Wo àwọn àtúnṣe tí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lù sí ìwé òfin Nàìjíríà

Ahmed Lawan àti Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, others

Láti ọjọ́ pípẹ́ ni àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ń pòùngbẹ àtúnṣe àti àtúnkọ ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí tọdún 1999.

Ilé ìgbòmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní àná, ọjọ́ Ìṣẹ́gun ọjọ́ kìíní, oṣù kẹta, ọdún 2022 dìbò láti fẹnukò láti mú àwọn àtúnṣe kọ̀ọ̀kan bá ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí.

Ṣíṣe àtúnṣe sí ìwé òfin yìí jẹ́ iṣẹ́ kan gbòógì tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ẹlẹ́kẹ̀ẹ̀sán lábẹ́ ìdarí Ahmed Lawan àti Femi Gbajabiamila yoo ṣe.

Àwọn àtúnṣe méjìdínláàdọ́rin ní àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà dìbò lé lórí níbi tí wọ́n ti gba àwọn kan wọlé tí wọ́n sì kọ̀ àwọn kan.

Àwọn aṣòfin kò gba òfin ti yóò fàyè gba àwọn obìnrin láti ní iye kan pàtó nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin wọlé

Àwọn aṣòfin lánàá dìbò tako fífún àwọn obìnrin ní iye àyè kan pàtó láti wà ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ nínú àtúnṣe sí ìwé òfin Nàìjíríà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini o ti selẹ̀ seyin lori eyi?

Ẹ ó rántí pé ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Aya Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Aisha Buhari lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ láti pé fún fífi àyè gba àwọn obìnrin nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ju bó ti wà lọ.

Bákan náà ni Ile igbimo Asofin tún tapa si abajade ti yoo fun awon obinrin ni anfaani lati je Omo ipinle kan naa pelu Oko won.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Leyin ti iyawo are orile ede Naijiria , Aisha Buhari ati iyawo igbakeji aare orile ede Naijiria ,iyaafin Dolapo Osinbajo , ko awon obinrin leyin lo si Ile igbimo.asofin to wa niluu Abuja lasiko ijiroro abadofin ti yoo fun awon obinrin ni anfaani :

-lati ni ida meedogun ninu ogorun un awon to wa ninu egbe oselu.

-lati fun awon obinrin ni aaye Pataki nile igbimo Asofin yala ni ti nílé igbimo aṣofin agba tabi ti ipinle.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Báwo ni àwọn obìnrin ṣe gba èyí?

Ẹ̀wẹ̀, Aya igbákejì Ààrẹ̀, Dolapo Osinbajo tó báwọn péjú sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin lánàá lásìkò tí ètò ìdìbò náà ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn kò ní kó àárẹ̀ ọkàn nídìí jíjà fún fifi àyè gba àwọn obìnrìn nínú òṣèlú síi.

Eyi lo faa ti awon obinrin to wa lorile ede Naijiria se fẹ gunle iwode lo si Ile igbimo Asofin to wa niluu Abuja lati lọfi ehonu won bi Ile igbimo Asofin se faake Kori lati gba awon abadofin naa wole.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àtúnṣe ìwé òfin ti fi àyè gba kí àwọn ìjọba ìbílẹ̀, ẹ̀ka ètò ìdájọ́ àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ máa dá owó na fúnra wọn.

Ọ̀kan pàtàkì lára àtúnṣe tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ṣe sí ìwé òfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni fífún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ 774 tó wà ní orílẹ̀ èdè yìí ní àǹfàní láti wà ní àyè ara wọn láì dúró de ìjọba ìpínlẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n tún dìbò lé lórí rèé:

Ilé ti fi àyè gbà kí ènìyàn dá jáde láti dupò òṣèlú.

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti pín ipò Mínísítà fétò ìdájọ́ àti Agbẹjọ́rò àgbà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Bákan náà ni wọ́n dìbò tako fífún àwọn olórí ilé ní owó ìfẹ̀yìntì láéláé.

Kò sí àyè fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti dìbò ní ilẹ̀ òkèrè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.