Ọmọ ọ̀dọ̀ jí N81.6m ọgá rẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ẹ wo bí o ṣe fi owó pitú

Aworan afurasi to ji owo gbe ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Zone 2 Lagos

Ọwọ ṣikun awọn agbofinro ti ba arabinrin ọmọ ọdọ kan Blessing Effiong ti wọn fẹsun kan pe o ji ẹgbẹrun mọkanlelaadọta dọla owo ọga rẹ gbe.

Ni iṣiro Naira, owo yi sunmọ mọkanlelgọrin miliọnu Naira,N81.6m.

Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa labẹ iadari igbakeji ọga ọlọpaa pata ni Zone 2 Onikan lo kede ọrọ yi.

Wọn ni awọn ri Blessing ati ọkọ rẹ Bassey Effiong mu lẹyin tawọn tọ pinpin wọn de ipinlẹ Cross River lati Lekki ni ipinlẹ Eko ti wọn ti fẹsun owo jinji kan wọn.

Gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa SP Ayuba Umma ti ṣe wi, awọ mejeeji gbimọran pọ lati hu iwa ẹsẹ yi lọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2023.

Ọjọ naa jẹ bi ọjọ kẹta lẹyin ti Blessing bẹrẹ iṣẹ ọmọ ọdọ ni ile awọn ọga to wa ni Lekki.

SP Umma sọ pe lọjọ Kọkanlelọgbọn oṣu Kini ni ọwọ tẹ awọn afurasi yi to si ni wọn ti na ninu owo naa lati fi ra awọn dukia kọọkan.

Alukoro ọlọpaa ko ṣalaye ẹni to ni owo naa ati idi to fi ni aduru owo bẹẹ ni ipamọ ninu ile rẹ.

Ọrọ naa fẹ dabi ti Minisita kan lorileede Ghana ti awọn ọmọ ọdọ rẹ ji owo miliọnu kan dọla ni ile rẹ ati awọn dukia mii.

Itu ree ti awọn afurasi fi owo ti wọn ji gbe pa

Gẹgẹ bi awọn agbofinro ṣe ṣalaye,alarina kan taa mọ si agent ti orukọ rẹ n j Anthony lo mu Blessing Effiong wa sibi to ti n ṣiṣẹ to si bẹrẹ iṣẹ lọjọ Kẹtalelogun oṣu Kejila ọdun 2023.

”Lẹyin ọjọ mẹta to bẹrẹ iṣẹ ni o ji $51,000 gbe ti oun ati ọkọ rẹ si salọ si ipinlẹ Cross River”

Alukoro ọlọpaa tẹsiwaju pe ”O kọkọ kọ lati ṣalaye iye to ji gbe amọ o pada jẹwọ pe oun ji ẹgbẹrun lọna ọgbọn dọla to si loun fun ọkọ rẹ,Bassey Effiong ni ẹgbẹrun ogun dọla”

“Bassey Effiong naa jẹwọ pe oun fi owo tọju iya oun to wa lori aarẹ,oun ra ọkọ tipa kan, ọkada meji toun si fi owo to ku pari ile toun kọ ni Cross River”

Awọn mejeeji ni awọn ọlọpaa lawọn ti ko lọ siwaju ile ẹjọ lẹyin ti iwadii pari lori ọrọ naa.

“Both suspects have been charged and brought before the court following the completion of the investigation, under the directive of the Assistant Inspector General of Police in charge of Zone 2 Command. AIG Olatoye A. Durosinmi.