Ọlópàá ní lóòótọ́ ní ọtá ìbọn bá Jumoke Oyeleke ní Ojota ṣùgbọ́n…

Kọmisaana ọlọpaa nipinlẹ Eko ati oku ọmọ ti wọn pa ni Ojota

Oríṣun àwòrán, others

Imọlẹ ti bẹrẹ si ni tan si ọrọ iyinbọnpaniyan arabinrin Jumoke Oyeleke ti ọta ibọn ṣekupa lasiko iwọde Yoruba Nation lọjọ Kẹta oṣu Keje ọdun yi.

Ko si sẹyin bi ileeṣẹ ọlọpaa ni Eko ṣe gba pe lootọ ni ọta ibọn ba Jumoke to ṣi mu ẹmi rẹ lọ.

Ọlọpaa to wa nidi iwadii iṣẹlẹ yi, IPO, Onyeisi Nwaolai lo jẹri si ọrọ yi ninu atẹjade to gbe sita nipa ohun to wa nidi iku Jumoke.

Ninu iwe ijẹri yi ti ileeṣẹ iroyin Naijiria Punch sọ pe o tẹ awọn lọwọ,awọn ọlọpaa lawọn ko le sọ pato ẹni to yinbọn naa ṣugbọn ọta ibọn ba Jumoke lootọ.

O sọ ninu iwe naa pe ”eeyan mẹjọ lo mu ẹri wa fun wa to fi mọ iya oloogbe Jumoke ati ẹni to ni ṣọọbu ti ọta ibọn ti ba,Tosin Oyemade”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ naa amọ ati ribi fidi ọrọ mulẹ bayi pe ọta ibọn ti a ko mọ ẹni to yin lo ba Jumoke”

Ninu ọrọ rẹ bakan naa, Onyeisi sọ pe awọn ri nkan ija oloro gba lọwọ awọn oluwọde kan ati pe awọn ti n ṣe ayẹwo finifini lori wọn.

Bi a ko ba gbagbe lọjọ Kẹta oṣu Keje ni awọn oluwọde Yoruba Nation Rally pe jọ si ọgba Gani Fawehinmi to wa ni Ojota.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

  • Ẹgbẹ́ ìlànà ọmọ Oodua fi ìròyìn ayọ̀ ránṣẹ́ lórí Sunday Igboho
  • Àṣà ìdaranjẹ̀ ti di èèwọ̀ ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà nílẹ̀ Yorùbá
  • Makinde, ìràwọ̀ igbákejì rẹ lò ń lò, òun gan ló yẹ kó jẹ́ gómìnà dípò rẹ – Igun PDP
  • Ilé wó lé èmí, àya àtí ọmọ márùn ún lórí, ẹ̀mí ìyá mí lọ sí – Olùgbé ilé tó dàwó ní Akure
  • Bí Yoruba kò bá yíwà padà, ẹkùn àríwá ní ipò ààrẹ yóò máa lọ – Oluwo
  • “Tí Sunday Igboho, Nnamdi Kanu bá bọ́ sínú APC, wọn yóò gbá ìtúsílẹ̀”
  • Ète ìdìtẹ̀ gbàjọba forí sánpọ́n ní Sudan
  • Seyi Makinde kúró lẹ́gbẹ́ PDP, ìyà tó o fi jẹ wá tó – Igun PDP Oyo
  • Aisha Yesufu kó ọ̀rọ̀ Ooni dànù, ó ní ohun tó kàn kọ́ ni Ọòni fẹ́ lọ ṣe ní ìpèbí
  • Afurasí Fulani ti pa aráàlú mi bíi 50, jó ile 254 níná – Oríadé kan figbe ta

Nigba tawọn ọlọpaa bẹrẹ si ni le awọn oluwọde yi ni ọta ibọn ba Jumoke ni ṣọọbu rẹ to wa ni Ojota lẹba ibi ti iwọde yi ti waye.

Awọn ọlọpaa kọkọ sọ ni ọjọ naa lọhun pe oku tawọn eeyan gbe ju sibẹ ni oku Jumoke wi pe kii ṣe ọta ibọn lo ba a.

Ṣugbọn awọn mọlẹbi Jumoke ati awọn araadugbo sọ pe nigba tawọn ọlọpaa le oluwọde wọ adugbo naa ni ọta ibọn pa Jumoke.

Ko pẹ si igba naa lawọn ọga ọlọpaa pada lọ ki mọlẹbi Jumoke si ile ti wọn si gbe oku rẹ lọ si aaye igbokupamọ si ki wọn to pada wa sinku rẹ.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lati mọ boya ọta ibọn lati ọdọ ọlọpaa lo ṣeku pa Jumoke lootọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ