Ọlọ́pàá tó gbé oúnjẹ tẹ̀lé ènìyàn nínú fọ́nrán tó gba ìgboro yóò fojú winá òfin

Nimota Akanbi àti ọlọ́pàá tó gbe oúnjẹ lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Others

Ọlọ́pàá tó gbé oúnjẹ tẹ̀lé ènìyàn nínú fọ́nrán tó gba ìgboro yóò fojú winá òfin

Láti bí ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn ni fọ́nrán kan gba orí ẹ̀rọ ayélujára kan léyìí tó ti ń fa awuyewuye láàárín àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Nínú fọ́nrán náà, ọlọ́pàá kan ń gbé oúnjẹ tẹ̀lé aṣojú orílẹ̀ èdè Netherlands tẹ́lẹ̀ rí, Nimota Akanbi níbi ètò ìnáwó kan.

Kini fidio yii bi jade nileese olopaa Naijiria?

Ìwà yìí ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ti ń kùn lé lórí wí pé báwo ni ọlọ́pàá yóò ṣe ojúṣe láti máa dá ààbò bò ará ìlú tí yóò wá gbaṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ nínú aṣọ ọlọ́pàá?.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá korò ojú sí ọlọ́pàá tó gbé oúnjẹ tẹ̀lé Nimota Akanbi

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti korò ojú sí ọlọ́pàá kan tí fọ́nrán gba orí ẹ̀rọ ayélujára níbi tó ti gbé oúnjẹ tẹ̀lé aṣojú orílẹ̀ èdè Netherlands tẹ́lẹ̀ rí, Nimota Akanbi níbi ètò ìnáwó kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nígbà tó ń júwe ìwà tí ọlọ́pàá yìí hù bíi èyí tí kò bá òfin àti ìlànà iṣẹ́ ọlọ́pàá mu, agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Muyiwa Adejobi ni àwọn ti ráńṣẹ́ sí ọlọ́pàá náà láti wá sí Abuja láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Adejọbi ní àwọn gbọ́dọ̀ korò ojú sí irúfẹ́ ìwà ìdójútì báyìí kí àwọn ènìyàn yé tẹ àwọn òṣìṣẹ́ àwọn lójú mọ́lẹ̀.

Oúnjẹ ara rẹ̀ ni ọlọ́pàá tó wà nínú fọ́nrán yẹn gbé dání kìí ṣe tèmi – Nimota Akanbi

Kini Nimota Akanbi so lori fidio naa?

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí fọ́nrán tó gba orí ẹ̀rọ ayélujára, aṣojú orílẹ̀ èdè Netherlands tẹ́lẹ̀ rí, Nimota Akanbi ní òun kọ́ ni òun ni oúnjẹ ti ọlọ́pàá náà gbé dání.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Akanbi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́rú ní lóòótọ́ ní òun àti ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ òun jọ lọ síbi ìnáwó kan ní ìlú Ìlọrin ṣùgbọ́n irọ́ tó jìnà sí òòtọ́ ni pé òun gbé oúnjẹ fún un láti gbe dání fún òun.

Ó ní òun mọ pàtàkì iṣẹ́ ọlọ́pàá àti pé ẹlẹ́kọ̀ọ́ ni òun, òun kò lè hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.