Ẹ lọ fọkànbalẹ̀, kò lè sí ẹ̀kúnwó epo bentírò- Ìjọba Àpapọ̀

Aworan patako NNPC

Oríṣun àwòrán, NNPC

Aarẹ Bola Tinubu ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ko ni si ẹkunwo epo bẹntiro gẹgẹ bi awọn iroyin kan ti ṣe n gbe e kaakiri.

Agbẹnusọ fun àa[rẹ orilẹede Naijiria, Ajiri Ngelale ko si oniṣowo epo kankan to laṣẹ lati fi owo kun epo bo ba ṣe wu wọn.

O fi kun un pe ijọba ti n gbe igbesẹ lati pinnu iye ti owo epo bẹntiro yoo ma jẹ.

Eyi lo waye lẹyin ti Ileeṣẹ to n ri si epo bẹntiro NNPC kede pe awọn ko ni erongba lati fowo kun owo epo bẹntiro.

Ninu atẹjade kan ti Ileeṣẹ NNPC fi lede lọjọ Aje, Ileeṣẹ naa rọ awọn ọmọ Naijiria lati maṣe kọ ibi ara si iroyin ofege naa.

NLC, ti sọ pe oun yoo gunle ieyanṣẹlodi ti ijọba ba tun fi owo le owo epo bẹntiro.

Adari NLC, Joe Ajaero, lo fi ọrọ naa lede nibi ipade ẹgbẹ African Alliance of Trade Unions, to waye niluu Abuja.

Lati ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2023, ti ijọba tuntun ti gori alefa ni Naijria ni ajọ NNPC ti n fi kun owo epo lemọlemọ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, N185 ni owo epo naa tẹlẹ ko to fo lọ si N500, ko to di pe o bọ si N617 loṣu to kọja.

Bí Tinubu bá tún fi kún owó epo, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì – NLC

Aworan Iwọde NLC

Oríṣun àwòrán, STRINGER

Awọn olori ẹgbẹ osisẹ NLC lorilẹede Naijiria, , ti se ikilọ fun ijọba apapọ pe awọn yoo gun le iyansẹlodi ni ti ijọba ba fi le fi aye silẹ fun ilewo lori owo epo bẹntiro.

Ajọ to n se amojuto epo bentiro lorilẹede Naijiria ti n kede ẹkunwo lori owo bentiro lati igba ti Aarẹ Bola Tinubu ti kede yiyọ owo iranwọ kuro lori epo bentiro.

Lasiko to n sọrọ ni bi apero ipade Africa Alliance Trade Unions Executives niluu Abuja, Aarẹ ẹgbẹ oṣisẹ, Joe Ajaero ni awọn osisẹ lorilẹede Najiria ko ni fi aye gba irufẹ igbesẹ yii lẹyin to ti waye nigba meji ọtọtọ ti wọn kede ilewo lori owo epo bẹntiro.

Saaju ki ijọba Aarẹ Bọla Tinubu to wọle sori oye, naira marunlelọgọsan (N185) ni owo epo bẹntiro lorilẹede NAijiria ki o to fo fẹrẹ titi to fi de nnkan bii ẹgbẹta naira to wa bayii.

“Bi a se wa ni bi bayii, wọn ti n gbero lati fi owo kun owo epo . Minista fun ọrọ osisẹ yoo wa lọ si ileẹjọ tako igbinyanju ẹgbẹ oṣisẹ lati ma le fesi.”

Awọn olori ẹgbẹ osisẹ kaakiri ilẹ Adulawọ bii orilẹede Ghana, Kenya, Senegal ati South Africa lo wa ni ikalẹ nibi ipade ọhun.

Bakan naa ni wọn fi asiko naa kesi ajọ isọkan ECOWAS lati ma gbe igbesẹ ologun ninu igbinyanju wọn lati yanju ọrọ oselu to n lọwọ lorilẹede Niger.