Wàhálà dé! Delta, Edo, Ondo dara pọ̀ mọ́ Oyo àti Kwara fún ìwọ́de lórí ìnira àtúnṣe Naira

Aworan awọn oluwọde lagbegbe Iyana church nilu Ibadan

Iwọde tun ti bẹrẹ lawọn ilu kan lorilẹede Naijiria latari inira paṣipaarọ owo naira tuntun ati ọwọngogo epo bayii.

Lara awọn ipinlẹ ti iwọde naa ti n dun lakọlakọ bayii ni Ọyọ, Ondo, Delta ati Edo.

Ibadan

Agbegbe apẹtẹ nilu Ibadan

Iwọde n waye lawọn agbegbe kaakiri ibadan bii Mọkọ̀la, iyana church, opopona Elẹyẹle si Eruwa.

Gbogbo awọn ọkọ to n rin lagbegbe naa ni wọn n da pada ti ọpọ awọn ile ẹkọ si nilo lati tete palẹ mọ fun awọn akẹkọọ lati tete pada sile.

Lagbegbe Mọkọla, nṣe lawọn oluwọde da gbogbo eto karakata duro nibẹ pẹlu bi olukuluku ṣe n bẹru abo rẹ.

Agbegbe apẹtẹ nilu Ibadan

Awọn oluwọde kan tilẹ gbe iwọde wọn lọ sileeṣẹ redio kan nibi ti wọn ti ni ontaja worobo lawọn, gbogbo ọja ti awọn si ta ni ọjọ Iṣẹgun, owo naira tẹlẹ lawọn gba ki awọn to de banki nibi ti wọn ti n kọ owo naa si awọn lọwọ.

Awọn ero miran pẹlu wa niwaju ẹka banki apapọ Naijiria nilu Ibadan to wa lagbegbe Dugbẹ lati ṣe paṣipaarọ owo wọn.

Agbegbe apẹtẹ nilu Ibadan

Bakan naa lawọn oluwọde kan naa wa lagbegbe sẹkiteriati ijọba nilu Ibadan lati fi ẹhonu tiwọn han pẹlu.

Ṣaaju lawọn akẹkọọ kan ti ya bọ sita lagbegbe Apẹtẹ nilu Ibadan lati fi ẹhonu han lori inira ti wọn n koju pẹlu ọrọ paṣipaarọ owo naira ati ọwọngogo epo yii.

Akurẹ

Agbegbe Round about nibi First Bank nilu Akurẹ

Awọn oluwọde ya bo agbegbe roundabout nilu Akurẹ nibi ti di ọna to lọ si banki Firsat bank to wa nibẹ.

Ọna yii lo lọ si ọfiisi gomina ipinlẹ Ondo, ọfiisi ẹka banki apapọ Naijiria CBN nilu Akurẹ, mọfiisi ajọ eleto idibo INEC ati ọfiisi ajọ idanwo aṣewọfasiti JAMB atawọn banki miran.

Delta

Awọn oluwọde ni Udu junction ni ipinlẹ Delta

Oríṣun àwòrán, screenshot

Wọlukọlu n waye bayii ni ipinlẹ Delta nibi ti awọn oluwọde ti dana di awọn opopona nlanla nibẹ.

Gbogbo nnkan ti ọwọ wọn ba ni ileto Orhuwhorun nijọba ibilẹ Udu, ni wọn n dana sun titi kan irinṣẹ ATM lawọn banki nibẹ.

Awọn ọdọ n fi ẹhonu han lori inira ọwọn gogo paṣipaarọ owo naira igba naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹgbẹrun naira.

Iwọde naa kọkọ bẹrẹ lagbegbe Orhuwhorun junctiony, ki o to ya wọ opopona marosẹ to wa nibẹ.

Amọṣa gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa ti pe fun suuru latọdọ awọn oluwọde.

Gomina Okowa rawọ ẹbẹ ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun eto iroyin, Charles Anigwu fi sita.

Bakan naa lo tun fi arọwa ranṣẹ si Banki apapọ Naijiria, CBN atawọn alaṣẹ eto iṣuna lorilẹede Naijiralati jawe si obi iye owo ti wọn n tẹ siota.

Edo

Ọpọ ero lo n fi ẹhonu han lopopona Akpakpava road nilu Benin city lori inira ti wọn koju lati ri paṣipaarọ owo ṣe.

Nṣe ni wọn di ọna naa pa pẹlu taya ti wọn n da ina sun laarin opopna naa ti ọkọ kankan ko si lee raye kọya.

Ìléẹjọ́ gíga Naijiria sún ìgbẹ́jọ́ lórí owó tuntun Naijiria sí February 22

Owo Naira tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileẹjọ giga julọ lorilẹede Naijiria ti sun igbẹjọ si iwaju lori ẹjọ ti awọn gomina pe lati tako igbeṣẹ tuntun lori naira tuntun ni Naijiria

Adajọ John Okoro to dari igbimọ onidajọ onigun meje ni wọn sun igbẹjọ naa siwaju di Ọjọ Kejilelogun, Oṣu Keji, ọdun 2023.

Lasiko to n ba awọn to wa ni ileẹjọ sọrọ ni ipinlẹ mẹsan ni awọn to ti so mọ ipẹjọ naa

O ni awọn ko ni fi igbẹjọ naa falẹ, ti awọn si ni ọyẹ nipa idojukọ awọn araalu.

Ọgọọrọ eniyan lo pejọ pọ si ibi igbẹjọ naa, ti ayika ileẹjọ naa si kun fọfọ.

Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ati gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai naa wa nibi igbẹjọ naa.

Awọn agbẹjọ ni sisun igbẹjọ naa siwaju tun mọ si pe banki ati CBN gbọdọ gba owo atijọ ati owo tuntun naa lasiko yii.

Awọn ipinlẹ mẹfa miran lo tun darapọ mọ igbẹjọ naa lati tako owo naira tuntun naa.

Awọn ipinlẹ ọhun ni Eko, Ekiti, Osun, Katsina, Ondo, Cross Rivers, Bayelsa ati Edo.

Òní ní iléẹjọ́ “Supreme Court”yóò gbẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ owó náìrà àtijọ́ ní Naijiria; Ohun tó yẹ kẹ́ẹ mọ̀ nìyí

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ni ko i tii mọ koko lori ọrọ owo naira atijọ ni Naijiria.

Ibeere ti awọn eniyan n beere ni pe ṣe wọn ṣi lee na owo atijọ 1000, 500 ati 200 naira, lẹyin ti banki apapọ Naijiria kede pe Ọjọ kẹwaa, Oṣu Keji ni gbendeke nina owo atijọ ni Naijiria.

Amọ loni, Ọjọru ni ileẹjọ to gajulọ ni Naijiria yoo gbe idajọ kalẹ lori igbesẹ banki apapọ Naijiria na.

Ileẹjọ to gajulọ ti yoo gbe idajọ kalẹ ni ilu Abuja loni ni wọn paṣẹ fun CBN lati dawọ duro lori aṣẹ wọn amọ ko dabi ẹni pe wọn mu aṣẹ naa ro.

Aṣẹ ti ileẹjọ gigajulọ pa nipe awọn eniyan ṣi le na owo atijọ naa titi di Ọjọ Karundinlogun, oṣu keji, ọdun 2023 titi ti idajọ yoo fi waye.

Kilo ti ṣẹlẹ ṣẹyin?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin ti ileẹjọ giga julọ lorilẹede Naijiria paṣẹ pe ki wọn gbegi le didena lilo owo atijọ ni Naijiria, Olootu eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami ni ki ileẹjọ da ipẹjọ naa danu.

Awọn gomina ipinlẹ mẹta ni iha ariwa orilẹede Naijiria lo pe ẹjọ naa mọ CBN, pe ki ijọba fi ofin de aṣẹ pe ki awọn eniyan ma na owo atijọ mọ ni Naijiria.

Amọ Malami ni ileẹjọ giga julọ lorilẹede Naijiria ko ni aṣẹ lati sọrọ lori iru ipẹjọ bayii.

Bakan naa ni iroyin kan jade ni Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Keji, ọdun 2023 pe gomina banki apapọ, Godwin Emefiele paṣẹ pe ko si mimi kan ti yoo mi aṣẹ oun lori gbedeke ati na owo atijọ ni Naijiria.

Amọ ni ọjọ kan naa ni ijọba ipinlẹ Kano paṣẹ pe banki tabi awọn ile itaja ti ko ba gba owo naira atijọ lọwọ awọn eniyan yoo foju wina ofin, ti yoo si di titi pa.

Titi di asiko yii, aarẹ Buhari to ni ki wọn fun wọn ni Ọjọ meje lati wa ọna abayọ si iṣoro to rọ mọ owo Naira naa ko i tii sọ nkankan fun awọn ọmọ Naijiria.