Ọlọ́pàá, Amotekun àti figilanté kán lu igbó láti wá àwọn tó pa ọlọ́pàá méjì ní báńkì Iragbiji, Osun

Ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, BBC, NPF

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọsun, Abilekọ Yemisi Opalọla fi idi iṣẹlẹ ikọlu to waye si banki kan nipinlẹ Oṣun lelẹ pe awọn ọlọpaa ti wọ igbo lọ lati wa awọn to ṣe iṣẹ ibi naa.

O fidi ọrọ ọhun mulẹ pe o ti di ọlọpa meji ti o ba iṣẹlẹ naa lọ nigba ti ouun ba ikọ BBC news Yoruba sọrọ.

Awọn adigunjale naa kọlu báǹkì Wema ti ilu Iragbiji ní ìpínlẹ̀ Osun leyi ti awọn ara adugbo ọhun sọ pe ile ifowopamọ kan ṣoṣo to ku awọn ku ree.

Banki Iragbiji

Opalola sọ pe nigbati awọn adigunjale naa ri awọn ọlọpa ti wọn di ihamọra ogun pẹlu awọn eṣọ aabo agbegbe ti wọn si koju ija ibọn si wọn ni kiakia.

Awọn Ọlọpa, ati apapọ awọn eṣọ aabo ibile pelu agbegbe ti wa ninu igbo papa iju lati mu awọn adigunjale naa, ti won gbagbọ pe awon adigunjalè naa si wa ninu igbo.

Osenilaanu pupọ pe olopa meji lo ba iṣẹlẹ naa lo ti oruko won nje Inspekito Ogunbiyi Ahmed ati Inspekito Odeyemi Ayinla lẹsẹsẹ, ni wọn yinbọn pa won.

Banki Iragbiji

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Adigunjalè kọlu báǹkì ní Iragbiji l’Osun, ìlú dàrú

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni awọn adigunjale ti ṣe ikọlu sile ifowopamọsi Wema Bank to wa ni ilu Iragbiji, nipinlẹ Osun.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni nkan bi aago mẹta kọja iṣẹju marundinlogun ni ikọlu naa bẹrẹ.

Iroyin ni awọn adigunjale naa bẹrẹ si n yinbọn soke ni kete ti wọn de inu banki ọhun lọna ati ṣẹruba awọn araalu.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọsun, Abilekọ Yemisi Opalọla fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba pe lootọ ni awọn adigunjale ṣekọlu si ile ifowopamọsi naa.

Lori iroyin pe awọn adigunjale naa ṣi n ṣọṣẹ lọwọ, Opalola ni awọn ikọ ọlọpaa kogberegbe ti wa lọna ibẹ lati lọ koju awọn adigunjale naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni “Gbogbo awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa ni a ti ran ló sibẹ ni kete ti a gbọ”

“Bi a se n sọrọ yii, awọn Tactical Squad, to fi mọ awọn oṣiṣẹ CID atawọn lọgalọga lo ti lọ sibẹ, lagbara Ọlọrun a o ti wọn mu.”