Fídíò, Ó máa ń dùn mí tí Òbí Yorùbá kò bá kọ́ ọmọ̀ rẹ̀ ní èdè nítorí pé èmi ti fi Yorùbá soriíre púpọ̀- Tiago Òyìnbó, Duration 5,24

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Tiago Isola, akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ibadan: Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

Eyin ọmọ Yoruba, e wa mọ̀ sii nipa oyinbo to fẹ́ran ede Yoruba pupo yii.

Wo Tiago Òyìnbá tó ń fi èdè Yorùbá dárà bíi kàásíǹkan!!!

Tiago Isola je omo orile-ede Portugal.

O n gbe ni Naijiria, o si je akekoo Fasiti Ibadan nibiti sanmọ́nti gbe dun ilẹ̀ to tun ni ọgba eranko

Tiago oyinbo to feran Amala ati gbegiri pupo

Kini awon nkan mii ti Tiago tun so fun BBC Yoruba?

Odomode Tiago Isola yii so nipa awon anfani ti oun maa n je lataari ede Yoruba pe: Àwọn ènìyàn máa ń fun ní nǹkan nítorí pé mo ń sọ Yorùbá

Bakan naa lo gba awon Obi ati Alagbato nimoran lati kọ́ omo wọ́n ni ede Yoruba ati ni jijẹ́ ounjẹ Yoruba

O ni: Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

Kò yẹ kí àwọn ìran Yorùbá máa fọwọ́ yẹpẹrẹ mú èdè Yorùbá àti pé kò yẹ kí àwọn òbí máa sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí àwọn ọmọ ní kékeré

Àǹfàní púpọ̀ ló wà nínú sísọ èdè Yorùbá tí mo sì ti mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nítorí èdè Yorùbá.