Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọlẹ́yìn Auxilliary mẹ́sàn-án fẹ́sùn ìdigunjalè! Àlàyé rèé

Awọn adigunjale

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iroyin to n tẹ BBC Yoruba leti ni wipe awọn mẹsan kan to jẹ alabaṣe alaga ẹgbẹ awakọ ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Mukaila Lamidi ti ọpọlọpọ mọ si Auxilliary ti wa ni atimọle ọlọpaa bayii fun oniruuru ẹsun to ni ṣe pẹlu igbimọpọ, idigunjale, igbiyanju lati paayan ati lilo nnkan ijagun lọna aitọ.

Koda wọn ti wọ gbogbo wọn lọ si ile ẹjọ Majisireeti to wa ni agbegbe Iyangaku

ni ilu Ibadan ti wọn si kawọ pọnyin rojọ lorii oniruuru ẹsun mẹtindinlogun.

Amọ gbogbo wọn ni awọn ko jẹbi ẹsun kankan ti wọn fi kan wọn.

Omii lara ẹsun wọn nipe wọn n ṣe ikọlu si awọn eeyan, lilọni lọwọ gba ohun ti kii ṣe tiwọn eyi to pọ to ọpọlọpọ miliọnu naira.

Iwe ẹsun ti wọn fi kan wọn tọka si wipe wọn fẹ ṣekọlu si ile Gomina Seyi Makinde.

“Wipe ẹyin (afurasi) atawọn mii to na papa bora ni ọjọ ikọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun 2023 ni nnkan bii ago meji ọsan ni ile Gomina Seyi Makinde ni agbegbe Ikolaba, Ibada lẹba ile ẹjọ Majisireeti gbimọ pọ lati da ilu ru ati ṣiṣe idigunjale eyi to di wipe ẹ ti da ẹṣẹ to lodi si ofin to si lẹtọ ifiyajẹni labẹ ofin orilẹede Naijiria.

Agbẹjọro awọn afurasi, J.D Olaniyan tako o wipe ile ẹjọ ko laṣẹ lati gbọ ẹjọ to si tọka si awọn ẹsun naa.

O wa rọ ile ẹjọ naa wipe ki wọn jẹ ki awọn mọlẹbi ati ará awọn onibara rẹ lẹtọ lati yọju si wọn ni ọgba ẹwọn Agodi ti wọn ko wọn si titi di asiko ti wọn yoo gbe ẹjọ naa lọ si ọdọ ile ẹjọ to koju osuwọn fun igbẹjọ.

O ni ile ẹjọ Majisireeti yii ko lẹtọ lati gba ẹjọ naa pẹlu iru ẹsun ti wọn fi kan wọn.

“Nitorinaa, mo rọ ile ẹjọ lati fi wọn si atimọle Agodi ki a le ni anfani lati foju kan wọn.

Eyi yoo jẹ ko rọrun fun awọn agbẹjọro wọn lati gbaradi fun ati lati gbe igbẹsẹ fun gbigba beeli wọn.”

Fun idi eyi, Adajọ S.H Adebisi ti ile ẹjọ Majisireeti ti sun igbẹjọ wọn siwaju di ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Keje, Ọdun 2023.

Niṣe ni awọn mọlẹbi to farahan nile ẹjọ bu si ẹkun gẹgẹ bi wọn ṣe n rii ti wọn n ko awọn afurasi naa lọ sinu ọkọ ti yoo ko wọn lọ ọgba ẹwọn.