Nítòótọ ni àwọn òsìsé ‘Immigration” kán ọrùn àti kókósè mi nígbà tí mo fé gba ìwé ìrìnnà- Emmanuel Omoboriowo

Emma

Iroyin to koko jade sita ni pe awon osise ile ise to n risi wiwole ati jijade awon eniyan ni Naijiria ti a mo si : ‘Immigration service’ ti lu okunrin kan se lese.

Ogbeni Emmanuel Omoboriowo ni aworan re lori ibusun nile iwosan ikoni nise isegun ni Fasiti Afe Babalola ni ipinle Ekiti gba ori ayelujara kan tele.

O ni awon osise to n ri si iwole ati ijade awon eniayn Naijiria ni o fesun kan pe won kolu oun lasiko ti oun wa gba iwe iriina ololufe oun ninu ogba won ni ipinle Ekiti.

Iroyin naa ni awon osise ileese naa fiya je Emmanuel Omoboriowo to je eni odun mejidinlogbon to lo sibe lo gba iwe irinna ololufe re.

O ni won na oun bi eni n lu bara ni leyin ti won ni ki oun ma wo inu ileese naa ki oun si gbe moto oun sita.

O tun so pe nina naa kan eegun kokose oun ati orun oun pelu egungun owo otun oun.

Emma

Sugbon agbenuso ileese to n risi iwole ati ijade awon eeyan ni Naijiria, Ogbeni Daramola Abiodun so pe oro ko ri bee rara.

O ni pe Ogbeni Emmanue wa oko re wo inu ogba ileese naa ni ona to fi fee se awon ero mii lese ni eyi to tapa si ofin ileese naa ni.

Ni eyi ti o si n ba won lo agidi nibe ki oro to ba ibomii yo.

Emma

Ogbeni Abiodun ni ko si osise kankan to kolu ogbeni Omoboriowo rara bikose pe won pase pe ko gbe oko re sita kuro nibe ni ko ma baa se akoba fun awon ero miran to wa ninu ogba ileese naa ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ogbeni Abiodun Daramola ni pe oro naa ti de iwaju awon agbofinro ni ipinle Ekiti bayii.

Sugbon koko ti opo n so lori ayelujara ni pe atunse ye ko ba bi awon osise ileese to n mojuto iwe irinna lilo bibo ni Naijiriia se n se kaakiri agbaye si awon omo Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ