Tinubu tún pàdé ìyá arúgbó Kwara tó ń ṣàdúrà fun nínú fídíò kan, ọ̀rọ́ bọ́

Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń retí àánú rẹ Tinubu – Ìyá arúgbó ní Kwara

Tinubu àti Alhaja Sifau Alanamu

Oríṣun àwòrán, Twitter

Olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu tún ti pàdé pẹ̀lú ìyá àgbàlagbà kan, tí òkìkí rẹ̀ kàn fún wí pé ó ń gbàdúrà fún Tinubu lásìkò ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó wáyé ní Abuja lọ́dún tó kọjá.

Ìyá àgbàlagbà náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alhaja Sifau Alanamu, tí ẹ bá rántí, ni òkìkí rẹ̀ kàn nínú fídíò kan pé ó kọ̀ láti sùn lálẹ́ ọjọ́ tí ètò ìdìbò abẹ́nú APC ń wáyé ní Abuja.

Màmá yìí sì ló ń gbàdúrà kíkan fún ìjáwé olúborí Tinubu ninu idibo abẹnu naa.

Lẹ́yìn tí Tinubu gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò abẹ́nú náà, ló ránṣẹ́ pe ìyá náà láti yọjú sí òun ní Abuja, níbi tó ti gba ìyá náà ní àlejò.

Tinubu àti Alhaja Sifau Alanamu

Oríṣun àwòrán, Twitter

Tinubu, jọ̀ọ́ ní àánú mẹ̀kúnù tó bá borí, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló nílò àánú rẹ – Ìyá àgbà

Ìyá náà tún ṣèlérí pé òun máa ri dájú pé òun yọjú síbi ayẹyẹ ìbúrawọ́lé fún Tinubu tó bá jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò gbogbogboò tí yóò wáyé nínú oṣù kejì ọdún yìí.

Nígbà tó di ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kìíní ọdún 2023 ni Tinubu àti ìyá yìí tún pàdé níbi ètò ìpolongo ìbò Tinubu tó wáyé nílùú Ilorin.

Àwòrán kan tí Dada Oluwasegun, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùrànlọ́wọ́ Tinubu lórí ètò ìròyìn fi sórí Twitter ní Tinubu sọ fún ìyá náà pé àwọn yóò tún pàdé níbi ètò ìbúrawọlé.

Nínú fídíò náà, Alhaja Sifau rọ̀ Tinubu láti ní àánú mẹ̀kúnù tó bá jáwe olúborí nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló nílò àánú nítorí ipò tí orílẹ̀ èdè yìí wà báyìí.