Wo àwòrán bí Ukraine ṣe rí tẹ́lẹ̀ ṣáájú ìkọlù Russia àti bó ṣe rí báyìí

Borodyanka near Kiev, Ukraine - 3 March 2022

Oríṣun àwòrán, EPA

Awọn ado oloro lati Ruissia ti ba ọpọ ilu nla ati abule jẹ ni Ukraine.

Awọn aworan yii ṣafihan bi ilu naa ṣe ri tẹlẹ ki ikọlu Russia to bẹrẹ si n waye ati bi ilu ọhun ṣe ri lọwọ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ ogun Russia jina diẹ si ilu Kyive, tii ṣe olu ilu Ukraine, oniruru ikọlu lo ti waye si ilu naa.

Ọjọ Abamẹta to kọja ni ado oloro ba ileegbe alaja pupọ yii.

Kyiv in Ukraine

Ilu Irpin niyii, to jẹ nnkan bii ogun kilomita si Kyiv ti ikọlu naa ti n waye julọ.

Oniruru ado oloro to n balẹ nibẹ ti yi awọ ilu naa pda.

Irpin, Ukraine

Ilu Kharkiv ni ilu keji to tobi ju ni Ukraine, o si jẹ ilu kan gboogi ti ikọlu Russia ti n waye julọ.

Ijọba Ukraine ni akọlu lemọ-lemọ lo ṣelẹ ni ilu naa lorumọju.

Kharkiv, Ukraine
Kharkiv, Ukraine

Ni Borodyanka, ọpọlọpọ ile ni ado oloro orilẹ-ede Russia bajẹ nibẹ.

Aworan drone ṣafihan bi ikọlu naa ṣe lagbara to.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa ni ọrọ ri niluu Chernihiv, nibi ti awọn ọmọ ogun Russia ti kọlu ilu naa lati iha Ariwa.

Ijọba Ukraine sọ pe ko din ni ọgbọn eeyan to ku lagbegbe naa lọjọbọ lasiko ti ado oloro ba awọn ile alaja pupọ ati awọn ile ẹkọ kan jẹ.

Chernihiv, Ukraine
Index image

Aworan lati ori ẹrọ satalaiti ṣafihan bi nnkan ṣe bajẹ to niluu Rivnopillya ti ko fi bẹẹ jinna rara si ilu Chernihiv.

Rivnopillya, Ukraine