PDP àti APC kọlu ara wọn l‘Eko àti Osun, ọ̀pọ̀ èèyàn fara pa

Aworan

Oríṣun àwòrán, @Jandor/ Amidu Tadese

Oludije sipo gomina nipinlẹ Eko, AbdulAzeez Adediran ti bu ẹnu atẹlu bi awọn janduku kan ṣe kọlu ọkọ ipolongo ibo rẹ, ti eeyan meje si farapa.

Adediran sọ eleyi nigba to n ṣe ipade pọ pẹlu igbimọ awọn lemamu ni agbegbe Ketu nijọba ibilẹ Kosofe nipinlẹ Eko lasiko ipolongo ibo rẹ.

O ni lowurọ ọjọ kẹrinlelogun ọsu kini, awọn janduku kan ṣekọlu si ọkọ ipolongo ibo rẹ, ti wọn si gun ọkan lara awọn osisẹ abo rẹ lọbẹ.

Bakan naa lo ni ikọlu naa ti bẹrẹ lati igba ti oun ti bẹrẹ ipolongo ibo lọdun to kọja ni awọn janduku kaakiri awọn ijọba ibilẹ ti n ṣekọlu si ẹgbẹ oṣelu PDP.

“Ọpọ awọn alatilẹyin mi pẹlu awọn akọrinyin lo farapa.”

Adediran ni gbogbo awọn ikọlu to n waye lo jẹ ẹdun ọkan sugbọn oun ko ti ṣetan juwọ lẹ, ti oun o si ro pe oun yoo juwọ fun awọn ẹgbẹ alatako nipinlẹ Eko.

O ni erongba oun ni lati mu idẹrun de awọn eeyan ipinlẹ Eko.

“Ni ṣe ni awọn janduku le Funke Akindele kuro ninu Ọja Kosofo”

Oludije sipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu PDP tẹsiwaju pe ko ki n ṣe oun nikan ni ikọlu ṣe akoba fun, o ni se ni awọn janduku kan yawọ ọga ti igbakeji ati gbajugbja oṣere tiata, Funke Akindele ti ba awọn ara ọja sọrọ, ti wọn si le kuro ninu Kosofo.

Adediran ni o ṣeni laanu bi ọrọ oṣelu ṣe n lọ nipinlẹ Eko sugbọn oun ṣetan lati mu idẹrun ba awọn olu gbe ipinlẹ Eko.

Nipinlẹ Osun, awọn janduku ṣekolu si Oludije sipo Sẹnẹtọ, ba ọpọ dukia jẹ

Aworan

Oríṣun àwòrán, Amidu Tadese

Ẹwẹ nipinlẹ Osun, Oludije sipo Sẹnẹtọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Amidu Tadese ni awọ janduku kan kọlu,ti ọpọ si farapa yanayan pẹlu ọpọ dukia ti wọn ba jẹ.

Isẹlẹ naa waye lọjọ Isẹgun, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni ọdun 2023, ni wọọdu kẹwa nijọba ibilẹ Irewole, niluu Ikire nipinlẹ Osun

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, Dokita Amidu Tadese ni awọn janduku naa to ọgbọn niye, ti wọn lo kiri ni agbegbe naa lati ṣe awọn eeyan ni ijamba lẹyin ti wọn ṣekọlu si ipade ẹgbẹ oṣelu Apc.

“Awọn eeyan wa ti tẹ fẹfẹ pe ki a bẹrẹ ipade ni wọọdu kẹwaa, ni isẹlẹ naa waye. A ri awọn janduku naa, ti wọn si n yinbọn lu wa.

“Lati Naira and Kobo ni wọn ti bẹrẹ si ni ba dukia awọn eeyan jẹ, ti wọn si fi ibọn tu ipade naa ka. Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo wa nidi isẹlẹ naa.”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Amidu Tadese