Wo Ààrẹ orílẹ̀-èdè tó ń múra láti díje du ipò igbákejì Ààrẹ nínú ìdìbò tó ń bọ̀

Aare Rodrigo

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ Philipines, Rodrigo Duterte ti sọ pe oun ti n mura lati du ipo igbakeji Aarẹ ilẹ naa lọdun 2022.

O ni eredi ipinnu oun ni lati gbogun ti iwa ọdaran atawọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi, ṣugbọn awọn alatako rẹ ti ni ni ọna alumọkọrọyi lo n da lati má ṣe jẹjọ awọn iwa to ti wu sẹyin.

Ọdun 2016 ni Duterte gori alefa, ofin ko si fi aye gba lati dije du ipo Aarẹ lẹẹkan si.

Ni bayii, Aarẹ naa ti wa sọ pe oun yoo dije du ipo igbakeji Aarẹ ninu fọran kan to tẹ awọn akọroyin orilẹ-ede naa lọwọ.

Ninu fọran naa ni Duterte ti sọ ni gbangba pe “Mo ti ṣetan lati dije fun ipo igbakeji Aarẹ ninu eto dibo to n bọ.”

Iroyin ni ẹgbẹ oṣelu rẹ, PDP-Laban ti fontẹ Aarẹ ọhun lati dije fun ipo igbakeji Aarẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Duterte tẹsiwaju ninu fọran naa pe “Mo ti ṣetan lati du ipo igbakeji Aare ki n le tẹsiwaju lati maa gbogun ti egboogi oloro lilo lawujọ wa, ati iwa igbesumọmi.”

“Bo tilẹ jẹ pe mo le má ni agbara bii ti tẹle, ṣugbọn mo maa lẹnu ọrọ lawujọ lati sọrọ tako oniruru iwa ti ko tọ lawujọ wa.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lati igba ti Duterte ti goti alefa lo ti bẹrẹ si n gbogun ti egboogi oloro lilo ni Philipines to bẹ ti awọn ẹgbẹ ajafẹtọ kan fi sọ pe ẹmi nnkan bii ẹgbẹrun mẹwaa eeyan lo ti ba igbiyanju naa lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn agbẹjọro nile ẹjọ to n gbọ ẹsun iwa ọdaran lagbaye, ICC, sọ pe awọn yoo ṣe iwadii awọn ẹsun ipaniyan naa ti wọn fi kan Duterte.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP-Laban ti n mura lati kede ọkan lara awọn alabaṣiṣẹ Duterte, iyẹn Christopher Lawrence “Bong” lati dije fun ipo Aarẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ