Èyí làwọn ìyàtọ̀ tó wà láàrín ìbò Ààrẹ Senegal àti ti Naijiria

Aworan Aarẹ to jawe olubori ni Sengal, Bassirou Faye ati Aarẹ Naijiria, Bóla Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹta 2024 ni idibo sipo aarẹ orilẹ-ede Senegal waye niluu naa. Bassirou Dimoaye Faye, ẹni ọdun mẹrinlelogoji(44) lo jawe olubori.

Ṣugbọn bo ṣe jẹ pe ilẹ Adulawọ ni Senegal gẹgẹ bii Naijiria, ti igbagbọ si wa pe awọn aleebu kan ko le ma waye ninu ibo ilẹ eeyan dudu, sibẹ, eyi lawọn ohun to mu ibo didi ni Senegal yatọ si ti Naijiria.

Ibrahim Haruna Kakangi, agba akọroyin niluu Abuja to wa nibi idibo Senegal naa ṣalaye pe,

‘Tiwọn ò dà bíi tiwa’

Diẹ ninu awọn ti wọn wa lori ila lati dibo ni Senegal to kọja

Oríṣun àwòrán, Getty images

Pẹlẹ-kutu ni idibo sipo aarẹ Ilẹ Senegal waye. Ko si iroyin rogbodiyan tabi iku ẹnikẹni lọjọ idibo kaakiri orilẹ-ede naa.

Mo le sọ pe bo ṣe pẹ to ti mo ti n jabọ iroyin idibo Naijiria, mi o riru eyi ri.

Fun apẹẹrẹ, nigba idibo aarẹ Naijiria ni 2023, iroyin jade nipa bawọn ẹgbẹ oṣelu ṣe fi ẹtọ awọn oludibo dun wọn kaakiri.

Akọsilẹ to wa ni pe agbegbe 114 ni rogbodiyan ti bẹ silẹ.

Eyi yọri si iku ati ipalara awọn eeyan, awọn agbofinro si tun mu awọn kan.

Ṣugbọn ninu idibo Senegal, ko si iroyin rogbodiyan, debi ti ẹnikẹni yoo tiẹ ku.

Kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi mọ ẹni tó jáwé olúborí

Awọn oludibo senegal

Oríṣun àwòrán, Getty images

Oru ọjọ ti idibo waye lawọn eeyan ti mọ pe Bassirou Faye lo jawe olubori.

Wakati diẹ lẹyin ti wọn dibo tan ni eeyan mẹrindinlogun ninu ẹgbẹ alatako ti ki Bassirou ku oriire.

Nigba ti yoo fi di alẹ ọjọ keji, aarẹ to yege ba awọn araalu sọrọ, o ki ara rẹ ku oriire.

Aarẹ to gbapo lọwọ rẹ, Macky Sall, naa ki Bassirou ku oriire.

Báwo làwọn èèyan Senegal ṣe mọ ẹni tó yege kí wọ́n tóó kéde?

Aworan araalu tinu rẹ n dun

Oríṣun àwòrán, Getty

Eyi ko ṣoro nibi tohun gbogbo ba ti ri bo ṣe yẹ ko ri, nitori bi wọn ba ṣe n dibo ni ẹgbẹ kọọkan yoo ti maa ran aṣọju rẹ lọ sawọn ibudo idibo.

Wọn yoo ka iye ibo ti ẹgbẹ ni nibudo ibo, awọn aṣoju yoo si mọ ohun to n ṣẹlẹ. Boya ẹgbẹ wọn n rọ mu ni abi o ti n fidi rẹmi.

Bi aye ṣe ti lu jara lasiko yii, ko le pẹ rara ti kalulu yoo ti maa mọ apa ibi ti nnkan n fi si.

Ohun to ṣẹlẹ ni Senegal ree. Ṣugbọn nibi ti ododo ko ba si, ti wọn ti n ji apoti ibo gbe, ti wọn n fọ omi-in mọlẹ, ti wọn n fagile awọn ibo kan, yoo ṣoro lati gba bi nnkan ṣe n lọ nibudo idibo gbọ.

Ti a ba fi eyi we idibo 2023 ni Naijiria, akọsilẹ CDD (Centre for Democracy Development), fi han pe ida mẹẹẹdọgbọn (25 %) rogbodiyan to waye ninu ibo aarẹ 2023 lorilẹ-ede Naijiria, waye latara biba apoti idibo jẹ, jija apoti idibo gba ati biba awọn ibudo idibo jẹ.

Eyi si ṣẹlẹ nibudo to to ọgọrun-un bi akọsilkẹ wọn sẹ wi.

Ohun ti mo ri ninu idibo Senegal ni pe otitọ wa, wọn gba ara wọn gbọ. Wọn finu tan ara wọn.

Wọn ni igboya, wọn si panupọ pe awọn ko ni i ṣe ohunkohun ti yoo mu wahala wa.

Fun idi eyi, ẹnikẹni ko fa wahala.

Eyi lo jẹ ki wọn ni esi idibo ti ko ruju, wọn si gba abajade rẹ ko too di pe wọn tiẹ kede.

Awọn to fidi rẹmi gba kamu, ẹni to yege si ki ara rẹ ku oriire.

Èèyan Naijiria le ni 200 miliọnu, ti Senegal fẹrẹ ma to milọnu mejiidinlogun

Aare tuntun Senegal, Bassirou  Faye ati tana, Macky Sall

Oríṣun àwòrán, Senegalese Govt

Èèyan Naijiria le ni 200 miliọnu, ti Senegal fẹrẹ ma to milọnu mejiidinlogun

Naijiria tobi, eeyan pọ nibẹ, to bẹẹ ti wọn ti le ni igba miliọnu ni Naijiria bayii, awọn to wa ni Senegal si fẹrẹ ma to miliọnu mejidinlogun (18) bi akọsilẹ sẹ sọ.

Titobi Naijiria, ailoootọ awọn eeyan lasiko ibo, wa lara ohun to n mu idibo Naijiria kun fun wahala.

Eyi ti ko ri bẹẹ fun Senegal ni tiwọn.

Ṣé báyìí ni wọ́n ń fìgbà gbogbo dìbò àlááfìa ní Senegal?

Rogbodiyan ti waye ri ninu ibo ilẹ Senegal naa ri ki wọn too kọgbọn.

Ibo aarẹ wọn ni 1988, lasiko iṣakoso aarẹ Abdou Diouf, mu rogbodiyan da ni.

Bakan naa lo ri fun wọn ni 1993.

Eyi ti wọn di lọsẹ to kọja yii paapaa, ẹru ba awọn eeyan.

Wọn kaya soke pe ki rogbodiyan ma ṣẹlẹ, nigba ti aarẹ ana, Macky Sall, pète ati sún ọjọ ibo naa siwaju.

Ẹkọ wo ni awọn ilẹ Afrika yooku le kọ lara Senegal?

Awon oludibo ni Senegal

Oríṣun àwòrán, Getty images

Iṣofo ọpọlọpọ owo, ẹmi ati dukia lasiko ibo lo kọ Senegal lọgbọn.

Wọn ko fẹ ri iru rẹ mọ ni wọn ṣe pinnu alaafia lasiko ibo.

Bi awọn orilẹ-ede Afrika yooku naa ba kọ ẹkọ yii lara Senegal, yoo ṣee ṣe fun wọn lati ni iru oori ti wọn ba n fẹ.