PDP Oyo sọ̀rọ̀ lórí pé Seyi Makinde ń lọ sẹ́gbẹ́ APC

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/ Facebook

Ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Oyo ti ke s’awọn ọmọ Naijiria, lati fi ẹyinkule ọwọ da gbogbo ọrọ ti Fẹmi Fani-Kayọde ba sọ nu nitori atimaasebo rẹ ti fihan pe, ko duro soju kan ri, bẹẹ ni asọrọ ana di bamii ẹda ni.

Bẹẹ ba gbagbe, Minisita ana feto irina ofurufu, Femi Fani-Kayọde lo ni oun lo ṣokunfa bi awọn gomina kan ṣe dara pọ mọ ẹgbẹ oselu APC ati pe laipẹ Gomina Makinde tipinlẹ Ọyọ naa pẹlu yoo fo fẹrẹ lọ si APC.

Fani-Kayode sisọ loju ọrọ yii lasiko to n salaye idi to se kuro ninu ẹgbẹ PDP, rekọja lọ si APC laipẹ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti Fani-Kayode sọ yii, ẹgbẹ PDP ni lọwọ yii, awọn to n ko ba igbaye-gbadun araalu ni wọn n korajọ si ẹgbẹ oṣelu APC, nitorina ajegbodo to n wẹni kunra lọrọ Fani-Kayọde.

Akọwe ipolongo f’ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Hakeem Ọlatunji woye pe niwọn igba ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ko ti lee kuro lẹgbẹ oṣelu APC, ko si ohun ti yoo yẹju Makinde pẹlu kuro lẹgbẹ oṣelu PDP.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

A ko fẹ Seyi Makinde ninu APC Oyo, yoo ba ọja j fun wa ni – Abass Aleshinloye

Bakan naa ninu ọrọ tirẹ, ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọyọ ni bi ẹlẹṣẹ to n lọ ṣọọsi tabi mọṣalaṣi fun irapada ọkan rẹ lọrọ Gomina Makinde yoo ri bo ba fẹ wa si ẹgbẹ oṣelu APC.

Ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ ọyọ, Ọgbẹni Ayọdeji Alẹshinlọyẹ ṣalaye fun BBC News Yoruba pe iru wọn, a kii fa akoso ṣọọṣi tabi mọṣalaṣi ke wọn lọwọ.

O fi kun un pe gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde yoo kan wa ba ọja jẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọyọ ni.

Ẹgbẹ oṣelu APC ni bi gomina Makinde ba ti le fi ọwọ sibi tọwọ gbe to si ṣetan lati tẹle ilana ofin ẹgbẹ oṣelu APC mu.

“Bo ba wa, a jẹ pe o ti di atunbi ni, ṣugbọn a ko ro pe yoo lee wa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.”

Ọgbẹni Ayọdeji Alẹshinlọyẹ to jẹ alaga ajọ awọn alaga kansu, ALGON tẹlẹ ni ipinlẹ Ọyọ ni ko saye fun un lati dije fun ipo gomina lẹgbẹ oselu APC bi o ba jẹ pe nitori atidije lo tori fẹ wa si ẹgbẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ