Ìpàdé ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ ASUU tún forí sọ́pọ́n

Ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ ASUU ń ṣèpàdé

Oríṣun àwòrán, others

Ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ilẹ̀ Nàìjíríà, ASUU, tún kọ̀ láti forí ìkòkò sọ̀ọ́dún bí ìpàdé wọn í wọ́n ṣe ní ìrọ̀lẹ́ àná ṣe forí sọ́pọ́n.

Ikọ̀ aṣojú ìjọba àpapọ̀ tí Mínísítà fọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́, Chris Ngige darí níbi ìpàdé náà kò ríbi pẹ̀tù sí àwọn olùkọ́ náà láti ṣéwélé ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n gùnlé.

Ngige ní òun ní ìrètí pé ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín àwọn àti ASUU yóò wá sópin láìpẹ́.

Ìpàdé kejì rèé tí ẹgbẹ́ ASUU àti ìjọba àpapọ̀ yóò ṣe láti ìgbà tí ASUU ti bẹ̀rẹ̀ ìyansẹ́lódì oníkìlọ̀ oṣù kan ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì, ọdún 2022.

Àwọn aṣojú ASUU ní àwọn kò ṣetán láti buwọ́lu ìwé àdéhùn kankan pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ mọ́ àfi kí ìjọba ṣ gbogbo ohun tí àwọn ti jọ ṣàdéhùn lé lórí tẹ́lẹ̀.

Ijoba Naijiria ati egbẹ́ awọn Oluko Fasiti yoo se ipade loni lori ọ̀rọ̀ iyanselodi wọ́n

Lónìí, ọjọ́ kìíní, oṣù kẹta, ọdún 2022 ni ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ASUU yóò tún ṣèpàdé láti jíròrò láti wá ojútùú sí ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín àwọn méjéèjì lórí ìyanṣẹ́lódì tí ASUU gùnlé.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ìpàdé tòní ni ó jẹ́ ìtẹ̀síwájú lórí gbogbo àwọn ìfẹnùkò wọn níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́sẹ̀ tó kọjá.

Ààrẹ ẹgbẹ́ ASUU, Ọ̀jọ̀gbọ́n Emmanuel Osodeke ní òun gba ìpè ìjọba àpapọ̀ lánàá láti tún pàdé fún ìjíròrò lónìí.

Osodeke ní òun kò rò wí pé àwọn ń tẹ̀síwájú bó ṣe jẹ́ pé gbogbo ìjíròrò àwọn kò ì tíì so èso rere láti ìgbà tí àwọn ti gùnlé ìyanṣẹ́lódì.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ tí Mínísítà fọ́rọ̀ òṣìṣẹ́, Chris Ngige sọ wí pé ìjọba ò le ṣe ẹ̀kúnwó owó olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ fásitì lásìkò yìí, Osodeke ní ìjọba àpapọ̀ kò ṣe òótọ́ pẹ̀lú àwọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ó ní bí Ààrẹ bá le buwọ́lu ẹ̀kúnwó àwọn ọlọ́pàá àti ti àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama, tí àlékún tún bá owó ìrìnà àwọn ìjọba kò sí ohun tó ní kí ìjọba má lè ṣe àlékún owó oṣù àwọn náà.

Bákan náà ló fi ìkọnilóminú hàn pé ìjọba kò buwọ́lu àbá owó oṣù wọn tuntun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wo iye igba ti ASUU ti da ise sile ni Naijiria:

BBC se akojopo odiwon iye igba ti egbe Oluko Fasiti ASUU ti se iyanselodi pe:

ASUU
ASUU