Mi ò ní ìkùnsínú sí àwọn tó bá mi du àṣíá ìdíje gómìnà ní APC- Oyetola

Gomina Oyetola

Oríṣun àwòrán, @Oyetola

Gomina ipinlẹ Ọsun, Alhaji Adegboyega Oyetọla ni ko si iku sinu kankan pẹlu awọn Oludije ti awọn jọ dije fun aṣia oludije ipo gomina ọsun lẹgbẹ oṣelu APC laipẹ yii.

O ni ẹtọ wọn labẹ iṣejọba tiwantiwa ni.

Ninu atẹjade kan ti Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Ismail Omipidan fi sita leyi ti jẹyọ.

Oyetọla ni jijade awọn oludije mejeeji, iyẹn Moshood Adeoti ati Yusuf Lasun jade lati dije gan ni iyọ ọbẹ iṣejọba tiwantiwa.

” Ẹwa iṣejọba tiwantiwa niyi. Awọn oludije lo wọn labẹ iṣejọba tiwantiwa ni. Mo si dupẹ pupọ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ fun adura wọn ati ati aduroti wọn pẹlu igbagbọ ti wọn ni ninu mi.

“Ẹ jẹ ki n wa fi da yin loju pe emi o ni ja a yin kulẹ. N o tubọ maa ṣiṣẹ ilọsiwaju apaọ lati san yin lẹsan igbagbọ ti ẹ ni ninu mi gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ oṣelu yii “

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bawo ni idibo abẹnu APC ṣe lọ si?

Lọjọ kọkandinlogun oṣu keji ọdun 2022 ni awọn omo ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Ọṣun jade lọ dibo yan ẹni ti wọn fẹ ki gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina to n bọ lọna ni ipinlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awon wo lo dije pelu Oyetola?

Awọn Oludije mẹta lo du asia naa – Gomina Oyetọla to wa lori ipo naa lọwọ to n du saa keji; Moshood Adeoti ti igun to wa kẹyin gomina aba, Rauf Arẹgbẹṣọla fa kalẹ; Lasun Yussuff to f’igbakanri jẹ igbakeji olori ile igbimọ aṣofinṣoju.

Lẹyin o rẹyin, gomina Oyetọla ni aṣia naa ja mọ lọwọ pẹlu ibo okoolenigba a le meji ẹgberun ati mọkan din laadọsan (222, 169).

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Adeoti ko ibo ẹgbẹrun mejila o le ẹẹdẹgbẹwa ati mọkanlelogun, (12, 921) ti Lasun Yussuff ni tirẹ si ni ibo ọtalenirinwo (460)