Àwọn òṣìṣẹ́ ọba, aráàlú ń tara bí wọn kò ṣe rí káàdì ìdìbò wọn gbà

Aworan

Awọn olugbe ilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo lo ti bu ẹnu atẹ lu bi ajọ eleto idibo ilẹ yi, INEC ṣe n pin kaadi idibo alalopẹ, PVC, ni ipinlẹ naa.

Ọsẹ to kọja ni Gomina ipinlẹ naa, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu kede ọjọ iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati fun awọn ara ilu ati os ni ale lọ gba PVC wọn.

Awọn olugbe ipinlẹ naa lo jade lọpọ yanturu nibamu pẹlu ikede ijọba lati lọ gba PVC wọn lawọn oriko to sunmọ wọn julọ amọ ti ko si oṣiṣẹ ajọ INEC kankan lawọn oriko naa.

Abẹwọ akọroyin ileeṣẹ BBC News Yoruba sawọn oriko gbigba kaadi PVC lawọn wọọdu nilu Akure ni o ti ri awọn ara-ilu to n reti awọn oṣiṣẹ ajọ INEC lati le gba kaadi wọn.

Pupọ ninu awọn to lọ oriko gbigba kaadi naa ni wọn pada sile lẹyin ọpọ wakati ti wọn ti n duro lai ri ẹnikẹni ko waa pin kaadi nibẹ.

Ki ni awọn araalu sọ nipinlẹ Ondo?

Aworan

Iya agba kan to ti le ni ọmọ aadọrin ọdun, Musilimat Akande, ti a ri ni St. Peter’s Demonstration Primary School wipe owo ti oun na wa si oriko naa to le ni ẹẹdẹgbẹrin naira lo dun oun ju.

Iya Akande ni ikede ijọba pe ki wọn lọ gba kaadi idibo loni lo mu ki oun o tun pada wa laimọ pe oun ko nii ba ẹnikẹni nibẹ.

Akande fikun pe bi igba mẹta ọtọọtọ loun ti wa si oriko naa to jẹ pe niṣe ni oun yoo pada sile lẹyin ọpọ wakati lori ila lai ri kaadi naa gba.

Bakan naa ni iyaafin Foluso Ogunleye to jẹ oṣiṣẹ ijọba banujẹ lori wiwa ti oun atawọn akẹgbẹ rẹ wa soriko naa lai si ẹni ti yoo da wọn lohun.

Ni ileewe Methodist Primary School, awọn to wa nireti pe awọn yoo ri PVC wọn gba ni wọn ba ijakulẹ pade nibi oriko naa ko ṣe yatọ si awọn oriko to ku.

Ọgbẹni Friday Aigbodemen to ni ohun ti wa ni ileewe naa lati nkan bii wakati mẹta sẹyin wipe ko bojumu rara fun awọn oṣiṣẹ ajọ INEC lati kuro ni oriko lai sọ fun awọn to ṣi ni kaadi lọdọ wọn.

Alagba Rasheed Ogunyemi to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin wipe igba kẹta ree tohun yoo wa sinu ọgba ileewe naa nitori kaadi idibo amọ ti ohun ko rii gba.

Aworan
Aworan

Àwọn òṣìṣẹ́ ọba kò rí PVC gbà ní ibùdó ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Ogun

Bákan náà ni ọmọ ṣe ṣorí ní àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Ogun bí àwọn ènìyàn kò ṣe rí PVC wọn gbà lẹ́yìn tí wọ́n ti lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti fi dúró de àwọn àwọn òṣìṣẹ́ INEC.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun kéde ìsinmi ọjọ́ méji ìyẹn ọjọ́ Ìṣẹ́gun àti Ọjọ́rú fún àwọn òṣìṣẹ́ ọba láti gba káàdì ìdìbò wọn.

Àyẹ̀wò BBC News sí ilé ẹ̀kọ́ St Peters Primary School ní Owode Ofada ní ìjọba ìbílẹ̀ Obafemi Owode ìpínlẹ̀ Ogun ṣàfihàn rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn kàn dúró sí ibùdó náà lásán .

Ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tó lọ sí ibùdó náà láti gba káàdì ìdìbò rẹ̀, Adekunle Jimoh ní láti nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ni òun ti lọ sí ibùdó náà ṣùgbọ́n òun kò rí àwọn òṣìṣẹ́ INEC láti fún àwọn ní káàdì ìdìbò.

Adekunle ní gẹ́gẹ́ bí ìkéde INEC pé aago mọ́kànlá ni àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa yọjú sí àwọn ibùdó yìí ni òun tètè ṣe kúrò nílé kí èrò tó pọ̀.

Ó ní nígbà tó di aago mẹ́ta ọ̀sán tí àwọn kò rí òṣìṣẹ́ INEC ni oníkálùkù àwọn gba ilé lọ.