Bí Yoruba kò bá yíwà padà, ẹkùn àríwá ní ipò ààrẹ yóò máa lọ – Oluwo

Oluwo tilu Iwo

Oríṣun àwòrán, emperortelu1/Instagram

Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrashed Adewale Akanbi, Telu kinni ti kede pe ẹkun ariwa ni ipo agbara yoo ma duro si ayafi ti iran Yoruba ba yi iwa wọn pada.

Oluwo ni awọn ọba ẹkun ariwa Naijiria lo maa n sin Ọlọrun kan soso, tawọn ọba ilẹ Yoruba si maa n sin orisa.

O wa gba wọn nimọran pe ti ilẹ Yoruba ba fẹ maa wa nipo giga, asiko ti to, ki wọn tun ero wọn pa, ki wọn si pa orisa sinsin ti.

Oluwo gbe imọran yii kalẹ nibi isọji itusilẹ kan to waye nilu naa nibi ti ọba naa ti sọrọ fun awọn olujọsin.

Ọba Akanbi ni gbogbo awọn to n bọ orisa ni yoo maa jo ajorẹyin nigba ti awọn to n sin Ọlọrun Ọba yoo maa lọ siwaju ati siwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O mẹnuba iwe Saamu ori kẹrindinlogun ẹsẹ ikẹrin (psalm 16:4) to si gba awọn ojisẹ Ọlọrun niyanju lati saayan bi iwa ibọrisa yoo se di ọrọ itan.

“Ta ni Sango, Ogun, Ọya, Ogun, Osun atawọn orisa alagbara miran tawọn eeyan nbọ?

Mo fẹ lu gbogbo ẹyin ọba nilẹ Yoruba, awọn pasitọ, wolii ati ẹni ọwọ lọgọ ẹnu, isẹ nla lẹ n se.

Ohun Ọlọrun si ti wa silẹ Yoruba pe ọba ti ko ba kọ orisa silẹ, ko ni nisinmi, gbogbo isoro tẹ si n koju lonii, isẹ ọba awọn ọba alaye ni.

Awọn ọba yii lo n gba abọde orisa sinu aafin wọn, eyi to yẹ ko jẹ ti Oluwa, ki wa ni yoo gbẹyin rẹ, se wọn ko wa ni maa ja bi?

Ki lẹ ro pe yoo jẹ ipa rẹ lori awọn araalu nigba ti ibi asẹ ba ti daru? Ẹyin gan ti wọ wahala nitori naa, ẹ ma ja mi niytan amọ ẹ gba imọran mi.”

Oluwo wa gba awọn olujọsin naa nimọran lati lọ sọ fawọn ọba wọn pe ko gbọdọ si ibọrisa ninu aafin nitori wọn ko le maa sin Ọlọrun ati orisa papọ, ki wọn si ni ki ibukun maa pọ si, rara o.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

“Orisa bibọ ni isoro ilẹ Yoruba, ki agbara si to le wa silẹ Kaarọ Oojire, a gbọdọ dẹkun orisa bibọ.

Agbara wa lẹkun ariwa nitori wọn korira orisa bibọ, ẹ ko si le ri orisa kankan ni sakani wọn.

Orisa bibọ jẹ ajeji nilẹ Yoruba, ko si ni dara fun awọn orisa naa, aye wọn ti bajẹ nitori naa, ẹ ye lọ si ojubọ wọn mọ.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ