Wo àwọn nǹkan tó yẹ kí ìjọba ṣe láti mú àdínkù bá bí owó Náírà ṣé ń já wálẹ̀ ní gbogbo ìgbà

Owó náírà àti dọ́là

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Láti nǹkan bíi oṣù méjì sẹ́yìn ni àlékún bí àwọn ènìyàn ṣe ń bèèrè fún owó dọ́là tó jẹ́ owó ilẹ̀ òkèrè.

Èyí sì ló ṣe okùnfà bí ìkúrẹtẹ̀ ṣe ń bá owó náírà, tó sì ń ṣe àkóbá fún ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.

Àwọn onímọ̀ sọ pé ìjọba nílò láti tọná wá ọ̀nà láti mú kí owó náírà rí ìrúgọ́gọ́ ní ọjà àgbáyé tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àmójútó bí owó dọ́là ṣe ń gbowó lórí gegege sí owó náírà.

Ní ojoojúmọ́ ni owó náírà ń já wálẹ̀ sí owó dọ́là bí owó dọ́là kan ṣe ti di N945 lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kẹjọ ọdún 2023 nítorí iye dọ́là tó wà nílẹ̀ kó tò ohun tí àwọn ènìyàn ń fẹ́.

Orílẹ̀ èdè tí ọrọ̀ ajé rẹ̀ bá gbáralé kíkó ọjà wọlé láti ilẹ̀ òkèrè bíi ti Nàìjíríà báyìí máa kojú ìṣòro ìnílò owó dọ́là lọ́pọ̀lọpọ̀.

Adélé alága ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà (CBN), Folashodun Shonubi ní ó jẹ́ ohun tó ṣeni láàánú pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tún ń ti gbogbo àwọn okoòwò èyí tó jẹ́ ti abẹ́lẹ́ mọ́ dọ́là lọ́rùn.

Onímọ̀ nípa owò kan, Victor Aluyi ní bí àwọn ènìyàn ṣe ń lo owó dọ́là kò ní wálẹ̀ rárá pé ohun tó yẹ kí ìjọba ṣe ni láti pèsè owó dọ́là kó pọ̀ yanturu.

Onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé mìíràn, Muda Yusuf ní CBN nìkan ló ní àṣẹ láti kó dọ́là wọ inú ìlú, kò sí ẹni tí le kó owọ ilẹ̀ òkèrè wọlé láì sí ìmọ̀sí CBN.

Aluyi ní tí ọ̀rọ̀ bá ti di báyìí, tí àwọn ènìyàn ń nílò owó dọ́là púpọ̀ báyìí, ohun tó yẹ kí CBN ṣe ni láti lo owó tó wà ní ìpamọ́ ní akoto owó ilẹ̀ òkèrè tó jẹ́ ti ìjọba láti fi dá ààbò bo owó náírà.

Lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Bola Tinubu, níṣe ni dọ́là di iye kan náà ní ọjà àgbáyé àti ní àwọn ilé ìfowópamọ́.

Ohun tí ìjọba fi ṣe èyí ni láti lè jẹ́ kí àwọn tó kó owó dọ́là pamọ́ kó owó náà síta kó lè pọ̀ yanturu tí àdínkù yóò sì bá bí ó ṣe gbówó lórí.

Aluyi ní pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé owó ilẹ̀ òkèrè tí ìjọba Nàìjíríà ní tó wà ní ìpamọ́ kò tó nǹkan ìyẹn bílíọ̀nù $18b, CBN kò lágbára púpọ̀ tó lè sà láti fi dá ààbò bo owó náírà.

Àwọn onímọ̀ ní owó náírà kò bá ní já wálẹ̀ ní ọjà àgbáyé bó ṣe ti ń jà láti bíi oṣù méjì sẹ́yìn, ìjọba nílò láti mójútó àwọn ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

Adelé gómìnà CBN, Shonubi ní àwọn kò gbàgbọ́ pé bí àwọn ènìyàn ṣe ń bèèrè fún owó dọ́là ní ó ń ṣe okùnfà bí náírà ṣe ń já wálẹ̀.

Shonubi ní àwọn tó ń ra dọ́là pamọ́ pẹ̀lú ìrètí pé àwọn máa ta ní owó ńlá ló fa ìdí tí owó náà fi ń gbé ẹnu sóke ní gbogbo ìgbà.

Lẹ́yìn tó ṣe ìpádé pẹ̀lú ààrẹ lọ́jọ́ Ajé, Shonubi ní nǹkan tí àwọn ń gbèrò láti ṣe fún àwọn tó ń kó owó dọ́là pamọ́, lẹ́yìn ìgbésẹ̀ àwọn níṣe ni wọ́n máa pàdánù owó wọn.

Àmọ́ àwọn onímọ̀ ní díẹ̀ ni nǹkan tí CBN lè ṣe láti mú àdínkù bá bí owó náírà ṣe ń já wálẹ̀.

Àwọn ìgbésẹ̀ náà nìyí:

Mú àdínkù bá àwọn tó máa ń ra dọ́là pamọ́

Muda ní àwọn ní ìmọ̀ pé díẹ̀ ni nǹkan tí CBN lè ṣe lórí owó dọ́là tí wọ́n sì ń lo àǹfàní yìí láti máa fi kó owó dọ́là pamọ́.

Ó ní àwọn ènìyàn yìí ní ìgbàgbọ́ pé náírà máa wọ N1,000 sí dọ́là kan, ìdí nìyí tí wọ́n fi ń rà á pamọ́ láti tà á ni iye yìí.

Àwọn tó ń pèsè ọjà kìí lo dọ́là ní oṣooṣù àmọ́ níṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn máa ń ra dọ́là pama nítorí pé ó ti le gbé owó lórí lásìkò tí wọ́n bá fẹ́ lò ó.

Ìjọba tuntun tó gba ipò lọ́wọ́ ààrẹ Buhari bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbèsè àìsí owó dọ́là nílẹ̀.

Lára rẹ̀ ni owó $800m èyí tí CBN jẹ àwọn iléeṣẹ́ ètò ìrìnnà òfurufú èyí tí kò lè kó èrè wọn lọ sí ìlú nítorí wọn kò rí owó náà pàrọ̀ sí dọ́là.

Ní àfikún sí èyí Yusuf ní CBN náà ṣe àwọn màkàrúrù kan àti pé ìjọba Buhari k]o san àwọn gbèsè kan padà.

Musa ní gbogbo àwọn gbèsè tó wà nílẹ̀ yìí náà ń mú ìfàsẹ́yìn bá owó náírà ní ọjà àgbáyé.

Dídẹ́kun gbígbe epo wọlé láti ilẹ̀ òkèrè

Epo bẹntiroolu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbígbe epo bẹntiro wọlé láti ilẹ̀ òkèrè jẹ ohun kan tó ń dá wàhálà sílẹ̀ ní Nàìjíríà láti bí oṣù méjì sẹ́yìn.

Epo tó ń wọlé láti ilẹ̀ òkèrè ni [ń gbé ara lé jùlọ nítorí kò sí èyí tó ń ṣiṣẹ́ nínú àwọn ilé ìfọpo rọ̀bì tí Nàìjíríà ní.

Yusuf ní tí kò bá sí à ń gbé epo wọlé láti ilẹ̀ òkèrè, iye dọ́là tí àwọn ènìyàn máa nílò lówó ilẹ̀ òkèrè máa dínkù jọjọ.

Ó ní Nàìjíríà máa ń gbé epo tó lé ní bílíọ̀nù kan dọ́là wọlé ní oṣooṣù, tí èyí bá sì ti kúrò níbẹ̀ bí àwọn ènìyàn ṣe ń nílò dọ́là máa dínkù.

Fòpin sí ìwà àjẹbánu

Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó ń bá Nàìjíríà fínra ni ìwà jẹgúdújẹrá tí àwọn onímọ̀ sì sọ pé ìwà àjẹbánu sì wà lára àwọn nǹkan tó ń fà á tí owó Nàìjíríà fi ń lọlẹ̀ síi.

Àwọn tí owó wọn kò mọ́ máa ń fẹ́ láti ní owó náà ní owó ilẹ̀ òkèrè nítorí kí ìkúrẹtẹ̀ má ba à báa.

Muda ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń kó owó ìlú jẹ ni wọ́n máa ń ṣẹ sí owó ilẹ̀ òkèrè àti pé àwọn tí wọ́n máa ń fún àwọn ènìyàn ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń san owó bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú owó ilẹ̀ òkèrè.

“Àwọn tí wọn kò ṣiṣẹ́ fún owó wọn máa le ra dọ́là ní iyekíye tí wọ́n bá pè é nítorí kìí ṣe òógùn wọn àma kò rí bẹ́ẹ̀ fún oníṣòwò tó bá fẹ́ pààrọ̀ owó.”

Bá iye epo ti Opec ń fẹ́

Ọna ti epo n gba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ó pọn dandan fún Nàìjíríà láti mú àlékún bá iye epo rọ̀bì tó ń pèsè láti bá iye tí Opec ń fẹ́ kí Nàìjíríà máa pèsè.

Aluyi ní iye epo rọ̀bì tí Nàìjíríà bá ta máa nípa lóri iye dọ́là tí CBN yóò rí gbà.

Ìdá tó lé ní àádọ́rùn-ún owó ilẹ̀ òkèrè tó ń wọ Nàìjíríà lọ ń wá láti ẹ̀ka epo rọ̀bì èyí tí CBN le lò láti fi da ààbò bo náírà.

Àmọ́ àìsí ààbò ní ẹkùn Niger Delta ń ṣe àkóbá gidi fún okoòwò epo rọ̀bì ó ní bí àwọn ènìyàn ṣe ń jí epo rọ̀bì ní ẹkùn Niger Delta ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ kọgbá sílé.

Muda náà ṣàlàyé pé tí Nàìjíríà bá ń pèsè iye tí Opec ń fẹ́, yóò mú ìdẹ̀kún bá owó náírà.

Gba àwọn olùdókoòwò láti ilẹ̀ òkèrè wọlé

Bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn olùdókoòwò láti ilẹ̀ òkèrè máa ń pa owó wọn pẹ̀lú dọ́là, ó pọn dandan kí Nàìjíríà wá bí wọ́n ṣe máa dókoòwò ní orílẹ̀ èdè yìí.

Kí àwọn olókoòwò bẹ́ẹ̀ tó lè wá sí Nàìjíríà, Muda ní ètò ààbò Nàìjíríà gbọ́dọ̀ dúró ire àti pé àwọn òfin gidi tó de okoòwò gbọ́dọ̀ fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀.

Nàìjíríà jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ọ̀rá tí àwọn olùdókoòwò ń wá èyí ló si fi ṣe pàtàkì kí ìjọba fi àyè sílẹ̀ fún àwọn tí yóò dókoòwò láti rí nǹkan wá jókòó tì.

Ọ̀pọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè ló ti kó ọrọ̀ ajé wọn kúrò ní Nàìjíríà ní àwọn ìgbà kan sẹ́yìn nítorí ojú ọjà Nàìjíríà kò bá wọn ètò wọn mú.

Ìpèsè àwọn ohun amáyédẹrùn

Ọkọ̀ ojú irin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iná mọ̀nàmọ́ná, ọ̀nà tó dùn-ún àti ọ̀nà ojú irin láti máa gbé ọjà káàkiri orílẹ̀ èdè yìí jẹ́ ọ́nà láti fi pe àwọn olùdókoòwò wọlé láti ilẹ̀ òkèrè.

Àmọ́ iná ọba àti ètò ìrìnnà Nàìjíríà kò dúró ire tó.

Muda ní kò sí olùdókoòwò tí yóò fẹ́ láti gbé iléeṣẹ́ rẹ̀ wọ ibi tí yóò ti máa nílò láti máa ra ẹ̀rọ amúnáwá lkó tó lè ṣiṣẹ́.

Ó ní gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ti gbọ́dọ̀ wà nílẹ̀ tí àwọn olùdókòwò ilẹ̀ òkèrè yóò bá wá sí Nàìjíríà láti ṣe ọrọ̀ ajé.