Àṣà ìdaranjẹ̀ ti di èèwọ̀ ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà nílẹ̀ Yorùbá

Awọn Gomina Guusu

Oríṣun àwòrán, Others

Iroyin ayọ lo jẹ pe o di ẹsẹ bayii fun ẹnikẹni lati mase da ẹran jẹ oko mọ yika ilẹ Yoruba lapapọ.

Idi ni pe gbogbo awọn ipinlẹ to wa ni Kaarọ Oojire ni wọn ti buwọlu abadofin ma fi ẹran jẹko mọ fun awọn darandaran lati gbogun ti iwa ipaniyan, ijinigbe ati ifipabanilopọ.

Koda, awọn gomina ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria yii tun fi ijiya to jopin ti awọn ofin naa lẹyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

  • Ẹgbẹ́ ìlànà ọmọ Oodua fi ìròyìn ayọ̀ ránṣẹ́ lórí Sunday Igboho
  • Makinde, ìràwọ̀ igbákejì rẹ lò ń lò, òun gan ló yẹ kó jẹ́ gómìnà dípò rẹ – Igun PDP
  • Ilé wó lé èmí, àya àtí ọmọ márùn ún lórí, ẹ̀mí ìyá mí lọ sí – Olùgbé ilé tó dàwó ní Akure
  • Bí Yoruba kò bá yíwà padà, ẹkùn àríwá ní ipò ààrẹ yóò máa lọ – Oluwo
  • “Tí Sunday Igboho, Nnamdi Kanu bá bọ́ sínú APC, wọn yóò gbá ìtúsílẹ̀”
  • Ète ìdìtẹ̀ gbàjọba forí sánpọ́n ní Sudan
  • Seyi Makinde kúró lẹ́gbẹ́ PDP, ìyà tó o fi jẹ wá tó – Igun PDP Oyo
  • Aisha Yesufu kó ọ̀rọ̀ Ooni dànù, ó ní ohun tó kàn kọ́ ni Ọòni fẹ́ lọ ṣe ní ìpèbí
  • Afurasí Fulani ti pa aráàlú mi bíi 50, jó ile 254 níná – Oríadé kan figbe ta

Ipinlẹ Eko si lo gbẹyin ninu awọn ipinlẹ to wa nilẹ Kaarọ oojiire ti wọn ti fi ọwọ si aba ofin naa.

Bẹẹ ba si gbagbe, awọn gomina ẹkun guusu Naijiria lo fi ohun sọkan lati gbe ofin naa kalẹ, to si ti bẹrẹ si fidi mulẹ lati ọjọ Kinni osu Kẹsan ọdun 2021.

Ẹ wo igba ti awọn ipinlẹ nilẹ Kaarọ oojire fi ọwọ si abadofin naa:Iroyin ayọ lo jẹ pe o di ẹsẹ bayii fun ẹnikẹni lati mase da ẹran jẹ oko mọ yika ilẹ Yoruba lapapọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ondo

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ni Ọjọ Iṣẹgun, Ọjọ Kọkanlelọgbọn, ọdun 2021 buwọlu ofin to de dida ẹran kaakiri nipinlẹ naa.

Eyi waye lẹyin ọsẹ diẹ ti Ile Igbimọ Aṣofin nipinle naa uwọlu abadofin naa ki wọn to fi ranṣẹ si gomina lati sọ di ofun.

Kọmisọnna nipinlẹ Ondo, Donald Ojogo ni gomina Akeredolu buwolu ni ọfisi rẹ.

Ekiti

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti ni gbedeke Ọjọ Kini, Osu Kẹsan an, ọdun 2021 lati gbegile dida ẹran kaakiri ipinlẹ naa ko le e ni ipa lara wọn nitori ofin naa ti fi ẹṣẹ mulẹ nibẹ tẹlẹ.

Ijọba ipinlẹ Ekiti ni labẹ iṣejọba Ayodele Fayoṣẹ nigba to di ipo gomina mu ni ipinlẹ naa ni wọn ti fofin de dida ẹran kaakiri igboro.

Wọn ni ofin naa si fi ẹṣẹ mulẹ ni ipinlẹ naa nitori naa ko si mimi kankan.

Oyo

Ijọba ipinlẹ Oyo ti ni awọn ti ṣetan lati bẹrẹ si ni fi ẹnikẹni to ba rufin dida ẹran laarin ilu jofin lẹyin ti wọn fi lede pe ọdun 2019 ni wọn ti buwọlu ofin naa ni ipinlẹ naa.

Ijọba ni bio tilẹ jẹpe ko to di asiko yii, ko si ṣiṣẹ ofintoto bọya awọn eniyan n tẹle ofin yii, ohun gbogbo ti yi pada bayii.

Ijọba ni awọn ti gbe Ajọ amuṣẹya Taskforce dide lati ri pe awọn darandaran tẹlẹ ofin naa.

Ogun

Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun naa ti buwọlu aba mase da ẹran ko lẹyin osu kan ti Ile Igbimọ Aṣofin ni ipinlẹ naa buwọlu u.

O si ti di eewọ lati da ẹran jẹ oko nipinlẹ Ogun bayii

Eko

Gomina ipinlẹ Eko Babajide Sanwoolu ti buwọlu ofin to de fifi ran jẹ laarin igboro ni ipinlẹ Eko.

Ohun ti eyi tunmọ si ni pe ẹnikẹni ti o ba da ẹran jẹ laarin ilu ni itako ofin yoo foju wina ofin.

Gomina buwọlu ofin yi ni ọjọ Aje lẹyin tawọn ọmọ ile aṣofin ipinlẹ naa fi ontẹ jan lẹyin ijiroro ni nkan bi ọsẹ kan sẹyin.

Osun

Ni ipinlẹ Osun, lọ fun gomina Adegboyega Oyetola naa ti buwọlu aba mase da ẹran jko, to si ti di ofin bayii.

Abadofin naa ni ile igbimọ aṣofin ọhun buwọlu ni Ọjọ Kejila, Osu Kẹjọ, ọdun 2021.

Lọwọ bayii ẹsẹ ni fun awọn darandaran lati da ẹmaalu yika tibu tooro ipinlẹ Osun.

Bayelsa

Oríṣun àwòrán, Bayelsa State Ministry of Agriculture