A fẹ́ rí ojú ẹni tó pa ọmọ wa àti òdodo nípa ikú rẹ̀ – Ẹbí Monsura Ojuade

Amofin fun ẹbi Monsurat Ojuade

Agbẹjọro fun mọlẹbi Monsurat Ojuade ti afurasi ọlọpaa kan yinbọn pa ninu ile rẹ, Isreal Mbaebie ti kede pe mọlẹbi oloogbe naa fẹ mọ ododo nipa iku to pa ọmọ wọn ati ẹni to seku pa a.

Mbaebie kede bẹẹ níbi iwadii imọ ijinlẹ lori iku to pa ọmọdebinrin naa to waye lọjọru ní ileẹjọ majisireti to wà ní Ebute meta l’Eko.

Adajọ ileẹjọ majisireti naa, Bola Folarin-William ti wa sun ijoko naa síwaju di ogunjọ osu Kẹwaa lati tubọ jẹ ki iwadii to gbopọn waye sii, ti yoo si tun si tun mu ki awọn ti yoo soju mọlẹbi Monsurat ati ọlọpaa jọ peju sibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni eyi yoo fun idile Monsurat, eyiun Baba, Iya, aburo baba ati ọkan lara awon ẹgbọn oloogbe naa lanfaani lati wa jẹri si isẹlẹ naa pẹlu aṣoju àwọn ọlọpaa.

Adajọ Bola Folarin-William ṣalaye pé iru ijoko bayii ni yoo mu ki gbogbo awọn jọ fori-kori lati mọ bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ ati ohun ti onikaluku pẹlu ijoba yoo ṣe, lati dena iru isẹlẹ yii lawujọ wa lọjọ iwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Amofin Isreal Mbaebie wa rọ ileẹjọ pe ko ba wọn yanju bi mọlẹbi yoo ṣe lọ sinku oloogbe naa lẹyin ti ayẹwo iku to pa oloogbe naa ba pari.

Adajọ majisireti naa wa paṣẹ fun awon ọlọpaa lati ṣe atọna bi wọn yoo ṣe tọwọ bọ’we lati le fun àwọn mọlẹbi laye lati lọ sin oku naa.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sí aṣọ lójú afurasí agbófinró tó pa Monsurat Ojuade, ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀

Monsurat Ojuade

Saaju la ti mu iroyin wa pe Agbẹjọrọ fun Monsurat Ojuade ti ọlọpaa pa ni agbegbe Ijẹshatedo nipinlẹ Eko, ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ileeṣẹ ọlọpaa lati bẹrẹ igbẹjọ lẹyin to ti kọkọ kọ lai fi oju afurasi ọlọpaa to sisẹ ibi naa han.

Ninu atẹjade kan ti agbẹjọrọ fun ẹbi Monsurat, Israel Mbaebie fi lede ni alẹ Ọjọọru, o ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣẹṣẹ fi to oun leti wi pe wọn n gbe afurasi ọlọpaa to pa ọmọbinrin naa, Sergeant Samuel Philips, lọ si ileẹjọ Magisreti loni.

Agbẹjọrọ naa ni saaju ni oun ti kọ lẹta si kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Eko pe awọn mọlẹbi ọmọ ti wọn pa naa fẹ ri oju Sergeant Samuel Philips ni gbangba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ati wi pe ẹbi kọ iroyin ti awọn ọlọpaa fi lede wi pe aṣita ibọn lo pa Monsurat nitori irọ patapata ni.

Ibatan Monsurat to wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni ọlọpaa naa mọ ọ mọ yinbọn lu aburo oun ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

” O jẹ ibanujẹ ọkan fun wa wi pe gbogbo ohun ti ẹbi Monsurat beere fun ni ileeṣẹ ọlọpaa ko kọ ibi ara si, ti wọn si tẹsiwaju lati bẹrẹ igbẹjọ Sergeant Samuel Philips, ti wọn fẹsun kan pe o pa Monsurat.”

”O ṣe ni laanu pe o ku wakati mejila ki igbẹjọ rẹ bẹrẹ ni wọn ṣẹṣẹ fi n to wa leti nitori awọn ọlọpaa ko fẹ fi iwadii wọn han si gbangba ati iru eniyan ti ọlọpaa naa jẹ.”

”Ko si idajọ ti ko yẹ ka ṣe ni gbangba, nitori irọ la ba ni idi ohun gbogbo ti ileeṣẹ ọlọpaa pe ni iwadii ti wọn ṣe.”

Agbẹjọro ẹbi Monsurat wa kesi gbogbo awọn ajafẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria ati lẹyin odi, lati pejọ si ileẹjọ Magisreti ni agbegbe Yaba, nipinlẹ Eko lati fi aidunnu wọn han.

Bakan naa ni agbẹjọrọ naa ni oun yoo sa gbogbo ipa oun lati ri pe ifiyajẹni ati ipaniyan ti wọn ṣe si ẹbi Monsurat ko lọ lasan.

Agbẹjọro naa ni oun yoo ri daju pe idajọ otitọ ati ododo leke ninu iṣẹlẹ yii, ti ẹbi Monsurat yoo si gba idalare.

Ọ̀gá Ọlọ́pàá

Wọn ni aṣita ibọn lo ba ọmọ ọdun mejidinlogun, Monsurat Ojuade ni nnkan bii aago kan oru, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2021, lasiko ti awọn ọtẹmuyẹ CID lọ ṣawari awọn adigunjale kan ni Ijeshatedo.

Amọ awọn mọlẹbi Monsurat ni irọ patapata ni pe aṣita ibọn ni, ti wọn si n bere fun idajọ ododo lori iku aitọjọ to mu ọmọ wọn lọ.