JAMB gbé ‘cut-off mark’ tuntun jáde fún sáà 2022/2023

Awọn akẹkọọ to n ṣe idanwo Jamb

Oríṣun àwòrán, JAMB/FACEBOOK

Ajọ to n ṣe eto idanwo aṣewọle si awọn ile ẹkọ giga ni Naijiria, Joint Admissions and Matriculation Board (JAMB), ti sọ maaki ti akẹkọọ gbọdọ ni lati wọ fasiti di ogoje.

Maaki tuntun ti wọn kede ọhun wa fun igbaniwọle si ile ẹkọ giga ni saa eto ẹkọ 2022/2023/

Nibi eto kan ti ajọ JAMB ṣe lati jiroro lori eto igbani wọle si ile ẹkọ giga, nilu Abuja lọjọ Abamẹta, ni ọga agba ajọ naa, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede, ti kede eyi.

Yatọ si ti maaki igbaniwọle si fasiti, akẹkọọ ti yoo ba wọle si ile ẹkọ gbogboniṣe ‘polytechnics’ ati ile ẹkọ giga fun iṣẹ olukọ, college of Education, gbọdọ ni ọgọrun maaki ninu idanwo JAMB to ba ṣe.

Ọjọgbọn Oloyede ṣalaye pe awọn maaki ti oun kede jẹ maaki to kere ju ti akẹkọọ gbọdọ ni, eyi ti awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga ko gbọdọ gba maaki to kere ju bẹẹ lọ.

Yatọ si ikede maaki tuntun, ọga agba ajọ JAMB tun kilọ pe awọn ile ẹkọ giga ko gbọdọ gba ju ẹgbẹrun meji Naira lati fi ṣe ayẹwo awọn akẹkọọ ti wọn fẹ gba wọle.

“Eyi tumọ si pe ile ẹkọ giga kankan ko gbọdọ jẹ ki awọn akẹkọọ tun ná owo miran lori eto ayẹwo – bi owo ti banki yoo gba lori sisan owo wọle, ati bẹẹbẹẹ lọ.”

Bakan naa ni Ọjọgbọn Oloyede sọ pe ajọ JAMB yoo fun awọn ile ẹkọ giga ni anfaani lọ̀fẹ̀ẹ́, si fọto ati ika ti awọn akẹkọọ tẹ̀ ẹ̀ lori ayelujara rẹ.

O ni eyi yoo din ṣiṣe magomago lori awọn akẹkọọ to joko ṣe idanwo rẹ kù.

O ni ogoje maaki yii ko yọ awọn fasiti aladani silẹ rara, paapaa bi mẹẹdogun lara awọn fasiti naa ṣe ti kọkọ beere fun maaki ọgọfa si aadoje.