Ọlọ́pàá ká ọwọ́, ahọ́n àti ìfun èèyàn mọ́ Alfa lọ́wọ́ l’Ondo

NPF

Oríṣun àwòrán, NPF

Alfa kan, Oluwafemi Idris, ti ko si gbaga ọlọpaa ipinlẹ Ondo lẹyin ti wọn ba oniruru ẹya ara eeyan lakata rẹ.

Alukoro ileeṣẹ naa nipnlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan lọjọ Aiku.

Gẹgẹ bii ohun ti alukoro ọlọpaa sọ, awọn tọpinpin afurasi naa lẹyin ti awọn eeyan kan si ileeṣẹ naa pe ọkunrin ọhun n ko ẹya ara eeyan pamọ sinu ile rẹ.

Iroyin ni ṣe ni ọkunrin ọhun fẹ fi ẹya ara eeyan naa joogun.

Atẹjade ọlọpaa sọ pe “Ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹṣẹ, ọwọ si tẹ afurasi naa.

“Nigba ti a wa inu ile rẹ ni Akoko, lara awọn ẹya ara eeyan ti a ba nibẹ ree; ọwọ eeyan, ifun mẹta, ọkan mẹta, ọpa ẹyin ati ahọn.

NPF

Oríṣun àwòrán, NPF

“Afurasi ọhun sọ pe Alfa ẹsin Musulumi ni oun ati pe ọrẹ oun kan to jẹ Alhaji lo ko ẹya naa fun oun.”

Ọlọpaa sọ pe ọkunrin kan ti orukẹ rẹ n jẹ Babatunde Kayode, to jẹ alawo ni afurasi naa gbe ori eeyan mẹta fun.

Odunlami-Omisanya pari atéjade naa pe ọwọ ti tẹ Babatunde Kayode amọ iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mu Alhaji ti afurasi ọhun ni o n ta ẹya ara eeyan fun oun.