‘Ìnira ni ìjọba máa kó bá aráàlú tí wọ́n bá fowó kún owọ iná’

Iná

Oríṣun àwòrán, Others

  • Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
  • Role, Broadcast Journalist

Bí awuyewuye ṣe gba ìgbòro wí pé ìjọba àpapọ̀ ń gbèrò láti fi ìdá ogójì kún owó iná mọ̀nàmọ́ná ni àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ń fa ìjọba létí láti má ṣe gbé ìgbésẹ̀ náà.

Ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ ni pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣì ń bá ìnira tí ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiróòlù ń mú bá wọn fínra lọ́wọ́ nítorí náà ti owó epo kò gbọdọ̀ kún-un.

Onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé kan, Bisi Iyaniwura nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá ṣàlàyé àwọn nǹkan tó ṣeéṣe kí àwọn ènìyàn orílẹ̀ yìí kojú bí ìjọba bá filè gbé ìgbésẹ̀ náà láti mú àlékún bá owó iná ọba.

Iyaniwura ní àwọn ènìyàn ṣì ń bá àlékún tó bá owó epo bẹntiróòlù fínra nítorí náà kò yẹ kí ìjọba fi ààyè gba kí owó epo gbówó lórí rárá.

Ó ní lára àwọn nǹkan tí wọ́n máa fi ń mọ orílẹ̀ èdè tó ń ní ìdàgbàsókè ni tó bá jẹ́ wí pé owó tí àwọn ènìyàn ń ná jáde pọ̀ ju owó tó ń wọlé fún wọn lọ.

Ó ṣàlàyé pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń ná ju iye tó ń wọlé fún-un lọ.

Àìníṣẹ́ tún máa lékún bí owó iná mọ̀nàmọ́ná bá tún gbẹ́nu sókè

Iyaniwura ṣàlàyé iná ọba tí kò dúró ire tẹ́lẹ̀ wà lára ohun tó ṣokùnfà àìníṣẹ́ àwọn ọ̀dọ́, tí owó iná bá tún wá lékún iye tó wà tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló tún máa gba iṣẹ́ lọ́wọ́ wọn.

Ó ní àwọn tó jẹ́ olókoòwò kéékèèké ni ọ̀wọ́n gógó iná ọba yìí máa ẹ àkóbá fún nítorí ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ wí pé iná mọ̀nàmọ́ná ni wọ́n ń lò láti fi wá oúnjẹ oòjọ́ wọn.

“Àwọn ènìyàn ń sọ wí pé kò sí owó lápò, kò sí owó nílé, níbo lẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn rí owó san tí wọ́n bá fi owó kún owó iná?”

“Àwọn tó jẹ́ oníṣẹ́ kéréje kéréje, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ oge, àwọn télọ̀, àwọn wẹ́dà, tó jẹ́ díẹ̀ díẹ̀ iná tó wà, wọ́n ń mánéèjì rẹ̀ ni, tí wọ́n bá fi owó kún owó iná, wọ́n fẹ́ lé wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ nìyẹn.”

Iyaniwura tẹ̀síwájú pé iná tí ìjọba ń pèsè kò tó nǹkankan tẹ́lẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ ilé ni kò ní mítà tó ń ka iye iná tí wọ́n bá lò, àwọn ilé iṣẹ́ tó ń pín iná kàn máa ń mú nǹkan tó bá wù wọ́n lọ fún wọn ní ìparí oṣù ni.

“Àwọn tó ní mítà, nǹkan tí wọ́n bá lò ló máa kà fún wọn àmọ́ àwọn tí kò ní mítà, ìyà tún fẹ́ kún ìyà fún wọn ni àlékún owó yìí máa jẹ́.”

“Kí ìjọba rò ó dáadáa nítorí ti owó epo tí wọ́n ṣì dá sílẹ̀, ara ń ni àwọn ará ìlú, wọ́n ń làágùn, ẹ tún wá ní ẹ fẹ́ fi owó kún owó iná.”

“Owó dọ́là ti kọ́kọ́ gbẹ́nu sókè tó dẹ̀ jẹ́ wí pé ìdá mẹ́ta nǹkan tí à ń lò ní Nàìjíríà wọ́n ń ko wá láti òkè òkun ni.”

“Owó epo lọ sókè, owó ọjà wọ́n, ṣé wàhálà kọ́ ni ìjọba ń wá fún àwọn ènìyàn báyìí?”

Owó iná nìkan ni àwọn òṣìṣẹ́ tó ń gba ₦30,000 gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jìlọ máa fi san

Aworan mita ina mọnamọna kan

Oríṣun àwòrán, others

Iyaniwura wòye pé tí àlékún bá fi lè bá owó iná mọ̀nàmọ́ná, ó túmọ̀ sí pé àwọn òṣìṣẹ́ tó ń gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náírà gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ máa fi owó oṣù wọn san.

Ó ní tí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò ₦30,000 àsìkò yìí, níṣe ló dàbí ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùn-ún náírà tẹ́lẹ̀ àti pé ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ni kò san ₦30,000 fún àwọn òṣìṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó tó kéré jùlọ.

“Owó ilé gbẹnú sókè, owó ọkọ̀ lọ sókè, níbo ni ₦30,000 fẹ́ gbé ènìyàn dé?

Ó fi kun pé owó tí kò tó ná ló ń ṣe okùnfa bí ìwà àjẹbánu ṣe gbilẹ̀ ní Nàìjíríà nítorí ọ̀pọ̀ ló fẹ́ tẹ́gbẹ́ tí wọ́n sì fẹ́ mọ́wọ́ dé ẹnu.

Ó wà rọ ìjọba láti ṣe àmójútó àwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n ta àwọn iná yìí fún bó ṣe yẹ kí ọ̀wọ́n gógó yìí le má ṣe kẹ́sẹ járí.

Bákan náà ló rọ àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè iná láti wá àwọn ọ̀nà mìíràn tí wọn yóò máa fi pèsè iná dípò tí wọ́n fi ń gbára lé epo bẹntiróòlù.

Ẹ ò gbọdọ̀ mú àlékún bá owó iná mọ̀nàmọ́ná – NLC jáwé ìkìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀

NLC

Oríṣun àwòrán, COLLAGE

Lẹ́nu ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn ni ẹnu ń kun iléeṣẹ́ tó ń pín iná ọba wí pé wọ́n ń gbèrò láti mú alékún bá iye tí àwọn ènìyàn ń san lówó iná.

Ìròyìn tó gbòde ni pé àlékún ìdá ogójì ni àwọn iléeṣẹ́ náà ń gbèrò káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè yìí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ iná ọba pínpín kò ì tíì sọ wí pé bóyá lóòtọ́ tàbí irọ́ ni wí pé àwọn fẹ́ fi owó kún owó iná, ètò tó wà nílẹ̀ ni pé oṣù mẹ́fà mẹ́fà ni wọn yóò máa ṣe àgbéyẹ̀wò iye tí àwọn ènìyàn ń san lówó iná.

Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kìíní, oṣù Keje ọdún 2023, NERC yóò tún ṣe àgbéyẹ̀wó iye tí àwọn ènìyàn ń san tẹ́lẹ̀ tí wọ́n yóò sì tún gbé owó tuntun mìíràn jáde.

Èyí sì ti ń mú kí àwọn ènìyàn ti máa rò ó wí pé ó ṣeéṣe kí wọ́n fẹ́ mú àlékún bá owó iná yìí.

Ki ni ẹgbẹ oṣiṣẹ n ja fun gan?

Ẹ̀wẹ̀, Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NLC ti ṣèkìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ láti má tẹ̀síwájú lórí èròńgbà wọn láti mú àlékún bá owó tí àwọn ènìyàn ń san lówó iná.

Ààrẹ NLC, Joe Ajaero nínú àtẹ̀jáde kan lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kẹfà ọdún 2023 ní bí ìjọba ṣe ń gbèrò láti mú àlékún bá owó iná pẹ̀lú ìdá ogójì bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kìíní, oṣù Keje jẹ́ ohun tó burú jáì.

Ajaero ní pẹ̀lú èròńgbà yìí, ó jọ́ wí pé ìjọba kàn mọ̀-ọ́n-mọ̀ dijú sí gbogbo ìṣòro tí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí ń là kọjá pàápàá àwọn mẹ̀kúnnù lórí ọ̀rọ̀ owó iná.

Ó ní àlàyé tí wọ́n ṣe láti mú àlékún bá owó iná náà kò ṣẹ̀yìn àlékún tó ti bá owó epo bẹntiróòlù àti pé gbogbo nǹkan ti gbówó lórí.

“Ìwádìí fi hàn pé ọ̀wọ́n gógó gbogbo nǹkan ti fò láti ìdá mẹ́rìndínlógún tí àlékún sì tún bá náírà sí iye dọ́là.”

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀wọ́n gógó yìí wáyé kò ní kí owó iná tún lékún pẹ̀lú ìdá ogójì yìí pé ó ti pọ̀ ju bí ó ṣe yẹ lọ.

Ajaero fi kun pé ó yẹ kí ìjọba wo bí wọ́n ṣe ń fún àwọn ènìyǹ àti iye tó ń wọ àpò àwọn òṣìṣẹ́ kí wọ́n tó gbìyànjú láti mú alékún bá owó iná.

Bákan náà ló wòye pé iná tí àwọn ẹ̀ka tó ń mójútó iná ọba ń pèsè kò tó àwọn ọmọ Nàìjíríà lò rárá, tí àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná ọba kàn ń mú àlékún bá owó iná bó ṣe wù wọ́n.

“Pẹ̀lú gbogbo àtìlẹyìn tí wọ́n ń ṣe fún ẹ̀ka tó ń pèsè iná, wọn ò tíì pèsè iná mẹ́gáàtì ẹgbẹ̀rún márùn-ún, síbẹ̀ owó gegege ni àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná ń gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn.”

“Ohun tó tún burú níbẹ̀ ni pé kò sí àmójútó fún àwọn iléeṣẹ́ yìí, ó tún lè di inú oṣù Kẹjọ kí wọ́n tún mú àlékún bá owó yìí, èyí tó ń ṣe àkóbá fún àwọn mẹ̀kúnnù.”

Ajaero tún tẹ̀síwájú pé pẹ̀lú àlékún tó bá owó ilé ẹ̀kọ́ àti ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ, tí wọ́n bá tún fi àlékún sí owó iná, ó ṣeéṣe kí Nàìjíríà má ṣe é gbé mọ́ fún àwọn mẹ̀kúnnù.

Ó ní pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan yìí, òun rọ ìjọba láti gbégi dínà fífi owó kún owó iná ọba kí ayé le rọrùn fún tolórí tẹlẹ́mù.