NÍ YÀJÓYÀJÓ Àdó olóró Nàìjíríà ja wọ ìlú lẹ́bàá Lake Chad, ó pa àwọn aráàlù

Copyright: Getty Images

Ajọ WHO lo koju arun Ebola ti wọn si kede ni ọdun to
kọja wi pe arun naa ti lọ si oko igbagbe lorilẹede DR Congo.

Ajọ eleto ilera lagbaye, WHO ni awọn oṣiṣẹ awọn to to
mẹtalelọgọrin wa lara awọn to fi ipa ba awọn obinrin agbalagba ati ọmọde
lopọ lasiko ajakalẹ arun Coronavirus ni orilẹede Democratic Republic of
Congo.

Iwadii to gbe iṣẹlẹ naa jade ni awọn to ṣe aṣemaṣe
yii ni wọn fi ẹsun oniga mẹsan an kan to fi mọ ifipabanilopọ kan wọn.

Bakan naa ni iwadii ọhun ni pe awọn oṣiṣẹ labẹle ati
ni oke okun lo hu iwa ifipabanilọpọ yii laarin ọdun 2018 si 2020.

Iwadii yii sọ bi awọn obinrin to le ni aadọta ṣe bọ
sita lati fi ẹsun ifipabinilopọ sun lasiko arun Ebola naa.

Ninu ọrọ rẹ, adari Ajọ WHO, Tedros Adhanom Ghebreyesus
ni ohun itiju gba a ni awọn to jẹbi ẹsun naa ṣe.

Iwadii naa fihan pe awọn oṣiṣẹ Ajọ WHO naa n bere fun
ibalopọ lọwọ awọn obinrin naa ki wọn to fun wọn ni iṣẹ.

‘’A tọrọ aforiji lọwọ awọn ti wọn hu iwa ibi yii si,
nitori awọn to yẹ ki wọn da abo bo wọn, ni wọn hu iwa ibi si wọn.’’

‘’A fi da wọn loju pe gbogbo awọn to jẹbi ẹsun naa ni
yoo foju wina ofin lai ku ẹyọkan’’

Ajọ WHO ni o ṣeeni laanu pe ko si eto alakalẹ lasiko ajakalẹ
arun Ebola naa lati koju awọn ẹsun bi ifipabanilopọ ati awọn iwa ọdaran
miran.

Adari Ajọ naa ni oun ti awọn gbajumọ nigba naa ni ọna
ati bori ajakale arun Ebola naa to pa eniyan ẹgbẹrun meji ni orilẹede DR
Congo.

Ajọ WHO naa lo koju arun Ebola ti wọn si kede ni ọdun to
kọja wi pe arun naa ti lọ si oko igbagbe lorilẹede DR Congo.