Sanwo-Olu buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro l’Eko

Gomina Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @jimidisu

Gomina ipinlẹ Eko Babajide Sanwoolu ti buwọlu ofin to de fifi ran jẹ laarin igboro ni ipinlẹ Eko.

Ohun ti eyi tunmọ si ni pe ẹnikẹni ti o ba da ẹran jẹ laarin ilu ni itako ofin yoo foju wina ofin.

Gomina buwọlu ofin yi ni ọjọ Aje lẹyin tawọn ọmọ ile aṣofin ipinlẹ naa fi ontẹ jan lẹyin ijiroro ni nkan bi ọsẹ kan sẹyin.

Awuyewuye ofin to de fifi ẹran jẹko ati eleyi to ni ṣe pẹlu owo ori VAT jẹ eleyi tawọn aṣofin ipinl Eko jiroro le lori laipẹ yi.

Bi a ko ba gbagbe Olori ile naa, Mudashiru Obasa dari akọwe ile, Lekan Onafeko lati fi ẹda iwe ofin VAT naa sọwọ si Gomina Babajide Sanwo-Olu fun ontẹ.

Ile igbimọ aṣofin ọhun tun buwọlu ofin to tako fifi ẹran jẹko laarin ilu nipinlẹ Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn ofin mejeji naa gba ontẹ lasiko ti awọn aṣofin ile ofọwọ si nibi ijoko wọn lẹyin ti wọn ti ka fun igba kẹta.

Ni kete ti wọn buwọlu ofin naa tan, Olori ile ọhun kan sara si awọn ọmọ ile fun akitiyan wọn lati ri pe ipinlẹ Eko ko rẹyin laarin awọn akẹgbẹ rẹ.

Ipìnlẹ Eko naa ti darapọ mọ awọn ipinlẹ mii bi Ondo to ti buwọlu ofin to tako fifi ẹran jẹ laarin ilu ni Naijiria.