Ìyanu, iyèméjì, àti ẹ̀hónú àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí bí Ààrẹ Tinubu ṣe pín ipò fáwọn mínísítà rẹ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn eniyan ti bẹrẹ si ni fi ero wọn han lori awọn orukọ to jade gẹgẹ bi minisita ni Naijiria ati ipo ti wọn fun awọn eniyan.

Eyi ko ṣẹyin ikede orukọ awọn minisita ti aarẹ fi lede ni Ọjọọru, lẹyin ti Ile Igbimọ Asofin buwọlu wọn.

Lara awọn Minisita ti wọn kede ni gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹri, Nyesom Wike gẹgẹ bi minisita fun ilu Abuja.

Bakan naa ni aarẹ kede Festus Keyamo gẹgẹ bi Minisita fun ileeṣẹ to n risi ọrọ ọkọ ofurufu, Adebayo Adelabu gẹgẹbi Minisita fun ọrọ ina ọba.

Nigba ti aarẹ kede gomina ipinlẹ Osun tẹlẹri, Adegboyega Oyetola gẹgẹ bi minisita fun ọrọ eto irinna ati Dele Alake gẹgẹ bi Minisita fun ọrọ ohun alumọni, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ohun ti awọn eniyan nsọ lori ẹrọ ayelujara ree…

Ikede awọn orukọ wọnyii ti mu ki awọn eniyan bẹrẹ si ni fi ero wọn han wi pe kii se ohun ti wọn lero pe wọn yoo fun awọn eniyan ni wọn fun wọn.

Ibeere akọkọ ni pe kini gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ n wa ni ipo minisita fun ilu Abuja?

Bakan naa ni wọn beere pe Dele Alake, ti ọpọ ro pe yoo di ipo minisita fun eto iroyin mu ni wọn lọ fun ni ipo minisita fun ọrọ ohun alumọni.

Awọn ti wọn tako igbesẹ yii ni igbẹsẹ yii jobi ẹni pe ijọba kan pin ipo naa bi o se wu u, ali kiyesi awọn ohun ti awọn araalu mọ wọn fun.

Aworan

Bakan naa ni awọn araalu tako awọn ti ijọba fun ni ipo minisita nitori pe awọn kan naa to wani ipo tẹlẹri ni wọn tun fun ni ipo minisita.

Awọn eniyan n beere idi ti gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ to ṣẹṣẹ kuro ni ipo se de ipo minisita naa, to fi mo gomina ipinlẹ ọsun tẹlẹ naa to fi di ipo minisita naa mu, to fi mo gomina ipinlẹ Plateau tẹlẹ,Simon Lalong ti wọn ti fun ni ipo minisita fun iṣẹ ati igbanisiṣẹ.

Aworan

Amọ awọn olufẹ wọn fi idunnu wọn , ti wọn si ki wọn ku oriirẹ pẹlu adura pe wọn yoo se aṣeyọri ni idi ipo minisita ọhun.

Aworan
Aworan

Iwe ofin Naijiria fi aye gba bi aarẹ Tinubu se pin ipo minisita- Onimọ nipa eto oselu

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Onimọ nipa eto oṣelu, Ọjọgbọn Dikrullahi Yagboyaju ni ko si ohun to buru ninu bi aarẹ Tinubu se pin ipo minisita lorilẹede naa.

Ọjọgbọn Yagboyaju lo sọ ọrọ yii lasiko to n fi ero rẹ han fun BBC Yoruba lori awọn minisita tuntun ti aarẹ Tinubu ṣẹsẹ yan.

O ni ni ero ti oun yiyan awọn minisita naa yoo mu idagbasoke ba orilẹede naa mu nitori awọn ti aarẹ ri pe o tọ ni o yan si ipo.

O ni labẹ ofin Naijiria, awọn meji ti wọn ni ẹtọ lati di ipo mu, ki si jẹ iṣẹ ti wọn yan laayo ni Olootu agba fun eto idajọ ni Naijiria, iyen attorney general of the Federation ati minisita fun eto idajọ, to si ni aarẹ si ti se bi o se yẹ lori ọrọ wọn.

Ọjọgbọn naa si ni aarẹ Tinubu ti se eleyii to tọ,̣ nitori awọn agbẹjọrọ lo di ipo naa mu.

Bakan naa lo ni ohun ti ofin sọ lori yiyan eniyan si ipo minisita ni pe ẹni naa gbọdọ le mọọkọ-mọọka, ko nilo ju bẹẹ lọ.

‘’ nitori naa, ko di dandan ko jẹ pe onimọ nipa ẹka kan ni aarẹ yoo yan sibẹ gẹgẹ bi minisita, nitori naa Alake lee se isẹ takuntakun ni ẹka ohun alumọni, ti awọn oṣiṣẹ ni ẹka naa ba ran an lọwọ nitori awọn gan ni wọn n ṣiṣẹ ni ẹka naa, amọ ohun ti wọn gbọdọ se ni lati ri pe ohun pese itọna to tọ fun wọn.’’

‘’Bakan naa ni ofin Naijiria fi idi rẹ mulẹ pe o kere tan ipinlẹ kọọkan gbọdọ fi minisita kọọkan silẹ, amọ ofin ko ni pe ipinlẹ kan ko lee fi silẹ ju ẹyọkan lọ.’’

‘’Aarẹ si pegede, nipa riri daju pe o kere tan ipinlẹ kọọkan ni minisita.’’

Bakan naa ni onimọ naa fikun un pe iriri ni agba nitori naa, o dara bi aarẹ se yan awọn to ti wa ni ijọba tẹlẹ lati di awọn ipo minisita naa mu.

O fikun un pe awọn ọmọ Naijiria ko gbọdọ ni ni ẹrọ wọn wi pe awọn ti wọn yan si ipo naa fẹ lọ jẹ owo ilu run ni, amọ ki wọn gbagbọ pe iriri wọn ni wọn nilo lati di awọn ipo naa mu.

Ojọgbọn Yagboyaju war ọ awọn ọmọ Naijiria lati sa ipa wọn ni ipo kipo ti wọn ba wa, fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria.

Bakan lo gba awọn minisita tuntun ni imọran lati se ohun to dara fun awọn araalu ni asiko wọn, nitori pe itan yoo sọ bi o ba di ọla ohun ti wọn gbese ni asiko wọn.