Kìí ṣe bàbá mi ló sọ mí ní Jackson, bí orúkọ náà ṣe wáyé nìyí – Gómìnà Adeleke

Aworan Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Senator Ademola Adeleke

Odu ni gomina ipinlẹ Osun, Sẹnẹtọ Ademola Adeleke lagbo ijo jijo lorilẹede Naijiria, ki i ṣe aimọ fun oloko.

Gomina Adeleke ki i figba kan fi ẹbun ti Eledua fi jinki rẹ pamọ nibi kibi to ba ti lanfaani lati fidi ra ijo lawujọ.

Koda, ọpọ eeyan ti wọn maa n gbadun ijo rẹ ni wọn sọ ọ ni orukọ inagijẹ ‘’dancing senator’’ eyi to tumọ si sẹnẹtọ onijo.

Wọn yi orukọ naa pada si ‘’dancing governor’’ eyi to tumọ si gomina onijo lẹyin to di gomina ipinlẹ Osun.

Amọ, n jẹ ẹyin mọ idi ti wọn fi n pe gomina Adeleke ni Jackson?

Gomina Adeleke tun pẹrẹ pẹrẹ ọrọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlifisan Arise Tv laipẹ yii nipa bi o ti nifẹẹ si iṣẹ orin kikọ nigba ti o wa ni ọdọ.

‘’Iṣẹ orin kikọ lo yẹ ki n ṣe lati ilẹ wa, amọ, igbe aye wọn to jẹ olorin nigba ti a n dagba nigba ti Naijiria ṣẹṣẹ gba ominira ko wọn ‘yan lori,’’ Adeleke ranti ọjọ.

Ṣugbọn baba rẹ gẹgẹ bi ọpọlọpọ awọn obi nigba naa fẹ ki o gbaju mọ eto ẹkọ rẹ eyi lo si jẹ ki o da omi tutu si lọkan nipa orin kikọ.

Bo tilẹ jẹ pe Adeleke ko mu orin kikọ gẹgẹ bi iṣẹ ojo rẹ, o si fẹran orin kikọ ati ijo jijo di oni.

Bo ya eleyii gan an ni ọmọkunrin rẹ, Adebayo Adeleke jogun ati ọmọ ẹgbọn rẹ, Davido to jẹ ilumọọka olorin bayii.

Ṣe ẹ mọ pe ori loniṣe, ayanmọ o gboogun, Adeleke ba ara rẹ nile ẹkọ fasiti Jacksonville ni Alabama lorilẹede Amẹrika lọdun 1981.

Lasiko ajọdun ile ẹkọ naa ni ọpọ eeyan mọ nipa ẹbun ijo jijo ti Eledua fi jinki Adeleke.

O dije ninu ijo jijo, o si fakọyọ debi wi pe o ni lati figa gbaga pẹlu aarẹ ile ẹkọ naa ni ipele aṣekagba.

Koda, oun ni o gba ipo kinni ninu idije ijo jijo lọjọ naa l’Amẹrika.

Orukọ rẹ, Ademola Adeleke ṣoro fun aarẹ ile ẹkọ naa lati pe.

‘’Lẹyin ti aarẹ ile ẹkọ mi gbiyanju lati pe orukọ mi ti ko ri pe ni o sọ pe Jackson loruko mi yoo maa jẹ.

Bi orukọ naa ṣe mọ mi lara niyẹn o, koda o wa ninu awọn iwe ẹri mi.

Orukọ mẹta ti mo n jẹ ninu iwe irinna mi ni Ademola Jackson Adeleke,’’ Adeleke ṣalaye.

Bayii ni pipe Adeleke ni Jackson ṣe bẹrẹ eyi to jẹ orukọ gbajugbaja olorin takasufee n ni, Michael Jackson.

Lonii, pẹlu idunnu ni gomina Adeleke fi n jẹ orukọ Jackson.

Adeleke ri ijo jijo bi ọna kan gboogi lati ni ibaṣepọ pẹlu ọpọ eeyan.

O ṣeeṣe ki n bẹrẹ orin kikọ ti mo ba ṣe gomina tan – Adeleke

Gomina ipinlẹ Osun ni oun le bẹrẹ iṣẹ orin kikọ lẹyin ti oun be ṣe gomina tan.

‘’Ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ, inu ẹjẹ mi ni orin kikọ ati ijo jijo wa.

Ti ẹnikan ba bẹrẹ si ni kọ orin bayii, mi o mo nkan naa ti o maa gbemi ninu lati bẹrẹ si ni jo.

Ijọ C & S ni mo ti bẹrẹ orin kikọ ati ijo jijo.

Ṣugbọn baba mi ko gba ki n kọrin, ile ẹkọ naa ni ṣa.

Inu mi dun pe ọmọkunrin mi ati ọmọ buọda mi n kọrin.’’

Kii ṣe ijo nikan ni Sẹnẹtọ Adeleke mọọ jo, o n lu ilu, bakan naa ni o tun n kọrin.