Ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba l’Ogun ni kí Olú Owode lọ rọọ́kún nílé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook

Igbimo lọba lọba nipinlẹ Ogun, ni abẹ adari Alake ti ilu Ẹgba, Ọba Adedotun Aremu Gbadebo ti ni ki Ọba Kolawole Sowemimo, Olu Owode ti ilu Owode lọ rọọkun nile fun oṣu meji.

Ifofin de Ọba Sowemimo naa waye lẹyin ipade olooṣoṣu ti igbimọ awọn lọbalọba ipinlẹ naa lọjọ Ẹti.

Igbesẹ wọn waye lẹyin asiko diẹ ti Oba Sowemimo fi owo kọ ọrun olorin Fuji, Wasiu Ayinde nita gbangba nibi ayẹyẹ kan.

Alaga igbimọ lọbalọba naa, Olowu tí ilu Owu, Ọba Ọjọgbọn Saka Matemilola ni fifi ofin de Ọba naa waye lẹyin ti awọn Ọba ti gbe aṣemaṣe ti Ọba naa ṣe yewo.

Olowu ni aṣemaṣe naa lodi si iwa awọn ọba nipinlẹ Ogun ati si aṣa ilẹ Yoruba.

Ki ni Olu Owode sọ lori ọrọ yii?

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, Oba Kolawole Sowemimo ni oun gba pe oun jebi.

O ni oun ko mọ pe iwa bẹẹ ko daara gẹgẹ bí ọba.

Ọba Kolawole Sowemimo ni oun faramọ idaniduro oṣu meji naa ati pe oun tọrọ aforijin lọwọ gbogbo igbimọ awọn lọbalọba nipinlẹ Ogun ati Ẹgba lapapọ lori iwa ti oun hu.

Bakan naa lo bẹ awọn omo Naijiria lati maa binu si iwa ibajẹ ti oun.

“Igbimọ lo pinnu pe awọn yoo da mi duro fun oṣu mẹta nitori bi mo ṣe na owo fun elere kan.

“Nigba ti wọn bi mi pe ki ni mo ni lati sọ, mo ni mo gba pe mo jẹbi, ti wọn si dikun si oṣu meji.

“N ko ni nnkan lati sọ, ọmọ ti wọn ba nifẹ si ni wọn ma n ba wi, ohun ti awọn igbimọ Ọba ba sọ ni mo tẹle.”