Ìdí rèé lórí bí mo ṣe di oníyàwó márùn-ún, ẹjọ́ mi kọ́ – Ọkọ Lizzy Anjorin

Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin Lizzy Anjorin, Alhaji Abdullateef Lawal Adegboyega ti salaye idi to se ni iyawo mẹrin saaju ko to fẹ Lizzy Anjorin.

Alhaji Lawal, ninu fidio kan to gba ori ayeluyara kan, wa sekilọ fun awọn iyawo rẹ mẹrin to ku lati ṣọ ara wọn lori ọrọ Lizzy Anjorin.

Adegboyega fi ikilọ naa lede lasiko to n sọrọ lori ayelujara nipa ija ati awuyewuye to n waye laarin awọn iyawo akọfẹ rẹ ati Lizzy Anjorin.

Ọkan lara awọn iyawo mẹrin naa, Fola, lo kọkọ lọ si ori ẹrọ ayelujara pe Adegboyega ko tọju oun ati awọn ọmọ ohun.

Amọ Adegboyega fi aridaju lede pe irọ patapata ni ati owo to fi sọ wọ si Fola, to fi mọ owo ile to n gbe.

Bi mo ṣe di oniyawo mẹrin re e:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ramota, iya Ayomide ni iyawo akọkọ mi:

Abdulateef Lawal Adegboyega ni Ramota, tii se Iya Ayomide ni oun kọkọ fẹ ni aarọ ọjọ oun amọ awọn dijọ gbe papọ fun igba diẹ.

O ni nigba ti ọrọ awọn ko fẹ ye ara awọn, ni awọn yago fun ara awọn, ko maa ba di pe awọn lu ara awọn pa sinu ile.

O ni lati igba ti awọn ti fi ara awọn silẹ, oun n tọju rẹ, ti oun si n se awọn ẹtọ ti o yẹ ki oun se, koda akọbi rẹ gan ti wa nile ẹkọ giga bayii.

Iyawo mi keji jẹ́ alalubarika:

“Mo dupẹ lori iyawo mi keji, mo si gbadura fun pe Ọlọrun yoo ba mi saanu rẹ ni gbogbo ibi to wa, ti yoo si gbe alaanu dide fun.

Mo ri pe obinrin alalubarika to fẹ jere ọmọ dọjọ alẹ ni, ti n ko si fẹ sọrọ ju bayii lọ lori ọrọ iyawo mi keji yii.”

ko mọ ju ko lọ si ibi ayẹyẹ ni ọṣọọṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Monsurat, iya Amuda ni iyawo mi kẹta amọ ale yiyan pọ fun:

Alhaji Lawal ni Monsura ni iyawo oun kẹta, ti oun si fẹ nilana ẹsin Islam amọ oun se iyawo alarede pẹlu rẹ amọ o ni o n hu awọn iwa kan ni oun se pa ti.

O salaye pe igba mẹta ọtọọtọ ni oun ti ka ọkunrin mọ ọdọ rẹ. Akọkọ ni igba ti oun rinrin ajo amọ ti oun de lẹyin ọjọ kẹfa, ti oun si ba ọkunrin ninu yara pẹlu rẹ.

“Mo ba Alfa lọdọ rẹ to wọ asọ mi sọrun, ti iyawo mi si ni o wa se alua pẹlu oun ni lati ọjọ mẹfa sẹyin, mo yari amọ wọn bẹ mi, ti mo si gba.

Ko tun pẹ mo tun ka ni igba keji pẹluọ́kunrin apọn kan to n gbe oke ile wa, ti wọn jọ joko sinu yara wa, ti iywao mi si wọ asọ oorun to fi ihooho ara rẹ silẹ, wọn bẹ mi, mo tun gbọ.

Ni igba kẹta, mo tun ka iyawo mi pẹlu ale, ọkunrin yii, mo mọ daadaa, ti iyawo mi si maa n ran mi si pe awọn dijọ n dajọ papọ ni, ase ale rẹ ni.

Wahala Monsura ni Alhaji Lawal sọ pe o ti oun sita, ti obinrin naa si tun maa n ya asọ mọ oun lọrun tawn ba ti n ja.

Iyawo lọ pe ọlọ pa si mi, mo ni maa fi ile silẹ fun, ko kan jẹ ki n ko asọ mi, mo si lọ n ya ile gbe lọdọ ọrẹ mi kan, ibẹ si ni mo ti pade Fola.

Lọwọ bayii, Monsura ti wa nile ọkọ miran, to si tun wa n pada maa da ile ru pẹlu Lizzy, irọ si lo n pa pe oun mọ Lizzy ri.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Fola ni iyawo mi kẹrin, amọ kii se ẹni ti eeyan n ba to:

Alhaji Lawal ni Fola, tii se iyawo kẹrin ni akọkọ, o si yẹ ki araye bi leere pe ki lo pa ọkọ rẹ akọkọ ati idi ti awn ẹbi ọkọ naa ko se fẹ ri loju.

Fola yii kii se ẹni ti eeyan n ba to rara, amọ asiko ti wahala wa laarin emi ati Monsura ni mo pade Fola yii, ta si n fẹ ara wa.

“Fola ko sọ fun mi nibẹrẹ pe oun ti bimọ ri, ẹnu awọn ọrẹ mi ni mo ti gbọ pe o ti bimọ meji, ti oun naa si sọ pe lootọ ni nigba ti mo bi i.

O salaye gbogbo itan aye rẹ fun mi, ipo tawọn obi rẹ wa ati oun gan, ti wọn n lo yara kan soso ni Agege amọ ẹsẹ rẹ kii duro soju kan.

Nigba to ya lo ni oun ti loyun fun mi, ara fu mi pe kii se emi ni mo ni oyun amọ mo ni to ba bimọ, a se ayẹwo DNA lati mọ baba to ni ọmọ, ti mo si gba ile fun si adugbo Fagba.”

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lawal ni oun ba Fola gbe pọ fun osu kan amọ oun ko le ba gbe papọ ni oun se lọ gba ile si Ikorodu.

O ni Fola yii ko mọ̀ ju ariya ọsọọsẹ lọ, ko m isẹ se, to si maa n fi owo ile ẹkọ ọmọ ra asọ ariya.

”Mi o ṣe iyawo pẹlu Fola nitori gbogbo awọn ọmọ to wa ni ọwọ rẹ mẹtẹẹta, o da mi loju pe ẹmi kọ ni mo ni awọn ọmọ naa.

Lẹyin naa ni mo sọ wi pe ka lọ ṣe ayẹwọ ẹjẹ boya emi ni mo ni awọn ọmọ naa, amọ Fola kọ pe ka ṣe DNA.

Nigba to ya lo ni oun ni oyun keji fun mi, ti mo si yari pe oyun naa kii se temi, ti ọmọ mi si sọ fun mi pe ọrẹ mi maa n wa sun ti Fola mọju.”

”Irọ ni gbogbo ohun ti awọn iyawo mi n sọ fun awọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ ayelujara pe Lizzy gba ọkọ awọn”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Oni inu ire ni Lizzy Anjorin, mo bẹbẹ ki n to fẹ ẹ ni

Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin Lizzy Anjorin, Abdullateef Lawal Adegboyega ni Lizzy Anjọrin nikan ni oun ṣe iyawo oloruka pẹlu, amọ oun ṣe Nikkah pẹlu iyawo oun meji, Iya Ayomide ati Monsuratu.

Ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin Lizzy Anjorin, Abdullateef Lawal Adegboyega ti ni irọ ni pe Lizzy Anjọrin gba ọkọ awọn iyawo oun mẹta to ba nilẹ.

Abdullateef Lawal Adegboyega ni oun ti wa lai si iyawo ni ile fun ọdun meji ko to di pe oun fẹ Lizzy Anjorin.

Bakan naa lo sapejuwe Anjorin gẹgẹ bi obinrin oni inu ire to fẹran awọn eniyan amọ ko gba ibajẹ eniyan.

O rọ awọn ọmọ Naijiria lati ma a ṣe iwadii awọn iroyin ti wọn ba n ri lori ẹrọ ayelujara nitori awọn eniyan kan fẹ ba oun lorukọ jẹ ni.

Adegboyega wa kilọ fun awọn iyawo mẹta to ku wi pe ti wọn ko ba ṣọra wọn, wọn yoo rugi oyin lori ọrọ kubakugbe ti wọn n sọ kaakiri nipa Lizzy Anjorin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ