Peter Obi bu ẹnu atẹ́ lú Tinubu lórí ọgọ̀ọ̀rọ̀ ọkọ̀ tó tẹ̀le lásíkò tó sàbẹ̀wò sí ìlú Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ osẹlu Labour Party, Peter Obi ti bu ẹnu atẹ lu oludije sipo Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lori ọgọọrọ awọn eniyan to tẹle lasiko to ṣabẹwo si ipinlẹ Eko.

Iroyin ni o kere tan awọn ọkọ to le ni ọgọrun lo tẹle Tinubu ninu fido to ja ranyin lori ẹrọ ayelujara lasiko to n lọ si ile rẹ ni Ikoyi lẹyin to kuro ni papakọ ofurufu.

Tinubu lo de si ilu Eko lati ilu Ọba nibi to ti lọ dapọ mọ awọn adari lagbaye lati buwọlu awọn eto idokowo fun Naijiria.

Lẹyin naa ni Tinubu wa si ilu Eko lati ṣe ọdun Sallah, ti ọgọgọrun awọn Musulumi miran si tẹlẹ lati lọ ṣe adura Eid ni agbegbe Obalende ni ipinlẹ Eko.

Ohun ti Peter Obi sọ ree…

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ninu ọrọ rẹ, Obi ni awọn adari lorilẹede Naijiria gbọdọ mọ lati ba dari awọn eniyan ni ọna to dara gẹgẹ bi awokọṣe.

O ni kodara to ki aarẹ naa maa gun ọkọ bọgini bọgini ki awọn ọgọọrọ ọkọ maa tẹle lasiko ti iya n ba awọn araalu finra..

O ni bio tilẹ jẹpe oun ko ri ọkọ naa tabi fidio naa ti wọn fi si ori ẹrọ ayeluja oun ti oun yoo sọ ni pe aarẹ gbọdọ mọ oun ti awọn ara ilu la kọja, ki o si jẹ apẹrẹ rere si awọn araalu.

‘’O kole sọ fun awọn eniyan ki wọn fi ara da iṣoro lasiko yii lai fi ara da nkankan fun ara rẹ gẹgẹ bi adari.’’

‘’Fifi ara da iṣoro gbọdọ bẹrẹ lati ọdọ awọn adari, ninu awọn lo n ṣaaju ti awọn araalu si n tẹle wọn.’’

Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu ọgọọrọ ọkọ to tẹle aarẹ Tinubu naa.