Bí a sé pa ọmọogun kan ní Ondo rèé – Àwọn afurasí

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn afurasi mẹta ti wọn fi ẹsun kan pe wọn pa ọmọogun oju omi kan, Samuel Akingbohun ti sọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.

Awọn afurasi yii sọrọ lasiko ti ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo fi wọn lede ni ilu Akure.

Lasiko naa ni awọn afurasi naa sọ bi awọn ṣe kopa ninu iṣekupani naa.

Akingbohun ni wọn fi ẹsun kan pe wọn pa lasiko ti ariyanjiyan bẹ silẹ laarin oloogbe naa ati ọlọkada ni agbegbe Idoani, ni ijọba ibilẹ Oṣẹ ni ipinlẹ Ondo.

Lẹyin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fi panpẹ mu wọn.

Awọn afurasi naa ni wọn ṣapejuwe pe wọn ṣeṣẹ kẹkọ jade girama ti wọn ko si ju ẹni ogun ọdun lọ.

Lasiko ti wọn n ṣafihan wọn ni wọn ni irin gbọọrọ ni awọn fi pa ọmọogun naa ti oun ṣiṣẹ ni ileẹkọ Navy Secondary School, Imeri, ti ko jina si Ido Ani.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye…

Aworan ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkan ninu awọn afurasi naa ni ọmọogun naa lo kọkọ gba ọrẹ oun loju ni asiko ti wọn n kọja lọ ni ọna ti ko dara, ti ọkada wọn si n sọra fun koto to wa nibẹ.

Lasiko yii ni wọn ni ọkan lara awọn afurasi naa fi ọwọ gba ọmọogun, eleyii to mu ki o gba oju rẹ, to si tun fi ori gba ni iwaju ori.

Lẹyin naa ni wọn ni ọkan lara wọn sọ wi pe kii se ọmọogun ni tootọ, ti wọn si bẹrẹ si ni tẹle de oju ọna ti ko si awọn ẹlomiran ti wọn si la irin mọ ni ori ati nkan ọmọ ọkunrin rẹ.

Awọn afurasi naa ni awọn fẹ lọ gba ẹrọ ‘’power bank’’ ti wọn fẹ fi gbana si ara foonu wọn ni iṣẹlẹ naa waye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa nitori awọn kan ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa ti salọ, amọ ọwọ yoo tẹ wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni lẹyin naa ni awọn yoo gbe wọn lọ si ileẹjọ lori ẹsun iṣekupani naa.