Wo àwọn ànfàní tó wà nínú èpo ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà

Aworan ogede

Oríṣun àwòrán, Other

Ọpọ eeyan lo fẹran lati maa jẹ ọgẹdẹ agbagba, nigba ti awọn mii fẹràn lati maa fi din dodo.

Amọ, ọpọ ni ko mọ awọn anfani to wa ninu epo ọgẹdẹ agbagba.

Epo ọgẹdẹ kun fun eroja aṣaraloore eyi to n ṣiṣẹ fun ilera ara eeyan.

Wọnyi l’awọn anfani to wa ninu ninu epo ọgẹdẹ.

Epo ọgẹdẹ kun fun eroja to n daabo bo ọkan

Awọn eroja to n daabo bo ọkan bii phenilic ati flavonoid lo wa ninu epo ọgẹdẹ agbagba.

Awọn eroja yii lo maa tun n daabo bo sẹẹli inu ara.

Bakan naa ni wọn maa n gbogun ti awọn ohun to le fa arun ọkan, arun jẹjẹrẹ tabi arun itọ ṣuga.

O maa n jẹ ki ounjẹ tete da ninu eeyan

Awọn eroja faiba to wa ninu epo ọgẹdẹ maa n jẹki ounjẹ tete da ninu eeyan.

Bakan naa ni awọn eroja yii kii jẹ ki inu eeyan kun.

Eroja inu epo ọgẹdẹ kii jẹ ki ara eeyan wu

Epo ọgẹdẹ kun fun eroja to maa n gbogun ti awọn nnkan to le jẹ ki ara eeyan wu.

Eroja aṣaraloore to wa ninu epo ọgẹdẹ maa n daabo bo ikun, o si tun maa n gbogun ti arun to le mu eeyan ni inu.

Ilera awọ ara

Awọn eroja aṣaraloore to wa ninu epo ọgẹdẹ maa n ṣe anfani to pọ fun awọ ara eeyan.

O ni eroja fitami A ati fitami C ninu eyi ti ko ni jẹ ki eeyan tete di ara arugbo.

O maa n daabo ara lọwọ arun

Epo ọgẹdẹ kun fun eroja aṣaraloore ti o maa n gbogun ti aisan ninu ara.

Awọn eroja to wa ninu epo ọgẹdẹ maa n jẹ ki eeyan wa ni ilera pipe.

O maa n jẹ ki ara mọ

Awọn eroja to wa ninu epo ọgẹdẹ agbagba maa n jẹ ki ara mọ.

Awọn eroja aṣaraloore yii si tun maa n daabo bo ẹdọ lọwọ arun.

Lakotan, epo ọgẹdẹ agbagba ni oniruuru eroja aṣaraloore ninu to wulo fun ilera ara.