Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ 98 ní Emefiele fi jìbìtì rà láàrín ọdún 2018 sí 2020 – Ìjọba àpapọ̀ fẹ́sùn tuntun kan gómìnà CBN tẹ́lẹ̀

Godwin Emefiele nile ẹjọ

Ara ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ ń béèrè ni bí ààrẹ ṣe yan gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers tẹ́lẹ̀, Nyesom Wike gẹ́gẹ́ bí mínísítà fún olú ìlú Nàìjíríà.

Wọn ti so igbẹjọ rọ lori ẹsun iwa ajẹbanu oni biliọnu mẹfa ati ẹẹdẹgbẹrun miliọnu Naira (N6.9 billion) ti ijọba apapọ fi n kan gomina agba tẹlẹ fun Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele niwaju ile ẹjọ giga apapọ nilu Abuja.

Godwin Emefiele nile ẹjọ

Igbẹjọ naa ko le tẹsiwaju nitori aisi olujẹjọ keji, arabinrin Sa’adatu Yaro ẹni to jẹ oṣiṣẹ banki apapọ Naijiria, ni ile ẹjọ naa nitori ailera rẹ.

Godwin Emefiele ni tirẹ wa nile ẹjọ ni Ọjọbọ.

Godwin Emefiele nile ẹjọ

Onidajọ Hamza Muazu to n gbọ ẹjọ naa, wa sun igbẹjọ si ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹjọ ọdun 2023.

Emefiele, Yaro ati ile iṣẹ rẹ ti o n jẹ April1616 Investment Limited ni yoo maa kawọ pọnyin rojọ niwaju ile ẹjọ naa lori ogun ẹsun to nii ṣe pẹlu iwa ajẹbanu, igbimọpọ hu iwa ibajẹ atawọn ẹsun miran ti wọn n fi kan wọn.

Ijọba apapọ ni Emefiele ra Ọkọ ayọkẹlẹ mejidinlọgọrun laarin ọdun 2018 si 2020

Godwin Emefiele nile ẹjọ

Emefiele ti wa ni ahamọ awọn agbofinro DSS lati igba ti aarẹ Naijiria, Bọla Tinubu ti paṣẹ ko lọ rọọkun nile ni ọjọ kẹsan oṣu kẹfa ọdun 2023.

Ẹsun ti wọn n fi kan an ni pe o lo ipo rẹ lati fun Yaro to jẹ oludari ni ileeṣẹ naa lawọn anfani ti ko tọna labẹ ofin.

Iwe ẹsun ti ileeṣẹ eto idajọ gbe ka iwaju ile ẹjọ naa sọ pe, ọkọ ayọkẹlẹ mejidinlọgọrun atawọn ọkọ ayẹta ti owo rẹ to biliọnu mẹfa ati ẹẹdẹgbẹrun miliọnu Naira (N6.9 billion).

Laarin ọdun 2018 si 2020 ni wọn ra awọn ọkọ naa gẹgẹ bi ijọba apapọ ṣe sọ.

Mẹrinlelọgọrin ninu wọn lo jẹ ọkọ Toyota Hilux, bọọsi ayẹta mercedes Benz mẹwaa, ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Landcruisers mẹta ati Toyota Avalon.