Àlejò ń fẹ́ lé Onílé jáde lọ̀rọ̀ àwọn Alfa tó ń gbógun tí oníṣẹ̀ṣe nílùú Ilorin- Ifayemi Elebubon

Aworan Baba Elebubon

Oríṣun àwòrán, Araba Ifayemi Elebubon

Araba awo ti ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon ti sọrọ sita lori idunkoko ti Ẹgbẹ apapọ Afaa niluu Ilorin gbe sita lati tako erongba awọn Onisẹse lati se ọdun isẹse logunjọ oṣu kẹjọ nipinlẹ Kwara.

O sapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bi ti alejo to fẹ le onile jade ni ile rẹ.

Baba Ẹlẹbubọn, lasiko to n ba Ileeṣẹ BBC Yoruba sọrọ, jẹ ko di mimọ pe igbesẹ awọn Musulumi ati Ileeṣẹ Ọlọpaa tako ofin orilẹede Naijiria to fi aye silẹ fun onikaluku lati se ẹsin to ba wu u.

‘Awọn ọlọpaa n ṣe oju iṣaaju lori ọrọ to n ṣẹlẹ ni Kwara’

Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuubọn tẹsiwaju lati kọminu lori bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe n ṣe lori ọrọ naa.

ninu ọrọ rẹ, nṣe lawọn ọlọpaa n ṣegbe dipo ki wọn na tan si aarin gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ja fun ofin ati ibọwọ fun ofin.

“Ojusaju ni nnkan ti ileeṣẹ ọlọpaa se, wọn kọ lati sọ ọrọ si ibi ti ọrọ wa

“Se Ilu Ilorin da yatọ ni?, Ibeere to yẹ ki a bi awọn Ọlọpaa ati awọn Musulumi niyẹn

“Se Ilu Ilorin kan dede wu nilẹ ti ko si ki n se Yoruba abi se ilẹ Fulani ni ilu Ilorin.”

Ẹlẹbubọn tẹsiwaju pe ki se pe Oosa sẹsẹ de si Ilu Ilorin sugbọn awọn Musulumni ni wọn fi tipatipa mu adikun ba iye awọn Onisẹse niluu Ilorin.

“Ofin ilẹ Naijiria sọ fun wa pe onikaluku ni anfani lati se ẹsin to ba wu

“N jẹ ọdun Isẹse ti wọn fẹ se pawọn lara tabi se o ni idiwọ kankan, wọn kọ lọ si Mọsalasi tabi Aafin, bakan naa ni wọn fa ijangbọn.”

Tí ìjà bá wáyé nílùú Ilorin Àwọn ẹlẹ́ṣin imole ni

Araba lasiko to n fesi ọrọ ti Akọwe ẹgbẹ agbajọpọ awọn afaa niluu Ilorin, Salihu Mohammed sọ lori wi pe sise ọdun Isẹse le mu ewu dani fun ẹmi ati dukia awọn olugbe Kwara.

Baba Araba ni ko seese ki awọn Onisẹse fa wahala lasiko Ọdun isẹse nitori gbogbo awọn ipinlẹ ti ọdun yii ti n waye, ti ko sisi rogbodiyan kankan.

“Ti ija ba waye lasiko ọdun Isẹse, awọn nani, ki se Ilorin nikan ni wọn ti se Ọdun Isẹse lorilẹede Naijiria.

“Nipinlẹ Osun, Oyo, Ogun ati Oyo ni ọjọ isinmi, se wọn ba dukia jẹ, kini Ilorin fi ya da yatọ.

“Ojusaju ni wọn se, se wọn le sọ pe ki wọn ma se ọdun Ileya niluu Ilorin

“Ọga ọlọpaa ko se daada, ẹsin Ibilẹ lo fi aye gba awọn ẹsin alejo yii, ti wọn wa fẹ le wa jade.”

Araba wa rọ gbogbo ẹlẹsin ibilẹ lati fọwọ wọnu lori bi nnkan se waye nitori ẹlẹsin ibilẹ ki se oni wahala.

“A ki se oni wahala, a bẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ pe ki wọn fọwọ wọnu

“A ma wo wọn, ẹni to ba yẹ ka pe lẹjọ, a yoo pe wọn lẹjọ.”

Ki ni sẹlẹ saaju?

Awon elẹsin Musulumi atawon ẹlẹsin iṣẹṣe ni ilu Ilọrin ti fọwọ siwe adehun alaafia wi pe ki yoo si ija ẹsin tabi jagidijagan botiwu o kere mo laarin awon.

Adehun yii lo waye latari ipade alaafia ti CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi pe laarin awon aafaa ati awon oniṣẹṣe Ilọrin lori bi igun mejeeji ṣe n dunkoko mọ ara wọn.

Aafaa Okutagidi to ṣoju gbogbo awọn aafaa niluu Ilọrin sọ pe nnkan ẹyọkan tawọn n ja fun ni pe awọn ko faye gba ki awọn oniṣẹṣe ṣe n nnkan miran yatọ si ẹsin Islam.

O ni “Ilọrin ki i bọ nnkankan, o le bọ ọ ninu yara rẹ sugbọn wọn ki i bọ ọ ni gbangba.

O tẹsiwaju pe laye awọn baba nla awọn ni awọn ti n pana ẹbọ ti ko si le bẹrẹ pada lasiko tawọn bayii.

Nigba to n sọrọ lorukọ awon oniṣẹṣe, Ifadara Ifasola jẹ ki o di mimọ pe ohun to ṣokunfa ija ni pe awọn gbọ pe aafaa kan lọ seti odo Iyemọja to wa lagbegbe Oko-Olowo, ti wọn si ni awọn fẹ ro odo.

Lawọn wa wo o pe ti wọn ba ro odo ti aburu si ṣẹlẹ si gbogbo awọn to ba lo omi naa, yoo ba awon oniṣẹṣe lorukọ jẹ nitori odo ti awọn n bọ ni, lawọn ṣe gbe igbesẹ, tawọn aafaa tun fi wa ṣakọlu si ile oun lalẹ ọjọ Isẹgun ọjọ kẹẹdọgbọn, osu Keje yii.

Ifasola ni kii ṣe pe awọn sẹsẹ bẹrẹ iṣẹṣe niluu Ilọrin, awọn ti n ṣe bọ ọjọ ti pẹ ṣugbọn gbogbo igba ni awọn aafaa ma n di awọn lọwọ, koda o ni wọn ti gbiyanju lati dana sun ile bab oun ri.

‘Orilẹede Niajiria kii ṣe ẹlẹsin kan ṣoṣo’

Gẹgẹ bii ohun ti ofin sọ, Naijiria kii ṣe orilẹ-ede ẹlẹsin kan ṣoṣo bii awọn orilẹ-ede bii Iran, Iraq, Saudi Arabia, Pakistan, Afganistan, Yemen, Morcco, Algeria, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

To n tumọ si pe ẹsin to ba wu onikaluku lo le ṣe gẹgẹ bii ohun to wa ninu iwe ofin orilẹ-de Naijiria, eyii ti wọn kọ lọdun 1999.

Iwe ofin Naijiria, ori kẹrin, ẹsẹ kejidinlogun, abala kinni sọ pe “gbogbo eeyan lo lẹtọọ si ominira ero, ẹri ọkan ati ẹsin, pẹlu ominira lati kuro ninu ẹsin kan lọ si omiran, ati ominira (yala oun nikan tabi toun ti awọn eeyan miran, wọn si le ṣe eyii ni kọrọ tabi ni gbangba) lati fi ẹsin rẹ han, ṣe itankalẹ ẹsin, tabi igbabọ ijọsin, ikọni ati iṣe ẹsin.”

Abala keji ẹsẹ ofin yii tun sọ pe “ko si ẹnikẹni ti eeyan le fi ipa mu lati ṣe nnnkan ẹsin miran, eyii to tako ẹsin tirẹ tabi ẹsin ti awọn obi tabi alagbatọ rẹ fọwọ si.”

BBC Yoruba kan si agbẹrọjo kan to ni imọ nipa ẹtọ ọmọniyan, Olusegun Kofoworola, o ni o lodi si ofin ki eeyan di awọn ẹlẹsin miran lọwọ lati ṣe ẹsin wọn bo ṣe wu wọn.

Ni ti awọn to sọ pe ilu ẹsin Musulumi ni Ilorin, Kofoworola fi kun pe “Ko si ipinlẹ kankan to ni ofin kankan… ofin to lagbara julọ ni Naijiria ni ofin orilẹ-ede Naijiria, nitori naa, ofin kankan, yala ti ijọba ipinlẹ tabi ibilẹ, ko lagbara ju ofin orilẹ-ede Naijiria lọ.”

O pari ọrọ rẹ pe ofin ni ipinlẹ ohun gbogbo, ko si sohun tabi ẹnikẹni to ju ofin lọ.