Àwọn jàndùkú ṣekúpa ọ̀gá àgbà CBN tẹ́lẹ̀rí ní Kaduna, jí èèyàn 50 gbé lọ

bandit attack

Oríṣun àwòrán, getty images

Awọn janduku ti ṣekupa eeyan mẹfa o kere tan lagbegbe Kwassam ati Sabon Layin, nijọba ibilẹ Kauru, nipinlẹ Kaduna.

Lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ni ọga agba kan ni banki apapọ Naijiria, CBN nigba kan ri ati aburo rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ko tii fidi iroyin naa mulẹ, atẹjade kan lati ọọfisi ajọ Southern Kaduna Peoples Union (SOKAPU), ti agbẹnusọ rẹ, Josiah Abraks buwọlu sọ pe oru ọjọ Ẹti ni ikọlu ọhun waye.

Abraks sọ pe awọn agbebọn naa tun ji aadọta eeyan gbe lọ ninu ikọlu miran ni abule Sabon Layin lasiko kan naa.

O wa ke si ijọba ipinlẹ Kaduna ataawọ ẹṣọ alaabo lati ji giri ki wọn si kọju ija si awọn janduku ọhun to n da ipinlẹ Kaduna laamu.

Ẹwẹ, gomina ipinlẹ naa, Uba Sani ti ke si ileeṣẹ ọmọ ogun lati mura si iṣẹ wọn nipinlẹ naa lọna ati daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu.

Gomina ọhun ni oun ti ran kọmiṣọna to n ri si eto abo, Samuel Aruwan, lati ṣabẹwo si awọn agbegbe ti ikọlu naa ti n waye.

Kerawa, to jẹ agbegbe ti awọn darandaran pọ si ni aringbungbun Kaduna jẹ ọkan lara awọn ibi ti ikọlu lẹmọlemọ awọn janduku agbebọn ti maa n waye.

Amọ awọn to n fara kasa awọn ikọlu naa julọ ni awọn agbẹ to wa lagbegbe ọhun.

Wayi o, ijọba Kaduna ti sọ pe oun yoo tẹsiwaju lati maa daabo bo awọn eeyan ipinlẹ naa.