Lekan, awakọ wọn pe ko wa si ile naa, nnkan bi aago mọkan si mejila ni lo de.

Bo ṣe de ni ọga ọlọpaa beere pe ṣe awakọ wọn niyẹn, wọn si ba a sọrọ.

Igba ti wọn sọrọ tan, ni wọn gbe e lọ teṣan. A ko mọ pe oku wọn wa ninu ile.

Igba ti aburo oloogbe, to jẹ n Ṣeyi de, la to mọ pe oku wọn wa ninu ile.

Mo mọ Lekan daadaa, mo mọ adugbo ti Lekan n gbe ni Oke-Lantoro niluu Abẹokuta.

Ile mi ni ni gbogbo wọn ti ṣe ayeyẹ ọdun keresimesi, Lekan ti ba nnkan jẹ gidi, ko ni atunṣe mọ.

Ki ijọba ṣe ohun to tọ, ati eyi to yẹ lori ọrọ yii, nitori pe gbogbo agbaye lo ti mọ ohun to ṣẹlẹ yii.”

Ọkùnrin méjì tó rà mọ́tò Fatinoye bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá

Aworan

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede orukọ afurasi meji to ra ọkọ ayọkẹlẹ Kehinde Fatinoye, lẹyin ti awọn afurasi agbebọn meji ati awakọ rẹ jo o nina mọle niluu Abeokuta.

Atẹjade kan agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi sita lọjọ Isẹgun lo ṣiṣọ loju ọrọ yii.

Atẹjade naa ni igbesẹ naa waye nibamu pẹlu ileri oun lati mu gbogbo awọn to lọwọ ninu iku mọlẹbi Fatinoye.

Awọn afurasi meji tọwọ tẹ ọhun ni Azeez Usman ati Owolaja Aanuoluwapo.

Agbegbe ọtọtọ nipinlẹ Ogun lọwọ ti tẹ awọn mejeeji lẹyin ti awọn afurasi mẹta akọkọ ti jẹwọ fun ọlọpaa pe Azeez Usman lo ra mọto naa.

Wọn ni owo toto ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira, N150,000, ni Azeez ra mọto naa.

A mọ pe wọn ji mọto naa gbe ni, a si ra a ni N150,000 – Awọn afurasi to ra ọkọ Fatinoye

Atẹjade naa ni lẹyin ti afurasi apaniyan naa ṣekupa tọkọtaya tan, ni wọn de ọmọ wọn kan soso, Oreoluwa ati ọmọ ti wọn gba tọ, Felix Ọlọrunyomi ni okun.

Awọn ọmọ naa si ni wọn gbe lọ si ẹyin mọto Hyundai, ti wọn wa lọ si odo Ogun ni afara Adigbe, nibi ti wọn ju wọn si.

Oyeyemi tẹsiwaju pe, lẹyin ti wọn ju awọn ọmọ naa sodo, ni wọn gbe ọkọ ayọkẹlẹ naa lọ ibi kan ni Oke Ate.

Ibẹ si ni wọn ti pe Owolaja AanuOluwapo lati lọ gbe ọkọ naa fun Azeez Usman ni sọbu rẹ, ẹni to fọ ọkọ naa si wẹwẹ, ti wọn si ta paati ọkọ naa ni ẹyọ-ẹyọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn afurasi mejeeji naa ni lootọ ni awọn mọ pe wọn ji ọkọ naa gbe ni, ti awọn si ra ni ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira.

Kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Frank Mba, ti wa pasẹ pe ki wọn gbe awọn afurasi naa lọ si ileẹjọ lẹsẹkẹsẹ lẹyin ti iwadi ba ti pari.