Bí àwọn olùrànlọ́wọ́ ṣe gé ẹsẹ̀ obìnrin tó há sínú ẹ̀rọ agbénifò ní pápákọ̀ òfurufú

Papakọ Ofurufu

Oríṣun àwòrán, DON MUEANG INTERNATIONAL AIRPORT

  • Author, By Kelly Ng, Joel Guinto & Thanyarat Doksone
  • Role, From Singapore and Bangkok

Awọn aranilọwọ ti ge ẹsẹ arabinrin kan ti wọn n gbiyanju lati ranlọwọ yọ ẹsẹ rẹ to ha sinu ẹrọ kan to n rin ni papakọ ofurufu.

Ọmọ rẹ sọ pe o ba awọn ẹbi rẹ lojiji ti ipo ironu inu ọpọlọ rẹ si n kọ awọn lominu lẹyin ti wọn ṣe iṣẹ abẹ fun un tan ni Ọjọbọ ọsẹ.

Iṣẹlẹ manigbagbe naa waye ni papakọ ofurufu Don Mueang ni Bangkok.

Awọn oniroyin abẹle jabọ pe ẹsẹ obinrin ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin ọhun dede ha ni owurọ Ọjọbọ lẹyin ti apoti ẹru to gbe dani yọ ọ ṣubu nigba to fẹ lọ wọ inu ọkọ baalu.

“Ipo ọkan ati iṣesi mama mi n kọ wa lominu,” ọmọ rẹ ọkunrin kọ eyi soju opo Facebook rẹ.

“A baa sọrọ fun akoko ranpẹ ṣaaju ati lẹyin iṣẹ abẹ naa… Bo tilẹ jẹ pe o fi agbara han nipasẹ iwo oju ati ohun rẹ, awa mọ pe denu denu, ọkan rẹ bajẹ tori o dede padanu ẹsẹ naa ni,” Kit Kittirattana fi kun un.

“Ẹbi wa mọ daradara pe a ko ni le mu ki ẹsẹ rẹ rin pada bii ti tẹlẹ mọ, ti kii sii ṣe pe a le mu iru igbe aye to ti gbe tẹlẹ pada wa,” o kọ eyi kun ọrọ rẹ.

Awọn aworan to wa lori ayelujara ṣafihan arabinrin naa ti wọn ko tii fi orukọ rẹ han – ti o joko pẹlu ẹsẹ rẹ to ha si abẹ ẹrọ agbenifo ti wọn n pe ni travelator.

Apoti ẹru alawọ “pink” kan to wa lẹgbẹ rẹ ti padanu ẹsẹ meji bẹẹ si ni nnkan bii alawọ pupa rẹsu rẹsu to maa n wa lara ẹrọ travelator naa ti kan danu.

Awọn alaṣẹ papakọ ofurufu naa sọ pe iṣẹlẹ ọhun ba awọn lọkan jẹ gidi, ati pe awọn yoo fun obinrin naa ni nnkan gba ma binu fun adanu ẹsẹ osi rẹ bẹẹ si ni awọn yoo tun gbe sisan owo itọju ilera rẹ.

Adari kan ni papakọ ofurufu naa, Karant Thanakulijeerapat sọ fun awọn oniroyin l’Ọjọbọ pe ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa ṣi wa labẹ iwadii.

O fi kun un pe papakọ ofurufu naa ti n ṣeto lati ṣe ayipada ọpọlọpọ ẹrọ agbenigoke to ti gbo ni ọdun 2025 ṣugbọn wọn wa lee jẹ ki amuṣẹ rẹ ya bayii.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe ẹrọ agbenigoke to ṣe ijamba yii ti n ṣiṣẹ lati ọdun 1996.